Ibadan Market looting: Ọjà ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ́ mílíọ̀nù ni jàǹdùkú kó lọ́jà Agbeni, wọ́n tún sọná sun ṣọ́ọ̀bù

Awọn osisẹ panapana n pa awọn isọ to jona

Oríṣun àwòrán, @Fedfireoyo

Awọn janduku yabo ọja Agbeni Ologede niluu Ibadan lọjọ Abamẹta, nibi ti wọn ti ji ọpọ nnkan ko ninu ṣọọbu mẹẹdogun, ti wọn si sọna si awọn ṣọọbu naa.

Iroyin ti a gbọ ni pe, ọja to to ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu owo naira lawọn janduku ọhun jigbe lọ.

Awọn kan tiẹ sọ pe, awọn janduku naa sọna sawọn ṣọọbu ọhun lati le bo iṣẹ ibi ti wọn ṣe mọlẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn to n gbe agbegbe naa, ti wọn ri eefin ina to sọ lala, ni wọn kan si ileeṣẹ panapana ipinlẹ Oyo, ni nnkan bii aago mẹfa owurọ ọjọ Abamẹta.

Awọn osisẹ panapana n pa awọn isọ to jona

Oríṣun àwòrán, @Fedfireoyo

Ṣugbọn ọga agba ileeṣẹ panapana ipinlẹ Oyo, Ọgbẹni Moshood Adewuyi ṣalaye pe, awọn janduku ọhun kọju ija si awọn panapana pẹlu ada atawọn ohun ija oloro miran nigba ti wọn de ibẹ.

Iṣẹlẹ ọhun ni a gbọ pe, o da ibẹru-bojo silẹ lagbegbe naa lẹyin tawọn eeyan n gbọ iro ibọn nigba tawọn ẹṣọ Operation Burst kọju ija si awọn janduku naa.

Àkọlé fídíò, Pistachio Green Puppy: Àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláwọ̀ funfun, tí òun sì jẹ́ aláwọ̀ ewé

Ọgbẹni Adewuyi sọ pe awọn ẹṣọ Operation Burst to koju awọn janduku naa ri pe alaafia jọba pada lagbegbe ọhun.

Iroyin kan tun sọ pe, ọwọ ti tẹ awọn meji to wa lara awọn to ṣagbatẹru iṣẹlẹ laabi yii.