Insecurity In Nigeria: Ẹ yàgò fún ádùrá ṣiṣe nínú igbó kí ẹ má kò sí ọwọ àwọn ajínigbe-Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Oasis of God Tv
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti kilọ fawọn olujọsin lati yago fun ṣiṣe adura ninu igbo, ki wọn ma ba ko si ọwọ awọn ajinigbe.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita gba latọwọ alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi, ileesẹ ọlọpaa ni ilu ti le kọja ki eeyan maa fi ara rẹ sinu ewu adura ṣiṣe ninu igbo.
Oyeyemi sọ pe bo tilẹ jẹ wi pe awọn araalu lẹtọ lati jọsin, amọ wọn ko gbọdọ maa ṣe adura lawọn agbegbe to ba da paro paro.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Obìnrin kan wọ ‘Wedding Gown’ láti wá ọkọ lójú pópó. Òpin ayé dé!
- PDP Oyo sọ̀rọ̀ lórí pé Seyi Makinde ń lọ sẹ́gbẹ́ APC
- Ìdí rèé lórí bí mo ṣe di oníyàwó márùn-ún, ẹjọ́ mi kọ́ - Ọkọ Lizzy Anjorin
- Ẹ wo ohun tí Ooni yóò ṣe fáwọn olóṣèlú bó se wọ ìpèbí lọ fọ́dún Ọlọ́jọ́
- Ìwà ọ̀daràn àti òmùgọ̀ ní kí Nàíjíríà jẹ gbèsè kún gbèsè - Obasanjo
- Jonathan, má yẹ̀yẹ́ ara rẹ láti díje ìbò ààrẹ 2023 - Ọ̀gá ẹgbẹ́ àwọn gómìnà kìlọ̀
- A kìí ṣọ̀rẹ́ èrò ká yọ̀ lọ̀rọ̀ Fani-Kayode, ajá rẹ̀ kò mọ ẹni a kìí gbó mọ́ - Salihu Lukman
- Tinubu là ń dúró dè láti sọ ìpinnu wa fétò ìṣèlú 2023 - Akeredolu
- Láì sí ẹ̀kùn àríwá, òfo ní ìpínlẹ̀ Eko, Rivers lórí owó ọjà - Masari
- Buhari, káàbọ̀ sí Amẹ́ríkà àmọ́ ohun tà ń fẹ́ rèé - Yoruba Nation
O ni iwe mimọ ni bi a baa n ṣe adura, ki a ma sun asunpara bakan naa.
Lọpọ awọn igbo to wa ni ipinlẹ Ogun, ṣiṣe eto isin adura paapa fawọn ẹlẹsin Kristẹni jẹ nkan to wọpọ.
Ipenija aabo lẹnu ọjọ mẹta yii si ṣe okunfa bi awọn ajinigbe ti ṣe n sa si abẹ igbo kijikiji lati ji awọn eeyan gbe, nibi ti wọn ba ti n ṣe ijọsin tabi iṣẹ wọn.
Ni ipinlẹ Ogun paapa lawọn ilu to ba sun mọ igbo tabi ibode pẹlu orileede mii bi Benin, iṣẹlẹ ijinigbe ko jẹ tuntun.
Oyeyemi ṣalaye pe, iṣẹ ipese aabo yii, ti gbogbo ara ilu nii ṣe, tori naa, kawọn araalu daabo bo ara wọn ati dukia wọn.
Amọ ṣa, o ni ti o ba wa di dandan ki wọn ṣe ijọsin adura wọn yii, ki wọn kan si agọ ọlọpaa to wa ni itosi wọn fun aabo tabi imọran to peye.

















