Nnamdi Kanu IPOB case: Iléẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ Nnamdi Kanu di oṣù kẹ̀wàà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileẹjọ kan ni ipinlẹ Abia ti sunjọ igbẹjọ ti Nnamdi Kanu gbe wa siwaju rẹ di ọjọ mii.
Ẹjọ naa wa laarin ikọ ajijagbara Indigenous People of Biafra,IPOB ati awọn agbofinro Naijiria.
Adajọ K.C.J. Okereke ti wọn gbẹjọ naa wa siwaju rẹ sunjọ igbẹjọ di ọjọ Kejej oṣu Kẹwa ọdun yi.
Agbẹjọro agba Naijiria, ọga agba ileeṣẹ ọmọ ologun Naijiria ati ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa to fi mọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ni Kanu pe lẹjọ
Ohun to ṣẹlẹ nile ẹjọ
Ni nkan bi ago marun un aarọ lọj Iṣẹgun ni awọn agbofinro ti duro wauwamu lopopona Umuahia-Ikot Ekpene nibi ti ile ẹjọ giga to gbẹjọ naa wa.
Awọn ọlọpaa gbegi dina ti eleyi si fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ.
Toun ti ojo to rọ, awọn to ni nkan ṣe plu ẹjọ yi peju sile ẹjọ.

Amọ ileẹj ko ribi gbẹjọ naa nitori awọn ti Kanu pe lẹjọ ''ko kọwe dahun ipẹjọ naa''
Adajọ gba gbogbo awọn ti ọrọ kan lati fesi si ọrọ to wa nilẹ ṣaaju ọjọ Keje oṣu Kẹwa.
"Tí Sunday Igboho, Nnamdi Kanu bá bọ́ sínú APC, wọn yóò gbá ìtúsílẹ̀''

Oríṣun àwòrán, Others
Eekan kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Jonathan Vatsa ti fi ero rẹ han pe o ṣeeṣe ki Nnamdi Kanu ati Sunday Igboho gba itusilẹ ti wọn ba darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.
Vatsa sọ eyi lasiko to n fi ero rẹ han lori bi minisita tẹlẹ feto irinna oju ofurufu, Femi Fani Kayode fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.
O ni Sunday Igboho ati Kanu yoo ri idariji gba, ti wọn ba darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu ijọba apapọ nitori ọrọ wọn ko buru ju ti Fani-Kayode lọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹgbẹ́ ìlànà ọmọ Oodua fi ìròyìn ayọ̀ ránṣẹ́ lórí Sunday Igboho
- Seyi Makinde kúró lẹ́gbẹ́ PDP, ìyà tó o fi jẹ wá tó - Igun PDP Oyo
- Afurasí Fulani ti pa aráàlú mi bíi 50, jó ile 254 níná - Oríadé kan figbe ta
- Ìdí rèé lórí bí mo ṣe di oníyàwó márùn-ún, ẹjọ́ mi kọ́ - Ọkọ Lizzy Anjorin
- Obìnrin kan wọ ‘Wedding Gown’ láti wá ọkọ lójú pópó. Òpin ayé dé!
- Gbogbo òṣìṣẹ́ ọba l‘Osun, abẹ́rẹ́ Covid-19 di ọ̀rànyàn fún yín bíbẹ́ẹ̀ kọ́... Oyetola
- Ewú n bẹ̀ nínú ṣíṣe ádùrá nínú igbó, kẹ́ má bà kó sọ́wọ́ ajínigbé - ọlọ́pàá ṣèkìlọ̀
- Sanwo-Olu buwọ́lu òfín máfi ẹran jẹko láàrín ìgboro l'Eko
- PDP Oyo sọ̀rọ̀ lórí pé Seyi Makinde ń lọ sẹ́gbẹ́ APC
Ninu ọrọ rẹ, Vatsa ni ibaniloju jẹ gba a ni ki awọn ole ati ọlẹ ma a darapọ mọ ẹgbẹ APC nitori ohun ti wọn fẹ.
Vatsa ni eleyii fihan pe ẹgbẹ oṣelu APC n tiraka lati gberi gẹgẹ bi ẹgbẹ oṣelu ni Naijiria.
''Ko ni ya mi lẹnu ti Igboho ati Kanu ba darapọ mọ APC lọna ati kuro ni panpẹ ati atimọle ti wọn wa.
Eleyii safihan ilakaka ẹgbẹ oṣelu APC ati igbe aye ọbayegẹ ati ajẹbanu ti wọn n lo ninu ẹgbẹ oṣelu naa.
Ole to ba ti darapọ mọ wọn bayii yoo gba itusilẹ ni, ti yoo si di eniyan nla ni awujọ.
Awọn alajẹbanu, ti wọn ji owo Naijiria, ti wa di eekan ni ẹgbẹ oṣelu APC , o ti pari fun ẹgbẹ oṣelu APC, ko si afojusun fun ẹgbẹ naa.''
O ṣi n ya mi lẹnu bi Femi Fani-Kayode ṣe darapọ mọ ẹgbẹ APC ati bi wọn ṣe gba a wọle si ile aarẹ ni Aso Rock jẹ iyalẹnu gba a ni.''
Bakan naa, gbogbo awọn ọmọ Naijiria lo mọ iru iwa ajẹbanu ti Fani-Kayode hu lai yọ aarẹ Buhari silẹ pẹlu bi o ṣe na owo to yẹ ki wọn fi tun papakọ ofurufu ti ipinlẹ Port Harcourt, ti ko le ni biliọnu meji naira.
Eekan ni ẹgbẹ oṣelu APC, Jonathan Vatsa lo fikun pe, Aarẹ Buhari naa sọ oju nu lori ẹsun ti wọn fi kan Fani-Kayode lori ipa to ko ninu iwa ajẹbanu ''Dasukigate''.


















