Emir of Kano: Soyinka ní ó dun òun pé Ganduje kò ní alámọ̀ran rere

Oríṣun àwòrán, Emir ti Kano
Ọjọgbọn Wole Soyinka ti bu ẹnu atẹ lu bi ijọba ipinlẹ Kano, labẹ iṣakoso Gomina Abdullahi Umar Ganduje, lori bo ṣe rọ Lamido Sanusi loye, gẹgẹ bi Emir ilu Kano.
Nigba to n sọrọ ninu atẹjade kan, Soyinka ni iyọnipo Sanusi tumọ si pe, awọn ara Ariwa Naijiria ko tii ṣetan, lati gba otitọ ati asa igbalode laaye.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Yorùbá rẹwà, kọ́ nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí ìró ẹnu wọn jọra àmọ́ tí ìtumọ̀ wọn yàtọ̀
- Coronavirus tún ti bẹ́ gìjà sí Ghana àti Gabon
- Ẹ yọmí kúrò ní àhámọ́! Sanusi pe Ọ̀gá ọlọ́pàá àti Ọ̀gá DSS lẹ́jọ́
- A kò mọ ẹni tó pa ọlọ́pàá Ondo àti ìyàwó rẹ̀, òun kọ́ ló pa ara rẹ̀- ọlọ́pàá
- Nàìjíríà bèèrè ìrànwó lọ́wọ́ àjọ àgbáyé láti kápá Coronavirus
- "Owó oṣù òṣìṣẹ́ yóò di gbèsè, oúnjẹ yóò wọ́n, ìlú yóò le, bí ọrọ̀ ajé Náíjíríà bá dagun"
Soyinka ni o ṣeni laanu pe Gomina Ganduje ko ni awọn ọrẹ gidi to le gba a silẹ ọwọ ara rẹ, ati pe, Sanusi ti wọn rọ loye jẹ ọkan pataki lara awọn to lee mu ayipada nla ba awọn ara Oke Ọya.
Ẹwẹ, Emir ilu Kano tẹlẹ ti wọn rọ loye, Sanusi Lamido Sanusi ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ ọhun rara, tori o ti bẹ awọn agbẹjọro agba mejila lọwẹ lati ja fun ẹtọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, DESIGNED BY STUDIO
Awọn agbẹjọro agba ti Sanusi bẹ lọwẹ ni; Ọjọgbọn Kanyinsola Ajayi, aarẹ ẹgbẹ awọn agbẹjọro Naijiria tẹlẹ ati Abubakar Mahmoud; aarẹ ẹgbẹ awọn agbẹjọro Naijiria bayii, Paul Osuro.
Awọn to ku ni Ifedayo Adedipe, Garba Tetengi, Suraj Sa'eda, Funke Aboyade, Nesser Dangiri, Ernest Ojukwu, ati H.O. Afolabi, ti gbogbo wọn jẹ agbẹjọro agba (SAN).

Oríṣun àwòrán, Maigaskiya Photography
Ọjọ Ẹti ni Sanusi n gbe ẹjọ naa lọ siwaju ile ẹjọ giga to wa nilu Abuja, to si n beere pe ki wọn tu oun silẹ ni ahamọ to wa, lẹyin ti Gomina ipinlẹ Kano le e kuro lori oye.
Awọn agbẹjọro Sanusi, ti Lateef Fagbemi (SAN) n ṣaaju wọn pe ẹjọ ọhun lodi si bi wọn ko ṣe jẹ ko kuro ni ilu Awe to wa ni, ni ipinlẹ Nasarawa.
Lara awọn ti Sanusi pe lẹjọ ni; ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa, Mohammed Adamu, ọga agba ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, DSS, Yusuf Bichi, adajọ agba ipinlẹ Kano Ibrahim Muktar ati adajọ agba Naijiria, Abubakar malami (SAN).
Ọjọ́ Ajé, ọ̀sẹ̀ yìí ní ìjọba ìpínlẹ̀ Kano yọ Sanusi Lamido ní orí oyè gẹ́gẹ́ bí Emir ìpínlẹ̀ Kano.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Emir of Kano: Lamido Sanusi pe Ọ̀gá ọlọ́pàá àti Ọ̀gá DSS lẹ́jọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Emir ipinlẹ Kano tẹlẹ, Lamido Sanusi ti pe ẹjọ ni ile ẹjọ giga ni Abuja lati pe fun itusilẹ oun ni ahamọ.
Sanusi ni wọn gbe lọ si ilu Awe ni ipinlẹ Nasarawa ni ibi ti wọn ti fi si inu ahamọ lẹyin ti ijọba ipinlẹ Kano yọ ọ ni ipo ni Ọjọ Aje.
Adari awọn agbẹjọrọ rẹ, Lateef Fagbemi lọ pẹjọ mọ Ọga agba ọlọpaa, ọga agba ajọ ọtẹmuyẹ, DSS ati olotu eto idajọ ni ipinlẹ Kano naa ni wọn gbe lọ si ile ẹjọ giga ti ilu Abuja.
Sanusi beere ki ile ẹjọ da ẹtọ oun pada gẹgẹ bi ọmọ orilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, EMIHD KANO EMIRATE
Bakan naa ni wọn beere fun aye lati rin lati agbeegbe kan si omiran yatọ si ipinlẹ Kano titi ti ileẹjọ yoo fi gbọ ẹjọ wọn.
Mò ń fojú sọ́nà láti bá Emir àná, Sanusi kírun lọ́jọ́ Jímọ̀ - Aráàlú Awe
Ọkan lara awọn iyawo Sanusi Lamido Sanusi, to jẹ Emir ana nilu Kano, ti ṣabẹwo si ni ilu Awe lẹyin irọloye rẹ.
Iyawo rẹ naa, atawọn ọmọ rẹ mẹta ni wọn bẹ ẹ wo nibi ti gomina ipinlẹ Nasarawa, Abdullahi Ganduje le si ni ipinlẹ nasarawa.
Emir ilu Awe, Umar Isa Abubakar; Kabir Musa Ibrahim ati alaga ijọba ibilẹ ti ilu naa wa, Umar Da-Akanio atawọn eeyan mii ni wọn tun ṣabẹwo si Emir tẹlẹ ri ọhun.
- Ǹ jẹ́ o mọ̀ pé ìdọ̀tí rẹ le è sọ ẹ́ di olówó?
- Wo àwọn ohun márùn ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa Sanusi
- Ẹ́ gbaradì, to bá lo jẹnẹrátọ̀ àbí tà á, ò ń fi ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá ṣeré - Sẹ́nétọ̀ ń dábàá
- Agbófinró, tó bá wa ọkada àbí kẹkẹ maruwa l'Eko, o rugi oyin - Sanwo-Olu
- Ará Yúróòpù ẹ fìdí mọ́lé yín, mo ti gbé ìlẹ̀kùn Amẹ́ríkà tìpa torí Coronavirus - Trump
Iroyin ni awọn eeyan ilu ọhun gba Sanusi tọwọ tẹsẹ, bo ti tilẹ jẹ pe inu wọn ko dun si bi ijọba Kano ṣe rọ ọ loye.
Ọkan lara awọn olugbe ilu naa, Mallam Ibrahim Usman Fulani sọ pe "Fulani daran daran ni mi, ṣugbọn igba ti mo gbọ iroyin irọloye Sanusi, ni mo pada wa si ilu.

Oríṣun àwòrán, @OfficialPDPNig
O ni "O yẹ ki n rinrin ajo kan, ṣugbọn mi o ni lọ titi di ọjọ Jimọ ti mo maa lanfani ati gbadura papọ ni Mọṣalaṣi kan pẹlu Sanusi."
Nigba ti Sanusi de ilu naa, ile oni yara meji kan, ti wọn ni o jẹ ti ọkan lara awọn eeyan ijọba ibilẹ ilu naa lo sun mọju.
Ẹwẹ, ijọba apapọ ti sọ pe oun ko lọwọ ninu bi wọn ṣe rọ Sanusi loye gẹgẹ bi Emir ilu Kano.
Agbẹnusọ fun aarẹ Muhammadu Buhari, Garba Shehu ninu atẹjade kan sọ pe, ki awọn eeyan dẹkun ati maa so iṣẹlẹ naa mọ aarẹ lọrun, nitori ko mọ ohunkohun nipa bi ọrọ naa ṣe ṣẹ.













