Oluwo: N kò lo "Private jet" torí mo kọ̀ láti máa ta ilẹ̀ aráàlú ní ìtàkutà

Oríṣun àwòrán, oluwo of iwo
Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi ti ṣalaye idi ti ko ṣe tii maa rinrinajo kaakiri ninu ọkọ ofururu aladani.
Gẹgẹ bii ohun sọ, eredi rẹ ko ju pe oun kọ lati maa ta ilẹ awọn eeyan oun ni itakuta, ati pe oun ni itẹlọrun.
Oluwo lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Facebook rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Sunday Igboho, àwa Yoruba Nation kò gbàgbé rẹ sí àhámọ - Akintoye
- Seyi Makinde pe olóyè PDP lẹ́jọ̀ fún ìbanilórúkọ jẹ́ lórí Facebook
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara dá ọ̀gá ilé Keu tí wọ́n ti lu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bí i bàrà dúró
- Buhari, ohun ìjà tó ń kójọ ni wọn yóò lò láti rẹ́yìn Nàíjíríà - Fr Mbaka
- A kò da iṣẹ́ sílẹ̀ mọ́, ó di ọjọ́ míì, ọjọ́ re - IPMAN, PTD
- "Èmi ni mo sọ fáwọn ọ̀gá ilé Keu pé kí wọ́n lu ọmọ mi bí ẹran"
- Agbẹjọ́rò wọ́ ìjọba lọ sílé ẹjọ́ pé kó yọ kéú kúrò lára owó Náírà
- Buhari, ìwé òfin 1999 ni ìparun Naijiria, tètè fà á ya - Tunde Bakare
- Gómìnà Yoruba, ẹ dúró lé ìjọba àpapọ̀ lọ́rùn pé kó fi Sunday Igboho sílẹ̀ - Gani Adams
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara dá ọ̀gá ilé Keu tí wọ́n ti lu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bí i bàrà dúró
- Ìdí rèé tí mo fi gbà kí ọkọ mi má a ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìyá àti àbúrò mi
Adewale Akanbi ni oun ko le maa jaye ọlọbaa kaakiri nigba ti awọn eeyan ti oun jọba le lori yoo maa jiya.
O ni "Gẹgẹ bii Ọba, to ba jẹ pe mo yan lati jaye ni, o yẹ kii n ti maa lo ọkọ ofurufu aladani iyẹn ti mo ba n ta ilẹ awọn eeyan ti mo jọba le lori."
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
"Ṣugbọn mo mọọmọ yan lati sin wọn bayii ni ki awọn le sin mi lọjọ ọla."
"Ohun to ṣe pataki si mi ni lọwọ yii awọn eeyan mi, ọna Ọlọrun ni mo si fi n han wọn, kii ṣe ọna oriṣa kankan."
"Bi mo ṣe n gbe igbe aye mi ree, idi naa si ni wọn ṣe n bu ọla fun mi."
Oluwo jẹ ọkan lara awọn Ọba ilẹ Yoruba to maa n sọ ni gbangba pe Ọlọrun nikan ṣoṣo ni Ọba nitori ko si Ọba kankan lẹyin Ọlọrun.
Bakan naa lo tun maa n sọ pe ko tọ ki eeyan maa sin oriṣa miran yatọ si Ọlọrun Ẹlẹdaa.



















