Catholic Seminary Attack: Ọkadà ní agbébọn gùn wọ iléẹ̀kọ́ Àgùdà láti jí èèyàn gbé

Awọn agbebọn

Oríṣun àwòrán, ICIRNigeria

O kere tan awọn agbebọn ti ji awọn akẹkọọ mẹta gbe lọ ni ileẹkọ imọ ijọ ''Catholic'' ni ipinlẹ Kaduna.

Ileeṣẹ ọlọpaa to fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ ni awọn agbebọn naa wa ni ọgọọrọ wọn si ileẹkọ ''Catholic Seminary'' ti wọn si ji awọn akẹkọọ gbe, ti awọn miran si farapa.

Ọlọpaa naa ni awọn agbebọn naa lo ọkada lati fi wọ ileẹkọ ''Saint Albert Seminary'' ni agbegbe Kagoma, ti wọn si ṣina bolẹ, ti wọn si salọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ileeṣẹ ọlọpaa naa ni awọn ti wọn farapa naa ti wa ni ileewosan, ti wọn si ti bẹrẹ si ni wa awọn agbebọn naa.

Lara awọn akẹkọọ ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni awọn ko le e sọ ni pato iye akẹkọọ ti awọn agbebon jigbe lọ.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni ibọn alagbara ni awọn agbebọn da bolẹ lasiko ti awọn akẹkọọ naa ṣẹṣẹ pari adura irọlẹ tan ni ṣọọṣi to wa ni ileẹkọ naa.

Àkọlé fídíò, Latifat Tijani: Ìjọba Naijiria ń ṣèlérí láti mọ́ rírì mi àmọ́ láti 2016, pàbó ló ń já sí

Wẹrẹ ti awọn akẹkọọ bẹrẹ si ni gbọ iro ibọn bayii ni wọn fi ẹsẹ fẹ, ti olukaluku si bẹrẹ si ni sa asala fun ẹmi wọn.

''Awọn ti ori ko yọ nikan ni wọn jajabọ lọwọ awọn ajinigbe naa, ti wọn si ko awọn akẹkọọ ti a ko tii le sọ iye wọn. ''

Wọn kesi ijọba lati wa wọrọkọ fi ṣe ada lori ijinigbe ojoojumọ ni awọn ileẹkọ to wa ni ariwa orilẹede Naijiria, ki wọn le doola ẹmi awọn eniyan.

O kere tan akẹkọọ to le ni ẹgbẹrun ni awọn ajinigbe ti jigbe lọ ni ileẹkọ girama ati fasiti, bẹrẹ lati Oṣu Kejila, ọdun to kọja.

Ọpọlọpọ awọn agbebọn yii ni wọn n bere fun owo ẹmi awọn ti wọn ba jigbe, ki wọn to doola ẹmi wọn.

Ileeṣẹ ọmọogun orilẹede Naijiria ni awọn ti ran ikọ ọmọogun ni ẹgbẹgbẹrun wọn lọ si awọn agbegbe yii.

Àkọlé fídíò, Africa Eye wádii àwọn tó wà nídìí ìgbésùmọ̀mí ni Mozambique

Bakan naa ni wọn pa awọn ẹrọ ayelujara ati ẹrọ ibanisọrọ ni awọn agbegbe wonyii, ki ọwọ le tete tẹ awọn ajinigbe to n da ẹmi awọn eniyan legbodo ni ojoojumọ.

Amo gbogbo igbiyanju yii pabo lo jasi, nitori awọn agbebọn yii ṣi n ṣọṣẹ ni gbogbo igba, ti wọn si n fi ẹmi awọn akẹkọọ ati olukọ ṣofo, to fi mọ awọn araalu.

Amin iyasọtọ kan

Ẹ dẹ́kun fífún ọkùnrin tí kò bá gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 ní ìbálòpọ̀

Covid 19

Oríṣun àwòrán, others

Wọn ti gba awọn obinrin ni imọran pe ki wọn o má fún awọn ọkunrin ni ibalopọ, ti wọn ba fi kọ lati gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19.

Eyi ko sẹyin bi ọpọ eeyan ko fẹ ẹ gba abẹrẹ naa kaakiri agbaye.

Ni orilẹ-ede South Africa, imọran ti wọn gba awọn obinrin naa di dandan paapaa bi awọn ọkunrin ni Eastern Cape ṣe kọ ẹyin si abẹrẹ naa.

Gẹgẹ bi iroyin ti Daily Maverick gbe jade l'oṣu Kẹsàn-án, oludari ajọ to n mojuto eto ilera ni agbegbe naa, Nomakhosazana Meth lo fi ikede naa sita.

O ni imọran naa wulo, paapaa fun awọn obinrin ti ko ti i ṣe igbeyawo.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa: Ọ̀rọ̀ Asopò ni á ń gbéyẹ̀wò pẹ̀lú Arabìnrin Tope Atoyebi láti Ilorin

Eyi yoo si daabo bo "ẹyin mejeeji".

Obìnrin lo pọ ju ninu awọn to ti gba abẹrẹ.

Eeyan to le ni miliọnu kan lo si ti gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ni agbegbe Eastern Cape, bo tilẹ jẹ pe miliọnu mẹrin aabọ ni afojusun awọn alasẹ, ti yoo ba fi di oṣu Kẹrin, ọdun to n bọ.