Balarabe Musa: Kókó ohun márùn-ún nípa gómìnà Kaduna tẹ́lẹ̀ tó dólóògbé

Aworan Balarabe Musa

Oríṣun àwòrán, Hutudole

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Iroyin iku agba ọjẹ oloṣelu Balarabe Musa jẹ eleyi ti o fọwọ kan ọpọ lẹmi ni Naijiria.

Ninu awọn ti wọn jọ jẹ irọ, Balarabe ni o fẹ ṣẹku ninu oloṣelu ti ko fi ọrọ isọkan ati idagbasoke Naijiria ṣere rara.

Lootọ, ohun ti ọpọ yoo ranti nipa Balarabe Musa ni pe oun ni Gomina alagbada akọkọ ninu akọsilẹ orilẹede Naijiria, ti wọn yọ kuro nipo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣugbọn ti eeyan ba ṣe iwadii daada yoo ri pe awọn nkan manigbagbe mii wa to ya Balarabe sọtọ laarin awọn oloṣelu ẹgbẹ rẹ ni Naijiria.

Oluṣiro ati olukọni ni Balarabe Musa jẹ:

Ninu awọn ọmọ Naijiria to n duro gẹgẹ bi alatako fawọn olori ti ko ba ṣejọba daada ni Naijiria, ni Balarabe Musa wa.

Lati igba to ti bẹrẹ irinajo rẹ lagbo ọṣelu lo ti n tako awọn to wa ni ijọba, to si maa n ṣapejuwe awọn olori gẹgẹ bi ẹni to n ṣe ijọba fun anfaani awọn to ri jajẹ lawujọ nikan.

Balarabe Musa ati Buhari ti ṣe pọ nigba kan ri:

Ohun manigbagbe kan ti a tun le tọka si nipa Balarabe Musa ni pe o ti fi igba kan gbaruku ti aarẹ Muhammadu Buhari ninu idibo aarẹ ọdun 2007.

Gẹgẹ bi alaga fun agbarijọpọ ẹgbẹ oṣelu ni Naijiria, CNPP, Musa ni Buhari jẹ ẹni t'eeyan le f'ọkan tan ju Umaru Musa Yar Adua ẹgbẹ PDP.

Amọ ṣa, nigba ti Buhari naa yoo fi di aarẹ, Balarabe ko ṣẹnu ku lati tako ijọba rẹ.

Àkọlé fídíò, Sickle Cell In Nigeria: Makinde ní ìgbàgbọ́ ninú ìdílé òun ṣèdíwọ́ láti ṣàyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀

PRP ni ẹgbẹ to ṣe to fi fẹyinti nidi oṣelu:

Agba ọjẹ oloṣelu nii, Aminu Kano lo da ẹgbẹ Peoples Redemption Party PRP silẹ nigba aye rẹ.

Ọrọ akọmọna ẹgbẹ yii to ni mimu aye dẹrun fawọn alaini lawujọ, jẹ eleyi ti Balarabe Musa nifẹ si.

Idi ree ti o fi dije dupo labẹ asia ẹgbẹ naa ni ọdun 1979.

Balarabe jẹ olori ẹgbẹ Peoples Redemption Party ni saa oṣelu awarawa ikẹrin ni Naijiria.

O jẹ oludije ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ naa ninu idibo to waye lọdun 2003 ṣugbọn airi owo tẹ iwe ikede ipolongo ara ogiri ṣakoba fun erongba rẹ lati fi di aarẹ.

Nigba ti ipenija ilera de ba lo fi ipo olori ẹgbẹ naa silẹ lọdun 2018.

Balarabe Musa ko faramọ idasilẹ ikọ Amọtẹkun:

Idasilẹ ikọ alaabo lawọn ipinlẹ kaarọ o jiire jẹ ọkan lara ohun ti Balarabe bẹnu atẹ lu.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin, o ṣalaye pe ''ọna ati fidi orilẹede Oduduwa Republic mulẹ'' lawọn to ṣe idasilẹ ikọ alaabo yii n wa.

Aworan Balarabe Musa ati Wole Soyinka

Oríṣun àwòrán, Twitter/ShehuSani

Ọrọ rẹ yii ko dun mọ awọn agba Yoruba ninu, ti ọjọgbọn Wole Soyinka si sọ pe Balarabe kuna pẹlu ọrọ to sọ yii.

Toun ti bẹẹ, Balarabe pada sọ pe nitori ifẹ Naijiria loun fi sọ bẹẹ ati pe oun ko fẹ maa ba ẹnikẹni takurọsọ nipa idasilẹ ikọ yii.

Ko figba kan dakẹ lori eto atunto Naijiria - 'Restructuring'

Loore koore ni Balarabe Musa a maa sọrọ nipa bi nkan ṣe n lọ ni Naijiria.

Ni pataki Musa a maa bawọn pe fun atunto Naijiria lọna ti gbogbo ẹkun to wa ilẹ yii yoo fi jẹ anfaani iṣejọba.

Lara ohun to sọ sẹyin ni pe ki ba da ti Naijiria ba pada si iṣejọba ẹlẹkunjẹkun mẹfa bi ti atijọ.

Koda o tun kesi awọn ọmọ ilẹ Naijiria lati gbera nlẹ ṣe ijijagbara ti yoo ko wọn yọ lọwọ ijọba All Progressives Congress, APC to wa lori oye.

Balarabe Musa

Oríṣun àwòrán, Hutudole

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe gomina ana nipinlẹ Kaduna, Balabe Musa ti jade laye.

Ọdun mẹrinlelọgọrin ni Balarabe Musa lo loke eepẹ, ko to jẹ Ọlọrun nipe.

Iroyin iku Musa ni sẹnatọ Shehu Sani fi si oju opo Twitter rẹ ni aarọ ọjọru.

Sani wa gbadura pe ki Oluwa fi ori jin ẹni re to lọ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Osu Kẹwa ọdun 1979 ni Balarabe Musa wọle sipo gomina nipinlẹ Kaduna gẹgẹ bi gomina alagbada akọkọ nipinlẹ naa.

Amọ ti wọn yẹ aga mọ nidi lọjọ Kẹtalelogun osu Kẹfa ọdun 1981 gẹgẹ bii gomina, eyi to mu ko jẹ gomina alagbada akọkọ ni Naijiria ti wọn yoo yọ nipo.

Ọjọ Kọkanlelogun osu Kẹjọ ọdun 1936 ni wsn bi Balarabe Musa sile aye silu Kaya nipinlẹ Kaduna.

Gbogbo ọmọ Naijiria ni yoo mọ ipa Balarabe Musa lara nitori ọpọ igba lo maa n sọrọ tako awọn iwa kotọ ti ijọba to wa lori oye n hu.

Balarabe Musa kii si se ẹni to n fi ẹya tabi ẹsin se ninu ọrọ rẹ.