Sunday Igboho: Ẹgbẹ́ ìlànà ọmọ Oodua ní kí Yorùbá túbọ̀ kún fún àdúrà kí ayọ̀ náà le dé

Oríṣun àwòrán, Sunday_igboho1/Instagram
Ẹgbẹ to ko gbogbo awọn to n pe fun idasilẹ Orilẹede Yoruba sodi, Ilana Ọmọ Oodua ti ke sawọn ajijagbara fun ilẹ Yoruba naa, lati maa foju sọna fun iroyin ayọ kan laipẹ nipa Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho to wa lahamọ lorilẹede Benin republic.
Maxwell Adelẹyẹ, to jẹ alukoro ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, ṣalaye ninu ifọrọwerọ kan pẹlu iwe iroyin The Punch lọjọ Aje pe, iroyin naa ko ni pẹ de nitori awọn ẹgbẹ ati lọgbalọgba to n ṣugba a rẹ ko sinmi.
Bakannaa lo ke s'awọn ọmọ Yoruba lati tubọ kun fun adura, ki iroyin ayọ naa le dohun ni kiakia.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Seyi Makinde kúró lẹ́gbẹ́ PDP, ìyà tó o fi jẹ wá tó - Igun PDP Oyo
- Afurasí Fulani ti pa aráàlú mi bíi 50, jó ile 254 níná - Oríadé kan figbe ta
- Ìdí rèé lórí bí mo ṣe di oníyàwó márùn-ún, ẹjọ́ mi kọ́ - Ọkọ Lizzy Anjorin
- Obìnrin kan wọ ‘Wedding Gown’ láti wá ọkọ lójú pópó. Òpin ayé dé!
- Gbogbo òṣìṣẹ́ ọba l‘Osun, abẹ́rẹ́ Covid-19 di ọ̀rànyàn fún yín bíbẹ́ẹ̀ kọ́... Oyetola
- Ewú n bẹ̀ nínú ṣíṣe ádùrá nínú igbó, kẹ́ má bà kó sọ́wọ́ ajínigbé - ọlọ́pàá ṣèkìlọ̀
- Sanwo-Olu buwọ́lu òfín máfi ẹran jẹko láàrín ìgboro l'Eko
- PDP Oyo sọ̀rọ̀ lórí pé Seyi Makinde ń lọ sẹ́gbẹ́ APC
Ni ọjọ kinni oṣu keje ọdun 2021 lawọn oṣiṣẹ DSS kọlu ile Sunday Igboho , wọn mu eeyan mejila, won si tun pa eeyan meji miran nibẹ ṣugbọn ori ko Sunday Igboho ni titẹ yọ lọjọ naa.
Awọn ọlọpaa ni papakọ ofurufu Cadjèhoun Airport nilu Cotonou mu Sunday Igboho nigba to n gbiyanju ati rinrinajo lọ sorilẹede Germany pẹlu iyawo rẹ.
Wọn ti fi iyawo rẹ silẹ, ṣugbọn Igboho funrararẹ ṣi wa ni lọgba ẹwọn lorilẹede Republic of Benin.
Laipẹ yii ni Sunday Igboho ke sawọn ololufẹ rẹ lati maṣe lo orukọ oun fun iwọde kankan lọwọ yii.
Lasiko to fi wa lọgba ẹwọn to n reti idajọ ni Benin Republic, Onidajọ Ladiran Akintọla tileẹjọ giga kan nipinlẹ Ọyọ ti paṣẹ pe ki DSS o san ogun biliọn naira fun Sunday Igboho lori ikọlu ile rẹ atawọn dukia olowo iyebiye ti wọn bajẹ nibẹ.




















