Sunday Igboho‘s Birthday: Àwọn olólùfẹ́ Igboho rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba Benin láti tú u sílẹ̀, wọ́n ní Ó ń jà fún ìran rẹ̀ ni, kìí ṣe apànìyàn
Ni ọjọ Aiku lawọn ọmọ ẹyin, ara, ẹbi ati ọrẹ eekan lara awọn to n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho, ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun kọkandinlaadọta rẹ.
Wọn fi ile pọn ọti fi ọna roka, ṣugbọn wọn ko gbagbe lati fi asiko naa rawọ ẹbẹ fun itusilẹ Sunday Igboho.
- "Ará Cotonou, Sunday Igboho kò gbọdọ̀ kú sọ́dọ̀ wa o, ó ti wà nílé ìwòsàn báyìí"
- Obìnrin mẹ́fà àti ọmọ wẹ́wẹ́ mẹsan sá ní àhámọ́ Boko Haram lẹ́yìn oṣù mẹ́fà
- Wo àṣírí nkan tó gba ẹsẹ̀ kan lọ́wọ́ Jigan Baba Oja
- Awò ojú tí mò ń lò kìí ṣe akọ tàbí ìgbéraga, ohun tó fà á rèé - Helen Paul
- Buhari, ohun ìjà tó ń kójọ ni wọn yóò lò láti rẹ́yìn Nàíjíríà - Fr Mbaka
Sunday Igboho ṣi wa ni ahamọ ofin lorilẹede Benin Republic lẹyin ti wọn mu ni oṣu diẹ sẹyin lasiko to n gbiyanju lati gba orilẹede Benin lọ si orilẹede Germany.
Awọn omọlẹyin rẹ to ba BBC News Yoruba sọro ṣalaye pe Sunday Igboho kii ṣe janduku, ọdaran tabi apaniyan gẹgẹ bi awọn alaṣẹ Naijiria ṣe n sọ.
Wọn ni ọṣẹ kan ṣoṣo ti wọn lee sọ pe o ṣẹ naa ni pe o n gbiyanju lati gba awọn eeyan rẹ lọwọ awọn agbenipa ti wọn n wọle wa pa wọn lori ilẹ baba nla wọn.
Sunday Igboho, àwa Yoruba Nation kò gbàgbé rẹ sí àhámọ - Akintoye
Ọjọ Kini, Oṣu Keje, ọdun 2021 ni Sunday Igboho wọ gau pẹlu ijọba Naijiria lẹyin ti Ajọ DSS ṣe ikọlu si ile rẹ, ti wọn si tun kede pe wọn n wa.
Adari ẹgbẹ ọmọ Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye ti kesi ajijagbara ilẹ Yoruba, Sunday Igboho pe ko fi ọkan balẹ nitori ko si ẹni to gbagbe rẹ.
Akintoye sọ eyi lati ba a ṣe ajọdun ayajọ ọjọ ibi rẹ to pe ẹni ọdun mọkandinlaadọta.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Seyi Makinde pe olóyè PDP lẹ́jọ̀ fún ìbanilórúkọ jẹ́ lórí Facebook
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara dá ọ̀gá ilé Keu tí wọ́n ti lu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bí i bàrà dúró
- Buhari, ohun ìjà tó ń kójọ ni wọn yóò lò láti rẹ́yìn Nàíjíríà - Fr Mbaka
- A kò da iṣẹ́ sílẹ̀ mọ́, ó di ọjọ́ míì, ọjọ́ re - IPMAN, PTD
- "Èmi ni mo sọ fáwọn ọ̀gá ilé Keu pé kí wọ́n lu ọmọ mi bí ẹran"
Agbẹnusọ fun Akintoye, Maxwell Adeleye lo fi eyi lede ninu atẹjade ti wọn fi lede fun awọn oniroyin.
Akintoye ni ija ilu ni Sunday Igboho n ja ti ọpọlọpọ araalu si fẹran rẹ nitori naa wọn ko le e gbagbe rẹ titi lai.
''Sunday Igboho duro ti awọn eniyan rẹ, ko si si ẹni to duro ti awọn eniyan rẹ to ri idojuti lailai, nitori naa ko si ẹni to le e fi ẹyin Sunday Igboho janlẹ.''
''Nitori naa gbogbo ọmọ Yoruba labẹ Ilana ọmọ Odua n ki Sunday Igboho ku ayẹyẹ ọjọ ibi ẹni ọdun mọkandinlaadọta.''
''O da wa loju pe ọjọ ibi ẹni ọdun aadọta rẹ yoo jẹ ninu ayọ ati idunnu, ti wọn yoo si ṣe ayẹyẹ rẹ kaakiri agbaye, nitori eyi kii ṣe opin irinajo rẹ.''

Oríṣun àwòrán, @sunday_igboho1
Bakan naa ni Aarẹ Ọna Kakanfọ ti ilẹ Yoruba, Gani Adams naa ki Igboho ku ayajọ ọjọ ibi rẹ, to si rọ ijọba orilẹede Benin Republic lati fi Sunday Igboho silẹ ni kiakia.
Ninu ọrọ tirẹ, Adams ni ipe fun itusilẹ ẹya eniyan ko le e pin lailai bi ijọba tilẹ dunkoko mọ wọn fun ọpọlọpọ ọdun.''
- Agbẹjọ́rò wọ́ ìjọba lọ sílé ẹjọ́ pé kó yọ kéú kúrò lára owó Náírà
- Buhari, ìwé òfin 1999 ni ìparun Naijiria, tètè fà á ya - Tunde Bakare
- Gómìnà Yoruba, ẹ dúró lé ìjọba àpapọ̀ lọ́rùn pé kó fi Sunday Igboho sílẹ̀ - Gani Adams
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara dá ọ̀gá ilé Keu tí wọ́n ti lu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bí i bàrà dúró
- Ìdí rèé tí mo fi gbà kí ọkọ mi má a ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìyá àti àbúrò mi
''A ko mikan lori ohun ti a fẹ, ti a si ni ẹrongba wi pe bo pe, bo ya, a o gba idajọ ododo, ti ohun gbogbo ti a fẹ ni ilẹ Yoruba yoo si wa si imuṣẹ.''
''Ẹmi naa ti ṣe ọjọ ibi ni ẹwọn ri, ti ohun gbogbo si le koko nigba naa lọhun, amọ mọ gboju soke si Ọlọrun lati tu mi silẹ, ki idajọ ododo si jọba. Laipẹ si igba naa, o si wa si imuṣẹ.''
''O ṣeni laanu pe nkan naa n ṣẹlẹ si Igboho lọwọlọwọ lasiko to pe ẹni ọdun mọkandinlaadọta, amọ o dami loju pe ododo yoo leke , ti yoo si gba itusilẹ laipẹ.''
''Nitori pe kii ṣe ija ara rẹ ni Igboho n ja, ija gbogbo ilẹ Yoruba lo n ja, nitori naa yoo gba itusilẹ laipẹ.''
Ọjọ Kini, Oṣu Keje, ọdun 2021 ni Sunday Igboho wọ gau pẹlu ijọba Naijiria lẹyin ti Ajọ DSS ṣe ikọlu si ile rẹ, ti wọn si tun kede pe wọn n wa.
Lẹyin naa ni wọn fi panpẹ ọba mu ni orilẹede Benin Republic, ti wọn si fi si ahamọ lati igba naa titi di asiko yii.

Ilé Sunday Igboho ń gbàlejò ọ̀pọ̀ ọmọ Yorùbá tó fẹ́ sàmì ayẹyẹ ọjọ́ ìbí lẹ́yìn rẹ̀
Pọpọ sinsin igbaradi fun awọn eto lati sami ayẹyẹ ọjọ ibi ajijagbara fun ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Igboho ti n lọ lọwọ nile rẹ to wa niluu Ibadan.
Oni ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 ni Igboho pe ẹni ọdun mọkandinlaadọta loke eepẹ.
Bo tilẹ jẹ pe ajijagbara naa ko si nile rẹ naa, to si wa ni ọgba ẹwọn nilu Cotonou, sibẹ pupọ awọn ọmọ Yoruba ni Naijiria ati kaakiri agbaye lo ti bẹrẹ si n ki ku oriire ayẹyẹ ọjọ ibi naa.
- Wo ewu tó wà fún ìyálamọ tó ń jẹ olúbi ọmọ lẹ́yìn ọjọ́ ìkúnlẹ̀
- Ẹ múra o, ọ̀wọ́n gógó epo bẹntirolú bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Ajé nílẹ̀ Yorùbá
- Wo ìtàn ayé Sunday Igboho, gbajúmọ̀ ajìjàgbara fún ilẹ̀ Yorùbá
- Ìgbagbọ́ mi nínú Nàíjíríà kò yinjẹ, ìrètí mi nípa ọjọ́ ọ́la wa sì le koko - Obasanjo
- Buhari, fa iwé òfin ọdún 1999 ya, ko sì pe ìpàdé àpérò aráàlú - Yorùbá VOR
- Àwàdà lásán ní Adeleke ṣe nípa ọ̀rọ̀ bàálù, kò sí òótọ́ níbẹ̀ - Ooni Ife
- Wàládè dé! Àwọn obìnrin aṣaralóge wọ gàù ikọ̀ Taliban ní Afghanistan
- Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ń se ọbẹ̀ tó máa ń fún wọn ní ìbejì ní Igbo-Ora
- Owó yíyá kò kọjá àfaradà tí a bá ti lò ó dáadáa- Aarẹ Buhari
Lootọ ni pe igboho wa ninu ọgba ẹwọn niluu Cotonou, iyẹn lorilẹ-ede Benin bayii, ṣugbọn ọpọ awọn eeyan lo ti bẹrẹ si n fi adura ranṣẹ sii.
Lọwọ yii awọn Alafaa ti wa nile rẹ ọhun, nibi ti wọn ti n palẹmọ fun adura ayajọ ọjọ ibi rẹ naa.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ fun oloye Sunday Igboho, Olayomi Koiki ti kede loju opo Facebook rẹ, aago meje alẹ ọjọ Aiku oni ni adura ati ayẹyẹ ọjọ ibi naa yoo waye.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kinni, oṣu keje ọdun 2021 yii ni ijọba Naijiria gbiyanju lati fi panpẹ ofin mu Igboho nile rẹ.
Loru ọjọ naa ni ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ba dukjia olowo iyebiye jẹ nile rẹ ọhun, wọn pa eeyan meji, wọn tun fi ṣikun ofin mu awọn mejila miran.

Oríṣun àwòrán, Olayomi Koiki
Lati igba ti ijọba Naijiria ti n gbiyanju lati fi Igboho si atimọle, awọn agbagba Yoruba kan bii Ọjọgbọn Banji Akintoye atawọn agbẹjọro rẹ ti n gbiyanju lati ri daju o bọ ni ahamọ ijọba ilẹ Benin to wa.
Ewe, ọkan lara awọn agbejọro rẹ, Ibrahim Salami ṣo fun BBC Yoruba pe oun gbagbọ pe didun ni ọsan yoo so lori ọrọ rẹ to wa nile ẹjọ Cotonou laipẹ.





















