Canada Asylum: Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ Nàíjíríà ń bèèrè láti ṣàtìpó ní Canada

Awọn ọmọ ilẹ Canada pẹlu asia lọwọ wọn

Oríṣun àwòrán, High Commission of Canada to Nigeria

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Laipẹ la mu iroyin wa fun yin pe obinrin kan to kopa ninu iwọde Endsars, to si kede ikọlu awọn ologun ni Lekki, DJ Switch, ti ri atipo gba lọ silẹ Canada.

Lati igba ti iroyin bi DJ Switch se ja pa naa gbalẹ́ kan, ni ọpọ awọn ọdọ miran naa ti n ya lọ si ileesẹ asoju ijọba orilede Canada ni Naijiria to wa nilu Eko.

Koko ohun ti wọn si n beeere ni pe ki ijọba ilẹ Canada naa fi aaye gba awọn plu lati wa se atipo lọdọ rẹ, gẹg bo ti se fun obinrin naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oniruuru awijare lawọn ọdọ naa mẹnuba pe o mu kawọn beere fun atipo naa, eyi ti wọn lo nii nnkan se pẹlu idunkooko mọ ẹmi awọn.

DJ switch

Oríṣun àwòrán, Twitter/DJ switch

Sugbọ̀n nibayii, olu ileeṣẹ asoju ijọba orilẹ-ede Canada ti sọ pe, ilẹ naa kii ṣadeedee gbawọn aṣatipo si orilẹ-ede naa.

Ileeṣẹ asoju naa sọrọ yii nitori awon ọmọ Naijiria to fẹ ja pa bii ọkan lara awọn oluwọde EndSARS, DJ Switch to ti fi ilu silẹ bayii.

Ohun to yẹ ki o mọ nipa ṣiṣe atipo tabi ṣiṣe abẹwo si orilẹ-ede naa ree: Canada

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ileeṣẹ ọhun ṣalaye pe orilẹ-ede Canada n ṣiṣẹ pọ pẹlu igbimọ to n ri si ọrọ awọn aṣatipo ni ajọ iṣọkan agbaye, UNHCR at'awọn ẹgbẹ mii lati ṣe idanimọ awọn to nilo atipo gan an.

Ba wo ni eto atipo ṣiṣe ṣe n ṣiṣẹ lawọn orilẹ-ede agbaye?

  • Ki o to le koju oṣunwọn fun atipo ṣiṣe nilẹ, o gbọdọ jẹ wí pe ogun wa ni ibi ti o n gbe.
  • Ohun miran to tun le mu ọ ṣe atipo ni pe awọn kan n dunkoko mọ ẹmi rẹ at'awọn ẹbi rẹ.
  • Ṣugbọn wọn kìí ṣaaba ṣe ifọrọwanilẹnuwo fawọn to ba ṣatipo lasiko rogbodiyan tabi laaṣigbo, ki wọn to fun wọn laye lati ṣe atipo.

Mo ti fẹsẹ̀ rìn kúrò ní Nàíjíríà àmọ́ ń kò tíì dé ibi tí mò ń lọ - DJ Switch

Aworan DJ Switch

Oríṣun àwòrán, dj_switchaholic

Nibo ni DJ Switch wa? Se o ti sa kuro ni Naijiria ni? Orilẹede wo lo wa gan, ati pe, ta lo n dunkooko mọ ẹmi rẹ?

Eyi ni ibeere to gba ẹnu awọn ọmọ Naijiria kan nipa obinrin yii, DJ Switch, ẹni to tu asiri fun araye nipa ikọlu ologun sawọn oluwọde EndSARS ni Lekki ni ogunjọ osu Kẹwa ọdun 2020.

Bi wọn ba sọ fun awọn eeyan pe wọn wa ibi ti Obianuju Catherine Udeh wa, o ṣeese ki ọpọ maa beere pe ta lo n jẹ bẹẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣugbọn bi a ba ti fi inagijẹ DJ Switch kun ibeere yii, ko ni jẹ ohun iyalẹnu nitori ọpọ lo gba ori ayelujara ni Naijiria lọ ti wadii nipa akọni obinrin naa.

Awọn oluwọde EndSARS

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Eyi ko si ṣẹyin bi iroyin ti ṣe gbode pe, gbajugbaja gbajumọ ori ayelujara ati DJ yii ti sa kuro ni Naijiria lọ si orilẹede Canada.

Bawo lo ṣe de kuro ni Naijiria ati pe nigba wo lo lọ?

Ninu iroyin to tẹ wa lọwọ eyi ti ileeṣẹ Iroyin Naijiria Punch gbe jade, amugbalẹgbẹ akọrin takasufe Peter Okoye ta mọ si Mr P fidi ọrọ mulẹ fun ileeṣẹ iroyin naa pe, DJ Switch ti kuro ni Naijiria

Ninu ifọrọwerọ naa pẹlu Charles Abi, o ni lootọ ni pe alaafia ni DJ Switch wa ati pe o ti rinrinajo kuro ni Naijiria.

Amọ ṣa, arakunrin Abi ko sọ ibi ti DJ Switch ka nlẹ lọ.

DJ Switch

Oríṣun àwòrán, djswitch_

Abi ni nitori idunkoko mọ ẹmi ti DJ Switch ni Naijiria ati aabo ti ko si fun ẹmi rẹ, lo mu ko tete sa asala fun ẹmi rẹ.

''A ko fẹ sọ nnkankan lasiko yii, ootọ ọrọ ibẹ si ni yẹn. Ọrọ idunkoko lọrọ taa n wo yii nitori wọn ti n dun koko mọ pupọ.

Ootọ ibẹ ni pe, DJ Switch ko si ni Naijiria lọwọ yii. A o ni sọ boya Canada lo wa ṣugbọn ko si ni Naijiria bayi ati pe alaafia lo wa.''

Nipa iroyin to gbode pe DJ Switch ba awọn aṣofin ilẹ Canada sọrọ, Abi ni oun ko le sọ boya bẹẹ lo ri.

''Mi o le sọ fun yin pe o sọrọ niwaju ile aṣofin ilẹ Canada amọ bi ẹ ba ri ti ile aṣofin Canada fi ọrọ to jọ mọ bẹẹ sita, a jẹ pe o ri bẹẹ ni yẹn.

Ọga mi ti kilọ fun mi pe, ki n ma kọ nkankan si oju opo rẹ, bi asiko ba to, yoo sọrọ''

Awọn oluwọde EndSARS

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ohun ti BBC ṣe iwadii ree:

Iwadii BBC ṣafihan pe DJ Switch ko kọ nkankan si oju opo rẹ lati le tọka ibi to wa.

Ṣugbọn a ri fọnran fidio ipade igbimọ ile asofin Canada kan to n gbẹjọ nipa ẹtọ ọmọniyan nilẹ okeere eyi to waye lọjọ Kẹfa oṣu Kọkanla ọdun yii.

Ninu fidio naa ti wọn gbe soju ayelujara, ni DJ Switch ati awọn ẹlẹri mii bi Osai Ojigho ti Amnesty International ti sọrọ.

Tim Okafor ati Stella Nkemdimrim to ṣoju awọn ọmọ ẹgbẹ Biafra to wa ni Canada ati Abdulrazaq Namdas ṣalaye fun alaga igbimọ naa, Peter Fonseca, nipa ohun to ṣẹlẹ ni Naijiria sawọn oluwọde ENDSARS.

Ko si ohun to tọka si pe Canada ni DJ Switch wa nigba to kopa ninu ipade yii ṣugbọn o sọ ninu fidio naa pọnbele pe, oun ti kuro ni Naijiria.

Aworan DJ Switch

Oríṣun àwòrán, Screenshot/parlvu.parl.gc.ca/

Bakan naa akọrin takasufe P Square to jẹ ọga Charles Abi, naa ṣẹnu pẹmu, ti ko si sọ nkankan to jọ mọ ọrọ DJ Switch loju opo rẹ.

Yatọ si awọn arigbamu yii, ijọba Naijiria naa ko ti sọ boya bi Switch ti sa kuro nilu de eti igbọ wọn ati iru igbeṣẹ ti wọn fẹ gbe nipa rẹ.

Bi a ko ba gbagbe DJ Switch wa lara awọn to lewaju iwọde ENDSARS, ti o si ṣalabapin fọnran fidio to ṣafihan bi awọn eeyan ṣe n rọ yika oluwọde kan ti wọn yinbọn lu ni Lekki.

Awọn oluwọde EndSARS

Oríṣun àwòrán, EPA

Bo tilẹ jẹ pe ijọba ti jade lati sọ pe awọn ko dena mọ oluwọde kankan lati maṣe rinrinajo kuro nilẹ Naijiria, amọ ijọba gbe igbesẹ kan laipẹ yii to fi han pe, o ṣeeṣe ki wọn maa dunkoko mọ awọn to ni nnkan ṣe pẹlu iwọde naa.

Bi a ko ba gbagbe, Modupe Odele agbẹjọro awọn oluwọde naa ṣalaye pe, awọn oṣiṣẹ ajọ to n risi iwọle-wọde da oun pada ni papakọ ofurufu Murtala Mohammed ni Eko lasiko to fẹ rinrinajo kuro ni Naijiria.

O ni wọn pada da iwe irinna oun pada ṣugbọn oun ko ribi ba baalu to yẹ fun irinajo naa lọ.

DJ Switch

Oríṣun àwòrán, djswitch_

Bẹẹ naa tun ni ile ifowopamọ agba Naijiria CBN, gbegi le asunwọn owo awọn oluwọde kan to fi mọ Rinu Oduala ati Majekodunmi Temitope, ti wọn n ṣoju ọdọ nibi ijoko igbimọ iwadii ti ijọba Eko gbe kalẹnipa iwa ọlọpaa EndSARS.

Awọn mejeeji ti tori igbesẹ naa binu kuro ninu igbimọ ọhun.