Afghanistan: Àwọn adájọ́bìnrin ní àwọn Taliban táwọn fi sí àhámọ́ ń lépa ẹ̀mí àwọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọpọlọpọ awọn adajọ obinrin ni orilẹede Afghanistan lo ti parọ foonu wọn ati nọmba wọn nitori awọn to n dunkoko iku mọ wọn.
O kere tan, awọn adajọ obinrin to le ni igba lorilẹede Afghanistan ti sa asala fun ẹmi wọn lọwọ awọn Taliban.
Iwadii BBC lo fi eyi lede lẹyin ti wọn ba awọn adajọ obinrin meje sọrọ ni ipamọ ti wọn wa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìpanu ''small chops'' ló mú kí sọ́jà da omi ìdọ̀tí lé mi lórí - Corper Fidelia
- Adigunjalè kọlu báǹkì ní Iragbiji l'Osun, ìlú dàrú
- Ìwọ̀fà lẹnu, ààrẹ gbọ́dọ̀ wá láti Gúúsù ní 2023 - Akeredolu
- Ìgbẹ́jọ́ ti bẹ̀rẹ̀ lórí ẹ̀sùn Baba Ijesha àti Princess tó ní ó fẹ́ bá ọmọ òun lájọṣepọ̀
- Sotitobire pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ẹ̀wọ̀n gbére
Lasiko ti BBC n ba awọn adajọ mẹfa sọrọ lati agbegbe ti wọn wa, ni awọn marun un ninu wọn sọ nkankan naa ti wọn n la kọja.
Gbogbo awọn adajọ naa ni wọn ti gba atẹjade, lẹta ati atẹjiṣẹ to n dunkoko mọ wọn pe awọn n bọ lati wa pa wọn ati ẹbi wọn.
Awọn adajọ naa ni lara awọn mẹrin to dunkoko mọ wọn jẹ awọn ọdaran ti wọn ti sọ sẹwọn tẹlẹ nitori wọn jẹbi pipa iyawo wọn.
Awọn obinrin wọnyii ni wọn n dajọ lati doola ẹmi awọn obinrin, tabi lati fi iya to tọ jẹ awọn ọkunrin to ba jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.
Lara awọn obinrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Masooma ni, oun ti ran ọpọlọpọ ọkunrin lọ si ẹwọn, lẹyin ti wọn jẹbi lilo ipa pẹlu obinrin, to fi mọ ẹsun ifipabanilopọ, ipaniyan ati ifiyajẹni.
Amọ, wẹrẹ ti awọn Taliban gba ijọba bayii ni wọn ti bẹrẹ si ni ranṣẹ iku si obinrin adajọ ọhun nitori awọn Taliban tu gbogbo afurasi ati ọdaran to wa ni ẹwọn silẹ, boya wọn jẹ Taliban tabi ẹlẹwọn miran.
''Oru ni a gbọ pe awọn Taliban ti tu awọn ẹlẹwọn silẹ ninu tubu, bi a ṣe bẹrẹ si ni sa asala fun ẹmi wa niyẹn.''
''Aṣọ ti a ma n da bo oju, Burka ni mo wọ, ti wọn ko fi da mi mọ, ti a fi kọja laarin ilu, amọ a ko le lọ si ibi kankan nitori kii ṣe gbogbo mọlẹbi mi loni iwe irinna oke okun''
''Lara awọn ti mo ran lọ si atimọle ni ọkunrin kan to pa iyawo rẹ, ti mo si ran lọ si ẹwọn ogun ọdun.''
''Amọ, nigba to jade kuro ninu ẹwọn naa, o ranṣẹ si mi pe oun ti gba gbogbo iwe ẹri mi ati pe bi oun ṣe pa iyawo oun, ni oun yoo pa emi naa.''
Nibayii, ọpọlọpọ awọn adajọ yii lo ti paarọ nọmba ipe wọn nitori awọn to n dunkoko iku mọ wọn.
Bakan naa ni wọn n gbe ni ipamọ, ti wọn si n kuro ni agbegbe kan lọ si omiran lati sa asala fun ẹmi wọn.
Ninu idahun si ibeere pe ṣe lootọ ni wọn n wa awọn adajọ lati pa wọn, ikọ aṣoju Taliban, Bilal Karimi ni iwadii yoo bẹrẹ lori ẹsun naa.
O ni awọn adajọ naa ni anfaani lati gbe igbe aye irọrun bi awọn araalu to ku.
Karimi ni ikọ Taliban ko gbagbe ileri ti wọn ṣe pe awọn yoo dariji awọn oṣiṣẹ ijọba to ṣiṣẹ tako wọn.
- Kíláàsì wó lé ọmọ ilé ẹkọ́ mẹ́ta lórí, ọ̀kan ti kú, ẹ wo ohun tó ṣe méjì tó kù
- Ìran mi ò ja ẹ̀ṣẹ́ rí, ẹ̀gbin yìí ló ta lé mi tí mo fi di "Scorpion" Ọ̀gá ọ̀gá nínú ìjà
- "Láí fábàdà, a kò pín ipò ààrẹ sẹ́kùn gúúsù ní 2023"
- Ọlọ́pàá kan d'àwátì l'Ogun, ẹbí rẹ̀ fẹ́ gbé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lọ sílé ẹjọ́
- Àlàyé rèé lórí bí sọ́jà ṣe lu àgùnbánirọ̀ obìnrin, tó da omi ìdọ̀tí le lórí
Amọ, ikọ Taliban ni awọn ti ọwọ ba tẹ, ti wọn n gbe ogun oloro tabi hu iwa aitọ yoo foju wina ofin.
Nibayii, ọjọ iwaju awọn obinrin lorilẹede Afghanistan ko daju nitori wọn ko gba ki wọn lọ si ileewe tabi ṣiṣẹ.
Bakan naa ni iko Taliban si ni awọn n ṣe agbeyẹwo ipa ti awọn obinrin yoo le ko ni awujọ Afghanistan.














