Sudan Failed Coup: Ọkọ̀ ìjagun kún ojú pópó láwọn òpópónà ìlu Khartoum

Oríṣun àwòrán, AFP
Ijọba ilẹ Sudan ti kede pe oun ti doju ete iditẹ gbajọba bolẹ lati ọdọ awọn ọmọ ogun kan lorilẹede naa.
Iroyin naa ni ọpọ rogbodiyan ologun lo ti n waye ni olu ilu orilẹede naa, Khartoum ati ilu Ombudman, ti wọn si ti gbe afara odo Nile to wa nilẹ naa tipa
"Lootọ ni ete lati ditẹ gba ijọba n waye amọ a ti doju rẹ bolẹ, o si yẹ ki awsn araalu gan tako pẹlu" Ileesẹ iroyin kan lorilẹede Sudan lo sọ bẹẹ ni aarọ ọjọ Isẹgun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹgbẹ́ ìlànà ọmọ Oodua fi ìròyìn ayọ̀ ránṣẹ́ lórí Sunday Igboho
- "Tí Sunday Igboho, Nnamdi Kanu bá bọ́ sínú APC, wọn yóò gbá ìtúsílẹ̀''
- Seyi Makinde kúró lẹ́gbẹ́ PDP, ìyà tó o fi jẹ wá tó - Igun PDP Oyo
- Aisha Yesufu kó ọ̀rọ̀ Ooni dànù, ó ní ohun tó kàn kọ́ ni Ọòni fẹ́ lọ ṣe ní ìpèbí
- Afurasí Fulani ti pa aráàlú mi bíi 50, jó ile 254 níná - Oríadé kan figbe ta
- Ìdí rèé lórí bí mo ṣe di oníyàwó márùn-ún, ẹjọ́ mi kọ́ - Ọkọ Lizzy Anjorin
- Obìnrin kan wọ ‘Wedding Gown’ láti wá ọkọ lójú pópó. Òpin ayé dé!
- Gbogbo òṣìṣẹ́ ọba l‘Osun, abẹ́rẹ́ Covid-19 di ọ̀rànyàn fún yín bíbẹ́ẹ̀ kọ́... Oyetola
- Ewú n bẹ̀ nínú ṣíṣe ádùrá nínú igbó, kẹ́ má bà kó sọ́wọ́ ajínigbé - ọlọ́pàá ṣèkìlọ̀
- Sanwo-Olu buwọ́lu òfín máfi ẹran jẹko láàrín ìgboro l'Eko
- PDP Oyo sọ̀rọ̀ lórí pé Seyi Makinde ń lọ sẹ́gbẹ́ APC
Bakan naa nileesẹ iroyin AFP kede pe awọn aditẹgbajọba naa tun gbiyanju lati gba akoso ileesẹ iroyin to jẹ ti ijọba apapọ orilẹede naa.
O ni ijọba orilẹede Sudan ni oun ti n saayan lati lati gbakoso ohun gbogbo lorilẹede naa ati isẹlẹ to waye ọhun.
Fidio kan to gba awọn oju opo ikansiraẹni lori itakun agbaye lo safihan ọkọ ijagun Armoured tank lawọn oju popo.
Ileesẹ iroyin AFP si ni lilọ bibọ ọkọ ati ero ti n waye diẹdiẹ lawọn opopona to wa nilu Khartoum.
Gẹgẹ bi iwe iroyin Reuters se wi, agbẹnusọ fun ileesẹ ologun lorilẹede Sudan, Mohammed Al Faki Suleiman kede pe ifọrọwanilẹnuwo fawọn afurasi aditẹgbajọba ti ọwọ tẹ yoo bẹrẹ laipẹ.
Ni ọdun meji sẹyin, ni wọn doju ijọba aarẹ Omar Al-Bashir bolẹ, tii se olori orilẹede Sudan to ti pẹ nipo naa julọ.
Lẹyin naa ni wọn fẹnu ko lori ilana bi wọn yoo se pin ipo laarin ara wọn eyi to fidi agbekalẹ isejsba naa mulẹ, ninu eyi ti awọn ologun, oloselu atawọn ikọ to n fi apa janu wa.













