Amadou Toumani Toure: Ọdún 72 ló lò lókè èèpẹ̀, kó tó jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ tẹlẹ fun orilẹede Mali, Amadou Toumani Toure ti jade laye.
Ọdun mejilelaadọrin ni oloogbe naa lo loke eepẹ, ko to ki aye pe o digbose.
Aarọ ọjọ Isẹgun oni ni Toure mi kanlẹ lorilẹede Turkey nibi to ti n gba itọju lọwọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mo ti fẹsẹ̀ rìn kúrò ní Nàíjíríà àmọ́ ń kò tíì dé ibi tí mò ń lọ - DJ Switch
- Àwa olóṣèlú yóò fi ẹ̀mí wa ṣòfò, tá ba jẹ́ kí ìwọ́de ọ̀dọ́ míì tún wáyé - Lawan
- Nígbà wo gan-an ni ẹgbẹ́ òṣèlú APC yóò ṣe ìpàgọ́ àpapọ̀?
- Kí ló ń fa ikú ọ̀wọwọ̀ọ́ níjọba ìbílẹ̀ Lagelu, n‘Ibadan?
- Ẹ̀sìn ìṣẹ̀ṣe ṣún síwájú, wo orin aládùn lẹ́nu ẹgbẹ́ akọrin àti ìjèrè ọkàn tí wọn ń ṣe
- Ojúlówó Shina Rambo yọjú sígboro lọ́jọ́ Àìkú, ó fi ìka hánu lórí ìpànìyàn tó ti ṣe
- Àwọn ọ̀dọ́ Benue pa pásítọ̀ ti wọ́n fẹ̀sùn kan pé ó ń mú ǹkan ọmọkunrin
- Iléẹjọ́ mú ọjọ́ kejìdínlógún, oṣù kọkànlá fún ìgbẹ́jọ́ àwọn tó jí ìbejì Àáfà Akeugbagold ní Ibadan
Ọjọ diẹ ẹyin ni aarẹ ana lorilẹede Mali naa gunlẹ silẹ Turkey pẹlu baalu olokoowo kan to ja si olu ilu Turkey, Istanbul.
Ki Toure to kuro nilẹ Mali, si lo ti se isẹ abẹ kan nilu Bamako, eyi to nii se pẹlu aisan ọkan.
Ọdun 2002 ni aarẹ orilẹede Mali tẹlẹ naa jẹ aarẹ titi wọ osu kẹta ọdun 2012, tawọn ologun fi tipa gba ijọba lọwọ rẹ.
Ọgagun Amadou Haya Sanogo si lo lewaju iditẹ gbajọba naa.
Gbogbo agbaye si lo n kan saara si oloogbe naa pe oun lo fopin si isejọba ologun fun ọpọlọpọ ọdun ni Mali.
Bakan naa lo tun fa akoso fun ijọba alagbada lẹyin to seto idibo apapọ lorilẹede Mali lọdun 1992.
Orukọ inagijẹ ti wọn fun oloogbe Amadou Toumani Toure si ni "Ologun fun ijọba alagbada."













