EndSARS Protest Update: Ìwé ẹ̀ṣùn 50 wà nílẹ̀ bí Makinde ṣe ń fi ìgbìmọ̀ olùwádìí lọ́lẹ̀

Seyi Makinde atawọn ọmọ igbimọ oluwadi

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ẹla lọrọ, bi a ko ba la a, kii ye ni, ọrọ okeere si ree, bi ko ba le ọkan, yoo din kan.

Idi ree ti gomina ipinlẹ Oyọ, Seyi Makinde fi lo anfaani ifilslẹ igbimọ olugbẹjọ ẹsun ifiyajẹni ọlọpaa lati maa se alaye awọn ọrọ kan.

Lara alaye naa si ni pe awọn agbaagba ilẹ Yoruba to lọ sepade pẹlu ijọba apapọ laipẹ yii ko faramọ mọ aba to n gbogun ti amulo awọn oju opo idọrẹpọ lori ayelujara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bi Makindeti salaye loju opo Twitter rẹ lọjọ Isẹgun, o ni iroyin naa tako ohun ti ipade awọn asaaju ilẹ Yoruba pẹlu ijọba apapọ fi ẹnu ko le lori patapata.

Awọn ọmọ igbimọ oluwadi

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde

O ni " Igun ta duro le lori ni pe niwọn igba ti ofin to n se akoso ori ayelujara tọdun 2015 ti wa nilẹ, a ko nilo ofin miran mọ lati gbogun ti oju opo ayelujara."

Wayi o, gomina ipinlẹ Oyo naa ti sefilọlẹ igbimọ ẹlẹnu mọkanla ti yoo tanna wadi awọn oniruuru ẹsun ifiyajẹni tawọn ọlọpaa ti se fun araalu.

Adajọ agba tẹlẹ nipinlẹ Oyo, oloye Badejoko Adeniji si ni alaga igbimọ oluwadii naa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Awọn ọmọ igbimọ yoku ni Oluwole Akintayo, alaga ẹgbẹ agbẹjọro nipinlẹ Oyo, Amofin Babs Oduyoye, tii se oludamọran fun gomina lori ọrọ oselu ati arabinrin Adebobola Agbeja, tii se ọkan lara smọ igbimọ fun apapọ awọn ọdọ nilẹ wa.

Awọn ọmọ igbimọ yoku ni Olumide Akintayo, Wunmi Odutayo, Nasir Sulaiman, Mary Kolawole, Mariam Badmus, Saheed Falowo ati Olufolakemi Ogundele.

Àkọlé fídíò, Sickle Cell In Nigeria: Makinde ní ìgbàgbọ́ ninú ìdílé òun ṣèdíwọ́ láti ṣàyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀

Gomina Makinde ni iwe ẹsun aadọta lo ti wa nilẹ latọdọ awọn araalu, to si n kesi awọn eeyan ipinlẹ Oyo lati tubọ fi iwe ẹsun ransẹ si igbimọ naa.

O wa rọ awọn ọmọ igbimọ oluwadii naa lati se bo ti tọ, ati bo se yẹ lasiko ijoko wọn.

Àwa olóṣèlú yóò fi ẹ̀mí wa ṣòfò, tá ba jẹ́ kí ìwọ́de ọ̀dọ́ míì tún wáyé - Lawan

Awọn oluwọde EndSARS

Oríṣun àwòrán, Reuters

Aarẹ Ile Igbimọ Aṣofin lorilẹede Naijiria, Ahmed Lawan ti kesi awọn aṣofin, lati pese iṣẹ fun awọn ọdọ atawọn ohun amayedẹrun mii.

Lawan parọwa bẹẹ lasiko to n sọrọ nipa eto isuna ẹka ileeṣẹ ijọba to n risi eto ọgbin, ti wọn n beere fun owo to din diẹ ni ogoji biliọnu naira (N139,458, 322,208.00) ninu eto isuna Triliọnu mẹtala o din diẹ naira (N13.8 trn) ti Aarẹ Buhari gbe kalẹ fun ọdun to n bọ.

Lawan ni eto ọgbin ṣe pataki lati pese iṣẹ fun awọn ọdọ nitori ti ifẹhọnuhan miran ba tun waye ni Naijiria, awọn aṣofin ati awọn to wa ni ijọba yoo fi ẹmi wọn sofo nitori awọn ọdọ naa n fapajanu lọwọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni bi ijọba ko ṣe naani ipese iṣẹ ati ohun amayedẹrun ti yoo ran awọn ọdọ lọwọ lati ri iṣẹ se, ti wọn ko si ni ma a fi ẹsẹ gbalẹ kaakiri igboro mọ, ko dara to.

Awọn oluwọde EndSARS

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ Ile Igbimọ Aṣofin naa ni "a dupẹ pe awọn ọdọ to wa ni igboro lo ṣe ifẹhọnuhan akọkọ, ti wọn si ṣe ni irọwọrọsẹ, ki awọn janduku to gba a mọ wọn lọwọ, ti wọn si ba ohun ini awọn eniyan jẹ, ati ti ijọba.

''Nitori naa, eto isuna ọdun 2021 yẹ ko dojukọ ipese iṣẹ fun awọn ọdọ, paapaa awọn to wa ni igberiko, ki wọn ba le ri iṣẹ se, ti wọn ko fi ni ronu janduku tabi ifẹhọnuhan ti yoo doju ijọba bolẹ.''

''Ohun to yẹ ki a se ni lati lọ ba wọn ni igberiko ti wọn wa, ki a mase duro ki wọn wa si igboro, nitori ti wọn ba ri iṣẹ to dara ṣe ni igberiko, ti igbe aye wọn si ni itumọ, wọn ko ni raye janduku abi hu iwa ọdaran.''

Awọn oluwọde EndSARS

Oríṣun àwòrán, Getty Images

''Fun awa aṣofin ti wọn dibo yan, a gbọdọ le jabọ fun awọn eniyan to fi wa si ipo, awọn to jẹ pe ọpọlọpọ wọn wa ni abule, ki a si ma fi ẹtọ wọn dun wọn.''

''Nitori ti rogbodiyan miran ba tun bẹ silẹ ni orilẹede Naijiria, awọn to wa ni ipo ijọba ni yoo fori fa julọ nibẹ.''

'' Ẹ jẹ ki a lo ẹka eto ọgbin lati pese iṣẹ fun awọn ọdọ, ki aye wọn ba le ni itumọ, ki awọn naa le jẹ eniyan laye''

Ahmed Lawan

Oríṣun àwòrán, Twitter/Ahmed Lawan

Bakan naa ni Alaga Igbimọ ile asofin lori eto ọgbin, Abdullahi Adamu ni, otitọ ni ọrọ ti Aarẹ ile igbimọ asofin sọ, Ahmed Lawan, amọ o ni o pọn dandan ki ijọba fikun owo eto isuna ẹka naa, ki wọn ba le kẹsẹjari.

Ìjọba Eko fẹ́ tú olùwọ́de EndSARs 253 sílẹ̀ lọ́jọ́ Ajé nínú 361 tó wà láhàámọ́

Awọn oluwọde EndSARS

Oríṣun àwòrán, EPA

Kọmisana feto idajọ ati agbẹjọro agba nipinlẹ Eko, Moyosore Onigbanjo SAN, ti rọ ileẹjọ lati tu awọn oluwọde EndSARS silẹ.

Awọn oluwọde naa lo to ọtalerugba o din meje 253 ninu ọtalelọọdunrun ati ẹyọ kan, 361 to wa ni atimọle ọlọpaa nipinlẹ naa.

Atẹjade kan tileesẹ eto idajọ fisita fawọn akọroyin lo sisọ lori igbesẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kọmisana feto idajọ ni ẹka agbefọba nileesẹ naa ti sagbeyẹwo awọn ẹsun ti awọn ọlọpaa fi kan awọn oluwọde ọhun, ti wọn si ri daju pe wọn ko sẹ si ofin.

Awọn oluwọde EndSARS

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O ni faili ogoji to jẹ mọ awọn oluwọde ọtalelọọdunrun ati ẹyọ kan nileesẹ ọlọpaa fi ransẹ si ẹka agbefọba lọjọ kẹfa osu kọkanla ọdun 2020.

Onigbanjo salaye siwaju pe "Wọn ti sagbeyẹwo ẹsun ti wọn fi kan afurasi mọkanlelọgọjọ lọjọ naa, ti wsn yoo si fi awọn yoku ransẹ lọjọ Aje ọsẹ yii."

Lara awọn afurasi oluwọde bii ọtalelọọdunrun ati ẹyọ kan ọhun, ẹka agbefọba yoo ba awọn mejilelaadọrun se ẹjọ.

Ẹjọ naa yoo da lori awọn ẹsun to nii se pẹlu idaluru, ole jija, ile fifọ, ipaniyan ati idigunjale, nigba ti awọn afurasi bii ọtalerugba o din meje yoo gba idande.

Àkọlé fídíò, Pistachio Green Puppy: Àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláwọ̀ funfun, tí òun sì jẹ́ aláwọ̀ ewé

Àwọn ọ̀dọ́ tún ń palẹ̀mọ́ fún abala kejì ìwọ́de lọ́jọ́ Aje

Wayi o, o tun ti n rugbo bọ nidi iwọde EndSARS bayii, to si seese kawọn ọdọ tun gunle iwọde miran lọjọ Aje ọla.

Iwọde ọhun, tawọn ọdọ pe ni abala keji iwọde EndSARS lo wa lati tako iwa idunkooko ijọba atawọn agbofinro nitori iwọde akọkọ ti wọn se saaju.

Iwọde naa si ni wọn ni ko sẹyin bi banki apapọ ilẹ wa, CBN, se gbẹsẹ le apo asunwọn owo awọn oluwọde EndSARS lọjọ Ẹti to kọja.

Awọn oluwọde EndSARS

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bakan naa ni wọn tun sediwọ fun awọn oluwọde to fẹ rinrin ajo silẹ okeere lati se bẹẹ, tile ẹjọ giga kan nilu Eko si fontẹ lu asẹ ijọba naa.

Awọn ọdọ naa, ti wọn n kesi ijọba lati wọgile awọn igbesẹ ọhun ti ko ba fẹ ri pipọn oju awọn, si ti n korajọ bayii nilu Eko ati Abuja lati na tan bii owo pẹlu ijọba.