Oluwo: Ọba Yorùbá tó bá ń bọ òrìṣà, kò sí ìsinmi fun

Oríṣun àwòrán, emperortelu1/Instagram
Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrashed Adewale Akanbi, Telu kinni ti kede pe ẹkun ariwa ni ipo agbara yoo ma duro si ayafi ti iran Yoruba ba yi iwa wọn pada.
Oluwo ni awọn ọba ẹkun ariwa Naijiria lo maa n sin Ọlọrun kan soso, tawọn ọba ilẹ Yoruba si maa n sin orisa.
O wa gba wọn nimọran pe ti ilẹ Yoruba ba fẹ maa wa nipo giga, asiko ti to, ki wọn tun ero wọn pa, ki wọn si pa orisa sinsin ti.
- N kò fẹ́ eégún onídọ̀tí ní ààfin mi - Oluwo
- Èmi ni mo fẹ́ ṣíwájú ìwọ́de ọ̀dọ̀ tí yóò tún wáyé-Oluwo
- Èmi ni mò ń jóko sórí ìtẹ́ Ọlọrun alààyè nílé ayé - Oluwo
- Ẹ má lọgun ‘Oduduwa Nation’ mọ́, Yorùbá ló kàn láti jẹ ààrẹ - Oluwo
- Ọba ni mí, mi ò le b'ọ̀rìṣà, Olorì tuntun tó ń bọ̀ já gbogbo ''scale''- Oluwo ti Iwo
- Oluwo ṣàlàyé ìdí ìhùwàsí rẹ̀ láwùjọ
- Oluwo àti Olorì àná, Chanel Chin tahùn síra
- Èmi Ọba tí wọ́n ń kó jẹ nígboro- Oluwo ti ilú Iwo
- Ọ̀rọ̀ èmi àti Olorì Chanel Chin kò yé ara wa mọ́ nínú ilé- Oluwo
Oluwo gbe imọran yii kalẹ nibi isọji itusilẹ kan to waye nilu naa nibi ti ọba naa ti sọrọ fun awọn olujọsin.
Ọba Akanbi ni gbogbo awọn to n bọ orisa ni yoo maa jo ajorẹyin nigba ti awọn to n sin Ọlọrun Ọba yoo maa lọ siwaju ati siwaju.
O mẹnuba iwe Saamu ori kẹrindinlogun ẹsẹ ikẹrin (psalm 16:4) to si gba awọn ojisẹ Ọlọrun niyanju lati saayan bi iwa ibọrisa yoo se di ọrọ itan.
"Ta ni Sango, Ogun, Ọya, Ogun, Osun atawọn orisa alagbara miran tawọn eeyan nbọ?
Mo fẹ lu gbogbo ẹyin ọba nilẹ Yoruba, awọn pasitọ, wolii ati ẹni ọwọ lọgọ ẹnu, isẹ nla lẹ n se.
Ohun Ọlọrun si ti wa silẹ Yoruba pe ọba ti ko ba kọ orisa silẹ, ko ni nisinmi, gbogbo isoro tẹ si n koju lonii, isẹ ọba awọn ọba alaye ni.
Awọn ọba yii lo n gba abọde orisa sinu aafin wọn, eyi to yẹ ko jẹ ti Oluwa, ki wa ni yoo gbẹyin rẹ, se wọn ko wa ni maa ja bi?
Ki lẹ ro pe yoo jẹ ipa rẹ lori awọn araalu nigba ti ibi asẹ ba ti daru? Ẹyin gan ti wọ wahala nitori naa, ẹ ma ja mi niytan amọ ẹ gba imọran mi."
Oluwo wa gba awọn olujọsin naa nimọran lati lọ sọ fawọn ọba wọn pe ko gbọdọ si ibọrisa ninu aafin nitori wọn ko le maa sin Ọlọrun ati orisa papọ, ki wọn si ni ki ibukun maa pọ si, rara o.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹgbẹ́ ìlànà ọmọ Oodua fi ìròyìn ayọ̀ ránṣẹ́ lórí Sunday Igboho
- "Tí Sunday Igboho, Nnamdi Kanu bá bọ́ sínú APC, wọn yóò gbá ìtúsílẹ̀''
- Ète ìdìtẹ̀ gbàjọba forí sánpọ́n ní Sudan
- Seyi Makinde kúró lẹ́gbẹ́ PDP, ìyà tó o fi jẹ wá tó - Igun PDP Oyo
- Aisha Yesufu kó ọ̀rọ̀ Ooni dànù, ó ní ohun tó kàn kọ́ ni Ọòni fẹ́ lọ ṣe ní ìpèbí
- Afurasí Fulani ti pa aráàlú mi bíi 50, jó ile 254 níná - Oríadé kan figbe ta
"Orisa bibọ ni isoro ilẹ Yoruba, ki agbara si to le wa silẹ Kaarọ Oojire, a gbọdọ dẹkun orisa bibọ.
Agbara wa lẹkun ariwa nitori wọn korira orisa bibọ, ẹ ko si le ri orisa kankan ni sakani wọn.
Orisa bibọ jẹ ajeji nilẹ Yoruba, ko si ni dara fun awọn orisa naa, aye wọn ti bajẹ nitori naa, ẹ ye lọ si ojubọ wọn mọ."




















