Boko Haram: Obìnrin mẹ́fà, ọmọ mẹ́sàn-án rin kílómítà àádọ́rún fún ọjọ́ mẹ́fà láti Yobe sí Bornu

Awọn obinrin to jajabọ lọwọ Boko Haram

Oríṣun àwòrán, Borno State Government

Àwọn obìnrin mẹ́fà àti ọmọ mẹ́san jàjàbọ́ lọ́wọ́ Boko Haram lẹ́yìn tí wọ́n rìn nínú igbó fún ọjọ́ mẹ́fà.

Kọmísọ́nà fọ́rọ̀ obìnrin nípìńlẹ̀ Borno, Zuwaira Gambo lo sisọ loju ọrọ yii lasiko to n safihan àwọn obinrin náà fun gomina ìpínlẹ̀ Borno, Babagana Zulum lọ́jọ́ Aje.

Gambo ni kìí ṣe ọdọ awọn nikan ni àwon Boko Haram ti kó àwọn ènìyàn mẹ́ẹ̀dógún yìí nítorí pé àwọn mìíràn ni abúlé ìpínlẹ̀ Adamawa àti Yobe ni wọn ti wá.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Wọ́n jí àwọn eeyan mẹ́ta àti ọmọ wọn gbé ní abúlé Takulashi nínú oṣù Kẹ̀wá ọdún tó kọjá nígbà tí àwọn tó kù wá láti abúlé Cofure nípìnlẹ̀ Adamawa.

Iwa ìjínigbé ti wọn si wáyé nínú oṣù Kàrún ọdún yìí gẹ́gẹ́ bí Kọmísọ́nà tó ń rí sí ọ̀rọ̀ obìnrin ṣe sọ.

Àkọlé fídíò, Latifat Tijani: Ìjọba Naijiria ń ṣèlérí láti mọ́ rírì mi àmọ́ láti 2016, pàbó ló ń já sí

Àwọn obìnrin náà, tó fi mọ́ ọ̀kan tó wà nínú oyún oṣù mẹ́jọ láti abúlé Cofure fi ẹsẹ̀ rìn fún ọjọ́ mẹ́fà nínú igbó Buni Yadi ni ìpínlẹ̀ Yobe, lọ sí ìlú Damboa ni ìpínlẹ̀ Borno.

Gẹgẹ bi Gambo ti salaye, ìrìnàjò tó tó kìlómítà àádọ̀rún ni awọn obinrin naa gunle, to si nira pupọ.

"Inú mi dùn púpọ̀ láti gba àwọn ọmọ mi yìí lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ́ ìyá lọ́wọ́ àwọn agbésùmọ̀mi.

Gbogbo nǹkan tó wà ní ìkápá mi ni maa ṣe láti rán wọ́n lọ́wọ́." Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Gómìnà Zulum sọ lásìkò to ń gbà alejo awọ́n obinrin naa.