Buhari in Kebbi - Ọmọ Nàíjíríà ní Adesina fẹ́ fọwọ́ bo òtítọ́ lóju mọ́lẹ̀ ni

Oríṣun àwòrán, Twitter/muhammadu Buhari
Olubadamọran pataki fun Aarẹ Muhammadu Buhari lori eto iroyin ati ipolongo, Femi Adesina, ti sọ pe ko si ootọ kankan ninu iroyin to n lọ kiri pe, ọkunrin kan gbiyanju lati kọlu aarẹ Buhari nipinlẹ Kebbi.
Aarẹ Buhari lọ si ipinlẹ naa lati kopa nibi ayẹyẹ ọdun apẹja ati aṣa nilu Argungu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọjọbọ ni fidio kan gba ori ẹrọ ayelujara kan, eyi to ṣafihan bi ọkunrin kan ṣe sare lọ sibi ti Aarẹ Buhari wa lasiko to ṣabẹwo si awọn apo irẹsi ti wọn to jọ lọna ara, to si 'pakuru mọ Buhari'.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Adesina sọ pe inu ọkunrin naa dun pupọ lati ri aarẹ rẹ ni, eyi lo si mu ko sare si Buhari lati bọ ọ lọwọ nibi to ti fẹ ẹ ya fọto pẹlu awọn agbẹ.
Ninu ọrọ kan to kọ si oju opo ayelujara Twitter rẹ, Adesina sọ pe " inu ọdọmọkunrin kan dun lati ri aarẹ rẹ ni ọdun apẹja ni Argungu, o si gbiyanju lati lọ bọ ọ lọwọ, awọn eleto aabo si dena rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ṣugbọn, awọn eniyan kan ti n sọ kiri pe "igbiyanju lati ṣe aarẹ ni ijamba ni. Awọn eniyan ṣe buru to yii?"
Ọpọlọpọ eniyan si ti n f'esi si eyi pe, igbiyanju lati fọwọ bo otitọ ohun to ṣẹlẹ ni ọrọ ti Femi Adesina sọ lori fidio naa.
Bakan naa ni awọn kan n bu ẹnu atẹ lu awọn alaabo Buhari pe 'ibo ni wọn foju si, ti ọkunrin naa fi raaye de ibi ti aarẹ wa'.
Igba akọkọ niyii ti wọn yoo ṣe gbaju-gbaja ọdun ẹja pipa naa lati ọdun kọkanla ti wọn ti ṣe e gbẹyin nitori eto aabo.












