EFCC: Ọkùnrin kan rí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn ún he lórí ẹ̀sùn jìbìtì 668,000 náírà

Ọkùnrin kan rí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn ún he lórí ẹ̀sùn jìbìtì 668,000 náírà

Oríṣun àwòrán, Efcc

Ọkùnrin kan rí ẹ̀wọ̀n ọdún márùn ún he lórí ẹ̀sùn jìbìtì 668,000 náírà

Ile ẹjọ kan ni ipinlẹ Sokoto ti ni ki ọkunrin kan, Umaru Isma'il, lọ fi aṣọ penpe roko ọba fun ọdun marun un gbako lẹyin to jẹbi ẹsun lilu jibiti ori ayelujara.

Ajọ EFCC fẹsun kan ọdaran naa pe o lu ẹnikan ti orukọ rẹ n jẹ Sani Musatune ni jibiti iye owo ti ko din ni 668,000 naira.

Lara ẹsun mẹjọ ti wọn fi kan Isma'il ni pe o gba owo lọwọ ẹni to lu ni jibiti lọna aitọ lẹyin to dibọn fun gẹgẹ bi ẹlomiran.

Bo tilẹ jẹ pe ọdaran naa sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun, ati pe irọ patapata ni ọrọ naa oun ko si mọwọ mẹsẹ.

Ṣugbọn nigba to n fesi, agbẹjọro ijọba, Habila Jonathan, pe ẹlẹrii mẹjọ lati fidi ẹjọ naa mulẹ, bakan naa lo tun pese awọn iwe to ṣafihan pe lootọ ni ọdaran naa wu iwa jibiti ọhun.

Nigba to n ṣedajọ rẹ, adajọ Bello Duwale ni ọdaran naa jẹbi gbogbo ẹsun mẹjọ ti wọn fi kan an.

Lẹyin naa lo ni ko lọ fi ẹwọn jura fun ọdun marun un lori ẹsun Kankan ti wọn fi kan an, yoo si maa ṣẹwọn ọhun nigba kan naa.

Adajọ ọhun tun ni ki ọdaran naa da gbogbo owo to gba lọwọ ẹni to lu ni jibiti pada, o si fi kun pe iye ọdun to yẹ ko lo ninu ẹwọn yoo le sii to ba kọ lati ṣe bẹ.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC:Wo ìrúfẹ́ ìgbeyàwó méje tó wà nílẹ̀ Yorùbá àti ojúṣe Alárinà