Coronavirus: Uganda ní àwọn arìnrìn àjò láti UK, US àti Yúróòpù lọ̀rọ̀ kàn

Oríṣun àwòrán, AFP
Ijọba orilẹede Uganda ti se agbekalẹ ilana kan ti yoo pọn ni dandan fawọn arinrinajo lati orilẹede mẹrindinlogun lati fi ara wọn pamọ fun ọjọ mẹrinla, ki wọn lee dena itankalẹ arun Coronavirus.
Lara awọn orilẹede ti ọrọ naa kan ni ilẹ United Kingdom, UK, Amẹrika ati awọn orilẹede mii nilẹ Yuroopu
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Coronavirus kan ìjàngbọ̀n l‘Áfíríkà, ẹ̀rọ tó ń ṣèdámọ̀ àrùn láàrin ìṣẹ́jú mẹ́wàá dé
- Ará Yúróòpù ẹ fìdí mọ́lé yín, mo ti gbé ìlẹ̀kùn Amẹ́ríkà tìpa torí Coronavirus - Trump
- Ẹ múra o, epo rọ̀bì di òkùtà lọ́jà torí Coronavirus, ìlú yóò le koko - NNPC figbe ta
- Ẹ́ gbaradì, to bá lo jẹnẹrátọ̀ àbí tà á, ò ń fi ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá ṣeré - Sẹ́nétọ̀ ń dábàá
- Ìbòòsí o! Ìṣọwọ́ gbá bọ́ọ́lù Atletico kò tọ̀nà àmọ́ a gba ìjákulẹ̀ wa - Liverpool
Bakan naa ni awọn alasẹ salaye pe gbogbo awọn arinrinajo to ba n de si papakọ ofurufu Entebbe ni wọn yoo maa fin oogun apakokoro si lara.
Amọ titi di akoko yii, orilẹede Uganda ko tii kofiri alarun Coronavirus kankan bi o tilẹ jẹ pe minisita feto ilera lorilẹede naa ti jẹwọ pe, ọrọ aje ilẹ naa ko lee gbe iwosan arun yii, to ba fi bẹ silẹ lọdọ awọn.
Coronavirus di akiri má dálé sí, ẹ wo àwọn èèkànlú tó ti fọwọ́ bà
Oṣu kẹwa ọdun 2019 ni arun Coronavirus bẹ silẹ nilu Wuhan, lorilẹ-ede China ti ọpọlọpọ eeyan si ti lugbadi arun naa kaakiri agbaye.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Arun ọhun ko mọ ọmọdẹ tabi agbalagba, bẹẹ ni ko mọ olowo tabi gbajumọ lawujọ, o si ti mu ẹmi ọpọ eeyan lọ.
Iwọnyi ni awọn eeyan jankan lagbaye ti wọn ti fara kaasa arun naa kaakiri orilẹ-ede agbaye.
Tom Hanks:
Owuro kutu Ọjọbọ ọdun yii ni gbajugbaja oṣere ilẹ Amẹrika, Tom Hanks kede loju lopo Instagram rẹ pe, oun ati iyawo oun, Rita Wilson ti lugbadi arun naa.
Hanks ṣalaye pe, awọn mejeeji n ṣe aisan ranpẹ ni wọn ba pinnu lati lọ ile iwosan, esi ayẹwo si fi han pe wọn ti ni arun Coronavirus lara.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Bo tilẹ jẹ pe ọmọ bibi ilẹ Amẹrika ni ẹni ọdun mejilelọgọta ọhun, ṣugbọn orilẹ-ede Australia lo ti lugbadi arun naa.
Nadine Dorries:
Misita fun eto ilera ilẹ Gẹẹsi, Nadine Dorries naa wa lara awọn eeyan jankan lagbaye to fara kasa arun Coronavirus.
Ileeṣẹ eto ilera orilẹ-ede naa sọ pe, minisita ọhun n fi awọn apẹrẹ arun naa han lọjọ kan naa to ṣe ipade ka pẹlu adari ijọba orilẹ-ede ọhun, iyẹn Boris Johnson.
O kere tan, eeyan mẹfa lo ti jẹ Ọlọrun nipe nilẹ Gẹẹsin bayii, ti awọn ti ko din ni ọọdunrun si n ba arun naa finra.
Claudio Pedrazzini:
Claudio Pedrazzini ni ẹni akọkọ lara awọn to wa ni ile igbimọ aṣofin Italy ti yoo ni arun Coronavirus.
Aṣofin ọhun wa lati agbegbe Lombardy, to jẹ iha ibi ti ọwọja arujn naa ti mulẹ ju lorilẹ-ede ọhun.
Iroyin ni awọn awọn akẹgbẹ rẹ ti wọn n joko ti nile aṣofin ti sẹ ara wọn mọle, ti wọn siti bẹrẹ si n gbe igbesẹ to kan lati mọ boya awọn naa ti ko arunn naa
Rudy Gobert:
Ajọ to n risi ere bọọlu alapẹrẹ NBA, niha Ariwa Amẹrika ti kede pe, ọkan lara ọmọ ikọ Utah Jazz, Rudy Gobert ti lugbadi arun Coronavirus.
Wọn ni agbabọọlu alapẹrẹ ọhun ti kọkọ fi ọrọ arun naa ṣere ninu ifọrọwerọ kan pẹlu awọn oniroyin lọjọ Aje, to si fọwọ kan awọn irinṣẹ ti wọn ko wọ inu yara ti wọn ti n parọ aṣọ lọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Lẹyin ọjọ meji si lo bẹrẹ si ni ṣaisan ranpẹ, nigba ti ikọ rẹ n gbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ pẹlu ikọ Oklahoma City.
Ṣugbọn lẹyin ti ayẹwo fi han pe ọkunrin naa ti ko arun ọhun, ni awọn alaṣẹ ba sun ifẹsẹwọnsẹ naa siwaju.
Daniele Rugani:

Oríṣun àwòrán, @goal
Laipẹ yii ni ikọ agbabọọlu Juventus kede pe, agba-ẹyin fun ikọ ọhun, Daniele Rugani ti ni arun Coronavirus lẹyin ayẹwo kan.
Ikọ naa ti wa sọ pe, oun ti bẹrẹ igbesẹ lati ri pe wọn ko gbogbo awọn to ti ṣalabapade okunrin naa sibi kan fun ayẹwo, ati itọju to peye.
Ko to ni arun naa, Rugani ti kopa ninu ifẹsẹwọn meje fun ikọ na ninu saa yii, eyi to gba gbẹyin ni ifẹsẹwọn wọn pẹlu Spal, leyi ti wọn bori.
Coronavirus kan ìjàngbọ̀n l'Áfíríkà, ẹ̀rọ tó ń ṣèdámọ̀ àrùn láàrin ìṣẹ́jú mẹ́wàá dé
Ẹwẹ, bi ọkanjuwa se n dagba lori ọwọja arun Coronavirus to n ja kalẹ bii ọwara ojo yii, naa ni ọgbọn n rewaju nitori awọn onimọ isegun ti se agbekalẹ eroja to n tete sedamọ arun naa lọgan laarin isẹju mẹwa.

Oríṣun àwòrán, Others
Ibudo ayẹwo imọ isegun to wa nilu Dakar lorilẹede Senegal si lo se agbekalẹ awọn eroja ayẹwo ọhun.
Isẹ akanse yii lo jẹ ifọwọsowọpọ ibudo ilera kan nilẹ Gẹẹsi, Mologic ati gbajugbaja ibudo ayẹwo ara kan to wa ni Dakar.
Ireti wa pe awọn ẹrọ to n sayẹwo arun Coronavirus bii miliọnu meji ni wọn yoo maa se jade lọdọọdun, ti wọn yoo si maa pin kaakiri ilẹ Afirika.

Bẹẹ ba gbagbe, ajọ eleto ilera lagbaye ti kede arun asekupani Coronavirus bii ajakalẹ arun lagbaye, to si ti tan ọwọja rẹ de orilẹede bii mẹrinlelaadọfa nigba ti awọn eeyan to to irinwo ati igba ti jẹ Ọlọrun nipe lati ipasẹ arun naa.














