Covid-19: Ìjọba Osun ní abẹ́rẹ́ covid-19 ti di dandan fáwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àtàwọn elétò ìlera

Oríṣun àwòrán, Osun State Government
Gomina ipinlẹ Osun, Adegboyegba Oyetola ti paa laṣẹ fun gbogbo awọn alabaṣiṣẹ pọ rẹ, awọn oṣiṣẹ ijọba, awọn eleto ilera atawọn nipinlẹ naa lati gba abẹrẹ ajẹsara covid-19.
Gomina Oyetola ṣalaye pe igbesẹ yii jẹ ọkan lati dẹkun ajakalẹ arun coronaviris nipinlẹ naa.
Gomina sọrọ yii ninu atẹjade kan ti olori awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Osun fi sita.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Obìnrin kan wọ ‘Wedding Gown’ láti wá ọkọ lójú pópó. Òpin ayé dé!
- PDP Oyo sọ̀rọ̀ lórí pé Seyi Makinde ń lọ sẹ́gbẹ́ APC
- Ìdí rèé lórí bí mo ṣe di oníyàwó márùn-ún, ẹjọ́ mi kọ́ - Ọkọ Lizzy Anjorin
- Ewú n bẹ̀ nínú ṣíṣe ádùrá nínú igbó, kẹ́ má bà kó sọ́wọ́ ajínigbé - ọlọ́pàá ṣèkìlọ̀
- Ẹ wo ohun tí Ooni yóò ṣe fáwọn olóṣèlú bó se wọ ìpèbí lọ fọ́dún Ọlọ́jọ́
- Ìwà ọ̀daràn àti òmùgọ̀ ní kí Nàíjíríà jẹ gbèsè kún gbèsè - Obasanjo
- Jonathan, má yẹ̀yẹ́ ara rẹ láti díje ìbò ààrẹ 2023 - Ọ̀gá ẹgbẹ́ àwọn gómìnà kìlọ̀
- A kìí ṣọ̀rẹ́ èrò ká yọ̀ lọ̀rọ̀ Fani-Kayode, ajá rẹ̀ kò mọ ẹni a kìí gbó mọ́ - Salihu Lukman
- Tinubu là ń dúró dè láti sọ ìpinnu wa fétò ìṣèlú 2023 - Akeredolu
- Láì sí ẹ̀kùn àríwá, òfo ní ìpínlẹ̀ Eko, Rivers lórí owó ọjà - Masari
- Buhari, káàbọ̀ sí Amẹ́ríkà àmọ́ ohun tà ń fẹ́ rèé - Yoruba Nation
Oyetola sọ ninu atẹjade naa pe ijọba ipinlẹ Osun ṣetan lati ge ọwọja covid-19 kuru nipinlẹ Osun.
O ni idi niyii ti ijọba fi pese abẹrẹ coronavirus lawọn ileeṣẹ eto ilera kaakiri ipinlẹ Osun fawọn oṣiṣẹ lati le gbaa.
Gomina Oyetola ni gbigba abẹrẹ yii lo le daabo bo awọn oṣiṣẹ atawọn araalu lọwọ arun covid-19 to n ṣọṣẹ ni Naijiria.
Ijọba ipinlẹ Osun sọ ninu atẹjade ọhun gbogbo awọn ti ọrọ kan ko gbọdọ kọ eti ikun si aṣẹ gomina yii.
Bakan naa ni gomina rọ awọn oṣiṣẹ lati maa tẹle ilana ati dẹkun covid-19 bii ibomu wiwọ ati titakete siraẹni.
Gomina tun rọ wọn pe ki wọn yago fun apejọ ọpọ eeyan, ki wọn si maa fọ ọwọ wọn deedee pẹlu ọsẹ ati omi.
Oyetola rọ gbogbo awọn olori ileeṣẹ ijọba, ile ẹkọ giga, ati ijọba ibilẹ lati ri pe awọn oṣiṣẹ to wa labẹ wọn pa aṣẹ ijọba yii mọ.














