Ondo Regent: Adelé Falowo ní òun ń fojú sọ́nà láti ṣe ìyàwó alárédè lẹ́yìn tí òun bá ipò sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Facebook/Moyinoluwa Falowo
Adele Ọba ilu Ibulesoro nipinlẹ Ondo, Regent Moyinolouwa Falowo sọ pe, jijẹ adele ọba ko di ibaṣepọ to wa laarin oun ati ọrẹkunrin lọwọ.
Moyinoluwa ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ṣalaye pe, niwọn igba ti oun si wa lori itẹ baba oun, aṣa ati iṣe ilu Ibulesoro ko gba oun laaye lati lọkọ tabi ṣe abiyamọ.
Amọ, Moyinoluwa sọ pe oun si n foju sọna lati ṣe iyawo alarede, ni kete ti oun ba ti pari iṣẹ oun gẹgẹ bi Adele, ti ọba miiran si gori itẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ọmọ Nàíjíríà tí wọn fi pósí ‘₦34m’ sin
- Ẹ fura, iyọ̀ onímájèlé tó dóde ti gbẹ̀mí èèyàn méje!
- Ta bá yá owó lókèèrè kò láìfí, ìpèsè ohun amáyédẹrùn là ń ṣe – Lai Mohammed
- Ìtàn ayé Alájọ Ṣómólú rèé, tó ta mọ́tò ra kẹ̀kẹ́?
- Ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ Donald Trump, àbúrò rẹ̀ Robert, dèrò ọrun
- Ibùdó ìyàsọ́tọ̀ ni mo wà, ló fi pẹ́ kí ń tó sọ̀rọ̀ lórí tírélà tó já l‘Eko - Omotola Jalade Ekeinde
Adele Ọba Ibulesoro ni, ipo oun ko jẹ iyalẹnu fun afeṣọna oun nitori oun ti ṣalaye fun tẹlẹ pe, oye Adele le yi kan oun ti baba oun ba papoda.
Moyinoluwa fikun ọrọ rẹ pe, oun ko gbọdọ gbe ohunkohun le ori oun tabi ki oun ṣi ori ṣilẹ, koda oun ko gbọdọ kunlẹ niwaju ẹnikankan mọ, niwọn igba t'oun wa lori oye gẹgẹ bi adele.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Moyinoluwa Falowo
Adele Oba Falowo ni oye naa ti jẹ ki oun mọ ọpọlọpọ nnkan ti oun ko mọ tẹlẹ, nipa aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba.
O ni wiwọ aṣọ ọkunrin ko jẹ nnkan to jọju f'oun nitori ohun to wa ninu aṣa ni wi pe, ọkunrin ni adele tabi ọba to wa lori tẹ gbọdọ jẹẹ.
Amọ, Moyinoluwa sọ pe, bi awọn agbalagba ṣe maa n kunlẹ tabi dọbalẹ fun oun kọkọ ri bakan lara oun, nigba ti oun ṣẹṣẹ jẹ oye naa.
- Agbára Oṣó àti Àjẹ́ yóò mú àgbéga bá ìmọ̀ ẹ̀rọ Nàíjíríà - Elebuibon
- Mi ò tí ì mọ obìnrin rí; kódà, mí ò ní 'Girlfriend'- Mr Macaroni
- Ire ṣ'ọjọ́-ìbí, Mide àti ọkọ rẹ̀ lẹ̀pọ̀, Iyabo Ojo f'aṣọ ilẹ̀ Afirika dárà
- Ilé ẹjọ́ ní kí ''Yahoo boy'' lọ darí ọkọ̀ f'óṣù mẹ́ta pẹ̀lú N50,000 owó ìtanràn
- Mọ̀ síi nípa Shina Rambo tó pàdé Jesu lọ́gbà ẹ̀wọn lẹ́yìn tó ti jalè
- Ìpànìyàn tún wáyé ní Akinyele, àwọn ará àdúgbò ṣe ìwọ́de
Ṣugbọn bayii, o ni tayọ tayọ loun maa fi n ki awọn to ba n ki oun nitori oun mọ pe, ori ade ni wọn n bọwọ fun un, kii ṣe oun gẹgẹ bi ẹnikan.
Adele Falowo tun sọ pe, ni ọpọ igba lawọn ojuṣe kan gẹgẹ bi Adele maa n tako igbagbọ oun gẹgẹ bi onigbagbọ ati ọmọlẹyin Kristi.
Amọ, o ni oun maa n yanju rẹ ni itubi inubi pẹlu awọn agbaagba oloye afọbajẹ laisi ikunsinu kankan.
Adele Ọba Ibulesoro ṣalaye pe, sisọ aṣa nu lo n ṣe okunfa iwa ifipabanilopọ to n gogo sii ni Naijiria bayii.
O ni ti aṣa ba ti sọnu, yoo jẹ ki rukerudo atawọn iwa ibajẹ maa pọ si lawujọ wa.














