Coronavirus in Oyo: Ìjọba ní gbogbo ìpéjọpọ̀ tí kò bá tẹ̀lé òfin ìdènà àrùn ni òun yóò tìpa

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde
Ijọba ipinlẹ ti gbe ilẹkun ileẹkọ giga kan tipa nitori ajakalẹ arun Coronavirus to suyọ nibẹ.
Igbimọ amusẹya ti ijọba gbe kalẹ fun arun Coronavirus lo sawari isẹlẹ naa, ti wọn ko si kede orukọ ile ẹkọ giga ti aje ọrọ naa si mọ lori sita.
Ijọba wa leri leka pe oun setan lati tilẹkun ileẹkọ, ibudo ijọsin tabi ileesẹ to ba tako ilana to n dena arun Coronavirus pa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Díẹ̀ ló kú kí owó tán l‘ápò mi torí ìrànwọ́ Coronavirus - Pasuma
- Mo ṣèlérí láti rí sí ìrẹ́pọ̀ àti ìwòsàn Amẹ́ríkà - Joe Biden
- Bí ọwọ́jà ìjọba mi kò bá tíì dọ́dọ̀ yín, ẹ ṣe sùúrù pẹ̀lú wa- Ààré Buhari bẹ̀bẹ̀
- Agbẹjọ́ro ọ̀dọ́ sọ́rọ́ ilẹ̀ kún nìjókòó ìgbìmọ̀ tó ń ṣe ìwádìí
- Ọlọ́pàá dóòlà ẹ̀mí èèyàn 10 nínú àwọn 16 tí ajínigbépawó jí gbé l'Óǹdó
Ijọba Oyo ni awọn ibudo gbogbo gbọdọ maa tẹle ofin to dena sisun mọ ara ẹni pẹki pẹki, lilo ibomu ati ọsẹ ifọwọ, to si tun n rọ awọn araalu lati maa fi oju sọri.

Atẹjade kan ti igbimọ amusẹya ọhun fisita salaye pe, awọn igbesẹ naa pọn dandan nitori bi wọn tun se kẹẹfin ọwọja arun Coronavirus nile ẹkọ giga kan nipinlẹ naa.
Atẹjade naa ni titẹle awọn ilana to n dena Coronavirus nikan ni ọna lati dẹkun itankalẹ ati ọwọja arun naa.








