Sunday Igboho: Bíṣọ́ọ́bù ní kò yẹ kí ìjọba pe àwọn ajìjàgbara ní agbésùmọ̀mí bíkòṣe ọmọ

Nnamdi Kanu ati Sunday Igboho

Biṣọọbu agba kan ninu ijọ Eleto, Samuel Chukwuemeka Kanu-Uche ti gba Aarẹ Muhammadu Buhari ni imọran lati forijin adari ẹgbẹ awọn IPOB, Nnamdi Kanu ati ajijagbara ilẹ Yoruba, Sunday Igboho.

Alufaa naa ni ṣiṣe eyii yoo fopin si erongba awọn eeyan naa lati jẹ ki ẹya wọn yapa kuro lara Naijiria.

Kanu-Uche lo sọ ọrọ naa lasiko ijiroro pẹlu awọn akọroyin niluu Abuja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bii nnkan to sọ, ọpọ eeyan ni Naijiria lo jẹ ọmọlẹyin awọn ajijagbara ọhun, o si yẹ ki ijọba apapọ lo awọn ọmọlẹyin wọn lati wọle si awọn ajijagbara naa lara.

O tun dabaa pe ki ijọba máa san ẹgbẹrun marundinlọgbọn fun awọn ọmọ ikọ Boko Haram to ba ronupiwada nitori iṣẹ ati iya lo n mu ki ọpọ eeyan kan darapọ mọ wọn.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho‘s Birthday: Àwọn olólùfẹ́ Igboho rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba Benin láti túu sílẹ̀,

Nigba to n sọrọ lori Sheikh Ahmad Abubakar Gumi, o ni o yẹ ki ijọba le lo ẹlẹsin Musulumi naa lati fopin si gbogbo iwa janduku lapa oke ọya nitori ipa ti ọkunrin ọhun ni lori awọn janduku naa.

Kanu-Uche sọ pe "Awọn wo lo lọ n gbe owo itusilẹ lọ fun awọn janduku? Kaka ki ijọba maa bu ẹnu atẹ lu Gumi, ni ṣe lo yẹ ki wọn wa ọna lati ba a ṣiṣẹ pọ lọna ati fopin si iwa janduku."

"To ba jẹ pe lootọ ni Gumi maa n lọ sinu igbo lati lọ ba awọn janduku sọrọ ti awọn janduku naa si maa n gbọ tirẹ, ijọba le ba wọn sọrọ lati ipasẹ rẹ."

Àkọlé fídíò, Ridwan Oyekola: October 30 ni màá tún ìjà jà láti gba belt mi padà àmọ́ kò sí onígbọ̀wọ́

"Ẹ jẹ ki n sọ fun ni gbangba bayii pe awọn oloṣelu lo n lo awọn ọdọ wọnyii fun iwa janduku, ti ijọba ba n fun wọn ni ẹgbẹrun marundinlọgbọn loṣooṣu, wọn ko ni máa ji eeyan gbe mọ, ounjẹ ni wọn n wa, ko si nnkan mii."

Biṣọọbu ọhun sọ siwaju si pe ijọba gbọdọ pe Kanu ati Igboho fun ijiroro.

O ni "O yẹ ki ijọba naa tun pe Nanamdi Kanu ati Sunday Adeyemo si ipade lori bii wọn yoo ṣe yanju gbogbo rogbodiyan to wa nilẹ yii.

Alufaa ọhun pari ọrọ rẹ pe "Ẹ ma pe awọn ni agbesumnọmi, ti ẹ ba pe wọn ni agbesumọmi yoo di wahala."

"Ṣugbọn ẹ pe wọn ni ọmọ, ki ẹ si sọ fun wọn pe, ẹyin ọmọ wa, ẹ wa o, ẹ jẹ ki a ni ifikunlukun.... yoo ṣiṣẹ bii idan."

Àkọlé fídíò, Latifat Tijani: Ìjọba Naijiria ń ṣèlérí láti mọ́ rírì mi àmọ́ láti 2016, pàbó ló ń já sí