Idanre kings: Ọba Aroloye ko rán ẹnikẹ́ni si Temilolu, awọn ọ̀dọ́ ìlú ló ń bínú
Laipẹ yii ni Adele Ọba Alaade ilu kan labẹ ilu Idanre, Temilolu Akinboola ṣalaye fun BBC, bi awọn janduku kan ṣe ya bo aafin rẹ ti wọn si lu u ni ilu bara.
Temilolu sọ pe, inu ile igbọnsẹ ni oun farapamọ si lọjọ naa ki awọn janduku ọhun to fi tipatikuku wọ oun jade lọ si aafin Owa ilu Idanre, Ọba Frederick Aroloye.

Oríṣun àwòrán, Temilolu
O ni wahala bẹrẹ lẹyin ti wọn fi oun jẹ Adele Ọba ti ó jẹ́ bàbá òun tan, ti wọn si ti ọja ilu Alaade gẹgẹ bi aṣa ati iṣẹṣe ilu naa ati awọn ilẹ Yoruba miran ti ọba ba wọ aja.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni "Mo gburo ọkada ti wọn pọ rẹrẹ, ti wọn n pariwo, ti wọn si n kọ orin bi ẹni to n lọ soju ogun, bẹẹ naa ni wọn n pariwo Adele da, Adele da!?.
Ọmọọba Temilolu salaye pe, lẹyin naa ni wọn gbe oun lọ si aafin Ọwa Idanre, ọba Frederick Aroloye to jẹ alakoso awọn ilu mẹta to wa labẹ rẹ.
Amọ awọn ọdọ ilu Idanre naa ti fesi lori isẹlẹ pe Owa Idanre o rán ẹnikẹ́ni si Temilolu.

Oríṣun àwòrán, Temilolu
Sùgbọn ọtọ lọrọ ṣe lasiko ti agbẹnusọ kabiyesi ti ilu Owa Idanre, ọgbẹni Kehinde Olarewaju Adesiyan salaye pe, kìí ṣe Owa Idanre lo ran awọn eniyan si ọmọọba Temilolu.
O ni bi Adele se ti ọja pa pe wọn fẹ se idaro baba rẹ to waja, ló bi awọn ọdọ ninu.
Ọgbẹni Adesiyan ni aṣa ati iṣẹṣe ko ye ọmọọba naa nitori lati ilẹ ni gbogbo eniyan ti mọ pe, Idanre ati awọn ilu to wa labẹ rẹ kii fi obinrin jẹ Adele bi ko se Lisa to dabi asoju ọba lo maa n ṣe Adele.
O fi kun pe irọ patapata ni pe wọn lu ọmọọba naa nitori gbogbo fọto to wa ni ikawọ aafin fi han pe, ko si ẹni to luu.

Oríṣun àwòrán, Owa Idanre Palace

Oríṣun àwòrán, Idanre palace