Governor's Pension: Kwara fẹ́ ṣé bí Èkó, ó dẹ́kun sísan owó ìfẹ̀yìntì fáwọ̀n Gọ́mìnà àná àti igbákejì wọn

Oríṣun àwòrán, Facebook/Saraki/Abdulrahaman
Ipinlẹ Kwara ti ṣetan lati ba ipinlẹ Eko ko anko, nipa yiyi ofin to ya owo ifẹyinti sọtọ fawọn Gomina tẹlẹ ati igbakeji wọn.
Lọjọ Ẹti ni ọrọ yii jẹyọ lati ọdọ Rafiu Ajakaiye, tii se agbẹnusọ fun Gomina Abdulrahaman Abdulrazaq.
Ajakaiye ni Gomina yoo fi aba iyipada naa ṣọwọ si awọn aṣofin lọṣẹ to n bọ, lati ṣe ayipada ofin ni kiakia.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo iye obìnrin tó bá Ginimbi ọ̀dọ́mọdé olówó kú àti obìnrin to ṣeéṣe kó jogún rẹ̀
- Èlé owó epo míì dé! Lítà epo pẹtiró di ₦155.17
- Wo ọ̀pọ̀ ìgbà tí Ginimbi ọ̀dọ́mọdé olówó ti ṣe àríyá aláṣọ funfun kó tó kú
- Ta ni olóògbé Jerry Rawlings, tí wọ́n fún ní àlàjẹ́ 'Junior Jesus'
- ''Aláàfin kìí ṣe ọkùnrin tí wàá jẹ lásán, tó sì wá sálọ - Aráàlú fèsì fún Olorì Anu
- Iléeṣẹ́ ológun sọ ikọ̀ ọdẹ́ ìbílẹ̀ JTF di ológun ní Borno, ẹ̀yà yókù ní Nàíjíríà fọnmú
''Gomina ti tẹti si ohun tara ilu sọ eyi ti o tako sisan owo ifẹyinti fawọn Gomina ati Igbakeji wọn''

Oríṣun àwòrán, facebookpage adbulrahman
''Ni ibamu pẹlu adehun ipolongo rẹ, Gomina yoo fi aba yii ṣọwọ si awọn aṣofin fun agbeyẹwo lọsẹ to n bọ''
Bẹẹ naa ni Ajakaiye sọ ninu atẹjade naa pe, Gomina ni ''yoo da ki awọn aṣofin pe ipade apero araalu lati sọ erongba wọn lori ọrọ yii''
O fi kun pe, Gomina Abdulrahman ro pe asiko ti to bayi ki wọn wọgile ofin naa, ki wọn baa le lo owo ọhun fun idagbasoke ipinlẹ Kwara.
Kwara ni ipinlẹ akọkọ to lawọn yoo tẹle ipaṣẹ Eko.
Amọ gomina ipinlẹ Delta, Ifeanyi Okowa, ti sọ ṣaaju pe oun ko ni pa ofin yii rẹ nitori Delta kii ṣe Eko.
Lọpọ awọn ipinlẹ Naijiria ni ofin to bu owo tabua fawọn Gomina ati igbakeji wọn ti wa nilẹ lẹyin ti wọn ba pari saa wọn yala ọdun mẹrin tabi mẹjọ.
Ìpinu Gómínà láti dẹ́kun owó ìfẹ̀yìntì fáwọ̀n Gọ́mìnà àná dùn mọ́mi- Bola Ahmed Tinubu

Oríṣun àwòrán, Tinubu
Asíwájú ẹgbẹ̀ òṣèlú All Progressive Congress (APC) tó tún jẹ́ gómìnà ìpińlẹ̀ Eko nígbà kan rí tí gbóríyìn fún gómìnà ìpińll Eko, Babajide Sanwo-Olu lórí ìgbésẹ̀ túntun tó gùnlé.
Lánàá òde yìí ni Gómìnà Babajide Sanwo-Olu sàlàyé pé, òun ń pinu láti kásẹ̀ òfin tó ní kí wan ma san owó ìfẹ̀yìntì fún àwọn gómìnà tó ti jẹ rí àti àwọn ìgbákeji wọ̀n.
Lọ́jọ́rú ni Tinubu fi ọ̀rọ̀ náà léde lójú òpó twitter rẹ̀ ló ti kí gómìnà ìpińlẹ̀ Eko ku oríre fún abájá bi ó ṣe ka ìsúnà owó ọdún 2021 ti o pé akọlé rẹ̀ ni títa ìrètí jí.
O ní ìgbésẹ̀ gómìnà láti fòpin si owó ìfẹ̀yìnti fún àwọn gómìnà ànà àti igbákejì wọ̀n, ó jẹ́ ìgbésẹ̀ akin tí òun si fi gbogbo ara dúró ti gómìnà lórí ìgbésẹ̀ náà.
"Mo rẹọ gbogbo àwọn gómìnà APC tó kù láti gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀"
Ìṣúná 2021 yóò ṣíjú ọ̀dọ́ kúrò nínú ìwá Yahoo-Yahoo - Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Twitter/Mr_JAGss
Gomina Babajide Sanwo-Olu ti gbe aba iṣuna oni triliọnu kan Naira le diẹ (₦1.155 Trn) fọdun 2021 kalẹ, niwaju ile aṣofin ipinlẹ Eko.
Bakan naa ni Sanwo-Olu fi erongba rẹ han, lati wọgile ofin sisan owo ifẹhinti fawọn Gomina tẹlẹ nipinlẹ Eko ati igbakeji wọn.
Lasiko to n sọrọ niwaju awọn aṣofin, Sanwo-Olu ni igbesẹ yii wa ni ibamu pẹlu ipinnu lati mu adinku ba owona ijọba.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ̀yin obìnrin, ẹ jáde du ipò ààrẹ láti gbàjọba lẹ́yìn Buhari - Amina Muhammed
- Sina Jesu ní orúkọ́ mi báyìí, ń kò jẹ́ Shina Rambo mọ́ - Adigunjalè tẹ́lẹ̀ kìlọ̀
- Agbẹjọ́rò wọ́ ìjọba lọ sílé ẹjọ́ pé kó yọ kéú kúrò lára owó Náírà
- Mọ̀ síi nípa Shina Rambo tó pàdé Jesu lọ́gbà ẹ̀wọn lẹ́yìn tó ti jalè
- Abẹ́rẹ́ àjẹsára tó dájú fún ìdènà àrùn Coronavirus ti jáde
- Wàhálà míì dé! Nupeng àti Pengassan gùnlé ìyanṣẹ́lódì
- Ààrẹ Mali tẹ́lẹ̀, Amadou Toumani Toure jáde láyé
- Làásìgbò ọ̀tun súyọ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC
- Afurasí afipábánilópọ̀ kàgbákò, obìnrin tó jà lólè fi eyín gé nǹkan ọkùnrin rẹ̀ jábọ́ lásìkò ‘Blow Job’
Ipinlẹ Eko wa lara awọn ipinlẹ Naijiria to fi ofin gbe sisan owo yii lẹyin (Payment of Pension Law 2007) ṣugbọn awọn araalu n lọgun pe owo ti wọn n san fawọn to fi ipo silẹ naa ti pọju.
Aba iṣuna ọdun 2021 ti Sanwo-Olu gbe kalẹ naa, lo pe akori rẹ ni ‘aba iṣuna to sọ ireti ji pada’.
Ninu aba naa o ni awọn yoo doju kọ pipese ohun amayedẹrun ati mimu igbe aye rọrun fawọn ọdọ nipa awọn eto orisirisi.
Fun idi eyi, o ni awọn yoo ya N9.16 billion sọtọ lati gbe oju awọn ọdọ kuro nibi iwa yahoo yahoo ati iwa ọdaran mi.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Mr_JAGss
Ẹka ọgbin, irina, aabo ati ẹkọ naa ko gbẹyin ninu awọn ti yoo jẹ ninu mudunmudun iṣuna ọdun 2021 yii.
Diẹ ree lara awọn ohun ti ẹka kọọkan yoo janfaani rẹ ninu eto isuna ọdun 2020 nipinlẹ Eko.
- Sayẹnsi ati imọ ẹrọ - 28,272,741,669.00
- Isẹ ilu gbogbo - 108,005,447,953.39
- Aabo araalu - 32,757,159,406.85
- Isẹ to jẹ mọ ọrọ aje - 381,852,747,856.72
- Ẹka eto ọgbin - 18,311,948,584.57
- Eto Okoowo - 41,989,851,318.18
- Irinajo Afẹ, Isẹ ọna ati asa - 6,012,710,830.00
- Ohun alumọọni ati amusagbara - 32,585,739,585.09
- Eto irinna - 98,931,628,325.88
- Ipese ohun eelo amayedẹrun ati isẹ ode - 172,238,545,968.00
- Oju omi gbogbo - 11,782,323,245.00
- Ayika - 50,934,105,592.09
- Ojusan Omi - 11,936,556,866.00
- Ọrọ to jẹ mọ ayika - 38,997,548,726.09
- Ilegbe ati itọju auwjọ - 40,280,489,878.68
- Eto ilera - 118,360,479,650.50
- Ọrọ ẹsin, igbafẹ ati asa - 5,170,065,144.74
- Eto ẹkọ - 143,655,493,855.89
- Aabo fun awujọ - 9,156,091,555.64Owona fun isẹ gbogbo - 136,278,189,622.39















