Adunni Ade: Kò dára kí ọkùnrin máa fi ‘Microphone’ sí ara obìnrin lásìkò eré tíátà

Adunni Ade

Oríṣun àwòrán, iamadunniade/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Adunni Ade ti ko aroye bẹnu lori bi amoju ẹrọ agbohunsafẹfẹ kan, se fi ibalopọ lọ oun lasiko ti wọn n ṣe ere sinima kan.

Ẹni ọdun mọkandinlogoji yii ṣalaye ọrọ naa ninu fidio kan to gbe soju opo Instagram rẹ.

Adunni ni ẹni naa, ti ko darukọ rẹ, ta omi oge si oun lara lọna aitọ lasiko to fẹ fi ẹrọamohunbugbẹmu (microphone) si oun lara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adunni Ade fi kun ọrọ pe, iṣẹlẹ yii lo mu ki oun maṣe faaye gba ẹnikẹni ninu awọn ọkunrin amoju ẹrọ lati fọwọ kan oun mọ.

O ni "Mi o ki n faaye gba awọn ọkunrin amoju ẹrọ agbohunsafẹfẹ fọwọ kan mi nitori ọkan ninu wọn lo nawọ ere ifẹ si mi lọna aitọ''

Àkọlé fídíò, Ṣé ìwọ mọ̀ pé Olodumare lè lo Aje láti gbé ẹ lọ síbi ire?- Abiodun Fatomilola

Se lo ti ọwọ bọ inu asọ kaba ti mo wọ̀, to si na ọwọ rẹ de ibi ibadi mi lori awijare pe oun fẹ́ fi mic si mi lara.

Eyi mu ki n fẹrẹ daku, ti mo si gan sibẹ, koda, o gba mi ni akoko diẹ ki n to sọrọ sita, mo si n pariwo pe ki lo de se tun fi ọwọ kan mi lẹyin ti mo ti kilọ fun saaju tẹlẹ pe ko mase fi ọwọ kan mi mọ.

Se ni ara mi n gbọn, ti mo si n pariwo pe iru ẹni bẹẹle fi tipa ba eeyan lopọ nitori pe o fi ọwọ kan mi ni ibi ti ko ba mi lara mu."

Arẹwa oṣere tiata yii tun ṣalaye pe oun gbiyanju lati fi ọrọ naa to awọn alaṣẹ ẹgbẹ awọn leti ṣugbọn oun yi ipinnu naa pada nigba tawọn eeyan ki ẹbẹ mọlẹ.

"N ṣe ni ẹni taa n wi yii ko agidi bori pe oun ko ṣe nkankan to buru. O fi ọwọ rẹ bọ mi lẹyin nitori pe o ni oun fẹ fi mic si mi lara''

''Ohun ti ko bojumu leyi jẹ fun mi.

Iṣẹlẹ ibalopọ tabi awọn aṣemaṣe miran jẹ eleyi tawọn oṣerebinrin tiata a maa koju nidi iṣẹ wọn."

Adunni Ade ni ọkunrin amojuẹrọ yii ko bẹbẹ tabi tọrọ aforijin lọwọ oun titi di akoko yii ti oun si fi ọrọ naa to agbẹjọro oun leti.

O ni oun ko tii fẹ gbe ọkunrin naa lọ sile ẹjọ bayii amọ to ba tun hu iru iwa yii tabi ta ko ohun lori isẹlẹ yii, oun se tan lati ba fa a gidi.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Adunni ni koda lawọn agbo oṣere tiata to gbajugbaja bi Hollywood, ọpọ awọn obinrin lo ti ke gbajare pe awọn ọkunrin a maa fi ilọkulọ lọ awọn nidi ere tiata.

O salaye pe nilẹ okeere, ko si ọkunrin onimọ ẹrọ ti wọn n gba laaye lati lọ fi ẹrọ amohunbugbẹmu si ara obinrin osere tiata lara lasiko igbaradi fun ere sise.

O wa gba awọn osere tiata atawọn onimọ ẹrọ wọn to n wo ilẹ Amẹrika fun awokọse nimọran pe ki wọn se awokọse ohun to dara lara wọn.

Bakan naa lo tun gba awọ̀n eeyan nimọ̀ran lati maa sọrọ soke nigba ti ohunkohun ko ba tẹ wọn lọrun, wọn ko si gbọdọ dakẹ lasiko ti ẹnikẹni ba se ohunkohun ti ko dara.

Àkọlé fídíò, Adeyemi Olubunmi Crown: Láti ìgbà ti mo ti fún ọkọ mi ni ẹ̀bùn mọ́tò ni ìfẹ́ wa ti yàtọ̀