Sunday Igboho: Yomi Aliyu ní àwọn ẹ̀yà ara Igboho ní àìsàn fi ọwọ́ kan, ó nílò ìtọ̀jú kíákíá

Oríṣun àwòrán, Sunday_igboho1/Instagram
Yoruba ni alagbẹdẹ to ba n lu irin ni oju kan, o ni ohun to fẹ gba lọwọ irin ni nitori isu atẹnumọran kii jona.
Idi ree ti agbẹjọro fun Sunday Igboho lorilẹede naijiria, Yomi Aliyu ko se dẹkun lilọgun fun ijọba ati gbogbo araalu pe ojojo n se ogun, ara ogun ko le.
Amofin Yomi Aliyu lo n lọgun bẹẹ lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lọjọ Isẹgun lori ipo ti ilera Sunday Igboho wa, eyi to ni o nilo itọju kiamọsa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Igboho ń jà fún ìran rẹ̀ ni, kìí ṣe apànìyàn, ìjọba Benin, ẹ bá wa tú u sílẹ̀
- Buhari, dáríjin Igboho àti Kanu láti fòpin sí ìjìjàgbara ní Naijiria - Bíṣọ́ọ́bù ìjọ Eleétò
- Buhari kíyèsára, gbèsè Naijiria pọ̀ ju owó tó ń pa wọlé lọ - AfDB
- Àṣìṣe márùn ún tí àwọn lọ́kọláyà ńṣe nípa owó
- Kíndìnrín àti ẹ̀dọ̀fóró Sunday Igboho ni àìsàn ń ṣe - Yomi Aliyu
- Agbébọn yabo Catholic Seminary ní Kaduna, wọ́n jí èèyàn mẹ́ta, ọ̀pọ̀ farapa
- "Buhari, oúnjẹ ní ko wá síkùn aráàlú ná, má fi N13.3bn gbé ọlọ́pàá agbègbè kalẹ̀"
- Chidinma yọjú sílé ẹjọ́ lónìí lórí ẹ̀sùn pípa Usifo Ataga àmọ́ ohun tó wáyé rèé
- "Ará Cotonou, Sunday Igboho kò gbọdọ̀ kú sọ́dọ̀ wa o, ó ti wà nílé ìwòsàn báyìí"
- Obìnrin mẹ́fà àti ọmọ wẹ́wẹ́ mẹsan sá ní àhámọ́ Boko Haram lẹ́yìn oṣù mẹ́fà
Aliyu ni aisan to n ba ajijagbara naa finra kii ṣe keremi, o si nilo itọju kanmọ n kia ati adura gidi.
O ni aisan to n ba Igboho finra kii ṣe eyii to n ṣe e tẹlẹ, ṣugbọn aisan naa bẹrẹ lẹyin ti ikọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ṣakọlu sile rẹ niluu Ibadan lọjọ kinni, oṣu Keje ọdun yii.
Aliyu ni "Aisan ti ko ṣe igboho tẹlẹ lo bẹrẹ si n ṣe nibẹ, aisan naa le to bẹẹ ti wọn fi gbe digbadigba lọ sile iwosan."
"Mi o le sọ ni pato boya wọn ti da pada sinu ọgba ẹwọn to wa tẹlẹ lati ile iwosan, ṣugbọn ohun ti mo mọ nipe ara rẹ ko ya, o si jọ bii pe aisan naa ti n daamu kindinri ati ẹdọforo rẹ."
Kindinrin ati ẹdọforo Sunday Igboho lo n yọ lẹnu:
"Bo tilẹ jẹ pe mi o le sọ nipa ibi gan ti aisan naa ti n ba finra julọ, ṣugbọn mo mọ pe o kan awọn ẹya inu rẹ."
Aliyu ni aisan ọhun bẹrẹ lasiko to farapa nibi to ti n gbiyanju lati ṣa asala lọwọ awọn ọtẹlẹmutyẹ DSS to kọlu ile rẹ ni ibẹrẹ oṣu Keje.
O ni idi ree ti wọn fi gbọdọ gbe ajijagbara ọhun lọ si oke okun fun itọju to peye.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ṣaaju ni ikọ ọtẹmuyẹ DSS ti kọkọ kọlu ile rẹ nilu Ibadan, nibi ti wọn ti ba ọpọlọ dukia jẹ, ti wọn si tun pa eeyan meji nibẹ.
Igboho ko saisan amọ o ni ipalara - Amofin Salami
Amọ bi Yomi Aliyu se n lọgun to yii pe ilera Sunday Igboho n bẹ ninu ewu to lagbara, sibẹ agbẹjọro fun Igboho to wa ni Cotonou, Amofin Ibrahim Salami sọ pe ko si ohun to jọ bẹẹ.
Nigba ti akọroyin BBC Yoruba kan si Salami lati mọ ile iwosan ti wọn gbe Sunday Igboho lọ nilu Cotonou, o ni ko si aisan kankan to n ṣe Igboho ati pe ko si nile iwosan.
Salami ni "Sunday Igboho ko ṣaisan, ṣugbọn o ni awọn ipalara kan nitori ikọlu ti ajọ DSS ṣe sile rẹ lọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun 2021."
"Lati igba naa wa, ko ri iwosan to peye gba, ilera rẹ si n buru si, idi ree to fi beere pe ki wọn gbe ohun lọ soke okun fun itọju."




















