Olota Of Ota: N kò fara mọ́ ìyapa Nàíjíríà, ìṣèjọba ẹlẹ́kùnjẹkùn ní ọ̀nà àbáyọ
Olota tilu Ota, Ọba Adeyemi Obalanlege ti ke si ijọba apapọ lati fori jin Oloye Sunday Igboho to wa ni ahamọ ni Cotonou.
Oriade naa ni ko si iru ẹsẹ yowu ti Igboho ko baa sẹ, ọmọ awọn ni awọn ko si le ta nu, amọ oun n rawọ ẹbẹ sijọba lati fi ori jin.
Ọba Olota rawọ ẹbẹ bẹẹ lasiko ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba lori awọn ohun to n lọ nilẹ Yoruba ati Naijiria lapapọ.
- Buhari tí mo mọ̀ ní 1983 kọ́ ló wà nípò, mò ń ‘doubt’ rẹ̀ - Olugbon
- Sunday Igboho, ṣe sùúrù díẹ̀ lórí ìwọ́de Yoruba Nation l‘Eko - Olugbon ń lọgun
- Wọ́n ti ń ti ọ̀rọ̀ olóṣèlú bọ ọ̀rọ̀ Sunday Igboho ní èyí tó yẹ kí Yorùbá fi ṣọ́ra- Oba Francis Olusola-Alao
- Alao Akala ló da ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba Oyo rú, àwa ọba kò jìjà àgbà - Onpetu Ijeru
- Kìí ṣe nítorí mi ò ṣ'ètùtù ni olorì méjì ṣe kú, àsìkò wọn ló tó- Oba Onpetu
- Ẹ dẹ́kun lílo Kurani àti Bibeli nìkan láti fi búra fún àwọn olóṣèlú wa, ẹ jẹ́ ká fí ńkan ìṣẹ̀mbáyé kún un- Oba Ogboni Iwase
- Ìjọba mọ̀ pé àwọn Fulani ń wa góòlù ní Owo láì ṣe nǹkan kan si - Olowo
- Gbá gbá gbá ni mo wà lẹ́yìn ìdásílẹ̀ Yoruba Nation - Tunde Gbadamosi
- Ọlọ́run fi ẹ̀mí Sunday Igboho ta gbogbo àwa tókù jí ni, ọ̀rọ̀ yìí ti kọjá ìsòpọ̀ Nàìjíríà - Oba Gbolahan Shomolu
Oriade naa ni ohun ko ni sọ boya ohun ti Igboho se dara tabi ko dara amọ ki ijọba fori jin lo se koko.
Nigba to n sọrọ lori iwa ipa tawọn afurasi Fulani kan n lo, Olota ni nibayii ti ofin ma da ẹran jẹko laarin ilu ti wa, ojuse awọn agbofinro ni lati ri pe ofin naa mulẹ.
O fikun pe alejo kọọkan nilẹ Yoruba lo gbọdọ tẹle ofin wa, eyikeyi ninu wọn ti ko ba si le bọwọ fun ofin ta ba fi lelẹ lọdọ wa, ni ko pada silu rẹ.
Lori ero awọn eeyan kan to n pe fun atunto Naijiria, oriade naa ni oun fara mọ isejọba ẹlẹkunjẹkun ta ti se ri, eyi to gbe wa pupọ.
O ni ilana isejọba naa lo mu kawọn ara ilu tubọ sun mọ ijọba lẹsẹkuku amọ ba se tẹwọgba ilana isejọba tilẹ Amẹrika yii lo ko wahala de, tawọn ijọba si jinna pupọ si araalu.
Ọba Obalanlege wa kede pe oun ko fara mọ iyapa Naijiria rara nitori agbara wa ninu ajọsepọ wa, sugbọn isejọba ẹlẹkunjẹkun labẹ ẹya kọọkan nikan ni ọna abayọ si isoro Naijiria.





