Community Police: Onímọ̀ ààbò ní ọ́lọ́pàá tó wà nílẹ̀ ló nílò ìtọ́jú kìí ṣe ìdásílẹ̀ ikọ̀ ọlọ́pàá agbègbè

Oríṣun àwòrán, NPF
Àìní àtilẹ̀yìn ìjọba àti ará ìlú ni ìṣòro tí àwọn ọlọ́pàá Nàìjíríà ń kojú tí wọ́n kò fi lè ka àpá ètò ààbò tó mẹ́hẹ ni Nàìjíríà.
Ónímọ̀ nípa ètò abo ni Nàìjíríà, ọ̀gbẹ́ni Dotun Ojon lọ fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ lásìkò tó ń bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀lọjọ Isẹgun.
Ojon, lásìkò to ń dá sí ìbéèrè nípa bílíọ̀nù mẹ́ta náírà lè diẹ̀ tí ìjọba àpapọ̀ gbé kalẹ fún ìdásílẹ̀ ọlọ́pàá àgbègbè, lo sisọ loju ọrọ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Ará Cotonou, Sunday Igboho kò gbọdọ̀ kú sọ́dọ̀ wa o, ó ti wà nílé ìwòsàn báyìí"
- Wo àṣírí nkan tó gba ẹsẹ̀ kan lọ́wọ́ Jigan Baba Oja
- Awò ojú tí mò ń lò kìí ṣe akọ tàbí ìgbéraga, ohun tó fà á rèé - Helen Paul
- Obìnrin mẹ́fà àti ọmọ wẹ́wẹ́ mẹsan sá ní àhámọ́ Boko Haram lẹ́yìn oṣù mẹ́fà
- Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ilé Kéú tó lú akẹ́kọ̀ọ́ bíi bàrà
- Ẹ dẹ́kun fífún ọkùnrin tí kò bá gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 ní ìbálòpọ̀
- Akúṣẹ́ apẹja bọ́ sínú agbami ọrọ̀ lẹ́yìn tó rí èébì ẹja Wéèlì létíkun
- Ìdí rèé tí ń kò fi máa lo bàálù àdáni - Oluwo
Ọ̀gbẹ́ni Ojon ni kàkà tí ìjọba yóò tún fi lo owó naa láti ṣe àgbékalẹ̀ ileesẹ alaabo tuntun, yoo kuku san kó fi owó náà rọ okun sápá àwọn ọlọ́pàá.
Bakan naa lo ni owo ọhun yoo tun wulo fun amojuto àwọn ikọ̀ elétò ààbò tó ti wà nílẹ̀ pàápàá jù lọ, ikọ̀ Amotekun àti Ọlọ́pàá Nàìjíríà.
Buhari, fi N3.3bn ra ibọn fun ọlọpaa, dipo agbekalẹ ọlọpaa agbegbe - Ojon
Ó ní wọ́n ti gba àwọn kọstabu si iṣẹ́ ọlọ́pàá pẹ̀lú ìrètí pé wọ́n yóò mọ agbegbe wọ́n daadaa nígbà náà, ṣùgbọ́n láti ìgbà yẹn náà kò fi bẹ́ẹ̀ sì ìyàtọ̀.
Ojon ni bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣe èyí lásìkò náà nítorí pé àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ fẹ́ ṣe ìdásilẹ̀ Amotekun ni.
Sùgbọ́n o ni àsìkò yìí tí wọ́n ti rí pé àwọn ènìyàn tí ń ní ìfẹ́ sí bí àwọn Àmọ̀tẹ́kùn ṣe ń ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àṣìṣe mìíràn náà wá ní ìhà wọ́n.
Olórí ẹgbẹ́ YPP nípìnlẹ̀ Ondo náà tún fi kún pé, kò ní dára kí ijọ́ba fi owó tùùlù-tuulu yí ṣe òfò pẹ̀lú ìdásilẹ̀ ọlọ́pàá àgbègbè.
O ni yoo dara kí wọ́n fi ra ohun èlò àti ibọn fún àwọn ọlọ́pàá, bákan náà ló pé kí ìjọba ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ọlọ́pàá láti mọ bí a ti ń bá ará ìlú ṣe.
Ojon ni eyi se pataki nítorí ọ̀pọ̀ ará ìlú ni kò ní ìgbàgbọ́ nínú ọlọ́pàá Nàìjíríà.
Buhari, wa bi ebi, ìṣẹ àti ìyàn yóò ṣe dínkù láàrin àwọn ará ìlú ná, dipo Ọlọpaa agbegbe:
Nínú èrò tìrẹ ọ̀gbẹ́ni Dele Farotimi ni ìjọba àpapọ̀ kan fi ẹ̀tẹ̀ sílẹ̀, máa pa làpálàpá ni, nítorí pé kí ṣe àsìkò ló yẹ kí orílẹ̀èdè bí Nàìjíríà ṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ̀rọ̀ nípa ètò ọ̀rọ̀ ọlọ́pàá agbègbè.
Ó ní kìí ṣe òní ni ìjọba yóò maa buwọ́lu owó kan fún iṣẹ́ ìlú, tó sì jẹ́ pé àwọn kan ni yóò pín owó náà.
Ọ̀gbẹ́ni Dele Farotimi ni nǹkan tí ó ṣe pàtàkì jùlọ lọ́wọ́lọ́wó ni bí ebi, ìṣẹ àti ìyàn yóò ṣe dínkù láàrin àwọn ará ìlú ná, èyí lásán lo ni yóò mú àdínkù bá ìwà ọ̀daràn láwùjọ.
"Kì í ṣe òní ni ìjọba tí ń ṣe irú ètò yìí ṣùgbọ́n kii sí àbájáde gidi kankan"
Farotimi wá ṣàlàyé pé, tí ìjọba bá ti mójú tó èyí tán, ó ṣe pàtàkì láti jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo wá láàrín ìlú, kí wọn sì máa tẹ́lẹ̀ òfin.
O ní láìsí èyí kò sì irú owó tí ìjọba lè gbé sílẹ̀ fún ọ̀rọ̀ àbò tí ó lè ní ìtumọ̀, tí ara ìlú kò bá nírètí pé ọ̀la yóò dára ju òní wọn lọ.





















