Super TV Usifo Ataga: Chidinma ní òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìpànìyàn

Chidinma Ojukwu ti sọ nile ẹjọ pe oun ko jẹbi ẹsun pipa Oludasilẹ ileesẹ agbohunsafẹfẹ Super TV, Usifo Ataga.
Ọmọbinrin ẹni ọdun mọkanlelogun ọhun, to jẹ akẹkọọ fasiti Unilag, sọ bẹẹ lasiko to farahan nile ẹjọ giga ipinlẹ Eko to wa ni Tafawa Balewa Square nilu Eko.
Arabinrin Ojukwu ati ẹlomii, Adebayo Quadri, ni wọn jọ fi ẹsun mẹjọto nii se pẹlu ipaniyan naa.akinwum
- Hàà! Akẹ́kọ̀ọ́ UNILAG ẹni ọdún 21 kà bòrò-bòrò pé: Èmi ló pa olówó, ọ̀gá Super TV, Usifo Ataga
- 'Hàá, irú ikú tí ọmọ mí kú kò tọ́ síi, aláànú mí ní'
- Òtítọ́ ni pé akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ wá ní Chidinma Ojukwu tó pá bàbá olówó Usifo Utaga- fásitì UNILAG
- Chidinma ò gbudọ̀ kú o sátìmọ́lé Ọlọ́pàá o! Àwọn aṣòfin f'ọ̀rọ̀ ráńṣẹ́ sí Ọ̀gá àgbà Ọlọ́pàá
- Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ilé Kéú tó lú akẹ́kọ̀ọ́ bíi bàrà
- "Ará Cotonou, Sunday Igboho kò gbọdọ̀ kú sọ́dọ̀ wa o, ó ti wà nílé ìwòsàn báyìí"
- Ọlọ́run nìkan ló ni ẹ̀mí mi, ara mi ti le koko - Bola Tinubu
Wọn fi ẹsun kan wọn pe wọn gbimọ pọ lati pa Ataga, wọn fi ọbẹ gun ni ọpọlọpọ igba lọrun, eyi to pa a, wọn si tun jọ fọwọsowọpọ lati yi iwe.
Wọn ni wọn ṣe ayederu iwe irinna silẹ okeere 'passport' fun Chidinma, wọn tun ṣe kaadi aṣẹ ọkọ wiwa 'driver's license' ni orukọ rẹ.
Bakan naa ni wọn ni awọn mejeeji tun gbe ayederu akọsilẹ apo asunwọn oloogbe Ataga ni banki jade.
Ẹsun miran ti wọn fi kan Chidinma ni pe o ji ẹrọ ibanisọrọ iphone 7 ati iphone 11, kọmputa alagbeka, ati kaadi ATM Usifo Ataga, to si fi gba N380,000 ninu apo asunwọn rẹ.
Aburo Chidinma, Chioma Egbuchu ni wọn fi ẹsun kẹsan-an kan pe ọwọ rẹ ni wọn ti ba iphone 7 Ataga.
Quadri ati Egbuchu naa sọ pe awọn ko jẹbi.
Ṣaaju ni ile ẹjọ Majisireti kan ti gba beeli Chidinma.

Gẹgẹ bi ẹsun ti wọn fi kan Chidinma, wọn ni o pa Ataga ni ile ayalo kan ni Lekki nipinlẹ Eko'lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹfa.
Amọ ọwọ awọn ọlọpaa tẹ ẹ ni ile baba rẹ lagbegbe Yaba ni ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa.
Ọjọ kẹsan-an, oṣu Kọkanla ni igbẹjọ naa yoo tẹsiwaju.
















