Yoruba Nation Rally shooting: Ẹrí rè é pé lóòótọ́ ní ọta ìbọn pá Jumoke Adeleke lásìkò ìwọ́de Yoruba Nation

Kọmisaana ọlọpaa nipinlẹ Eko ati oku ọmọ ti wọn pa ni Ojota

Oríṣun àwòrán, others

Imọlẹ ti bẹrẹ si ni tan si ọrọ iyinbọnpaniyan arabinrin Jumoke Oyeleke ti ọta ibọn ṣekupa lasiko iwọde Yoruba Nation lọjọ Kẹta oṣu Keje ọdun yi.

Ko si sẹyin bi ileeṣẹ ọlọpaa ni Eko ṣe gba pe lootọ ni ọta ibọn ba Jumoke to ṣi mu ẹmi rẹ lọ.

Ọlọpaa to wa nidi iwadii iṣẹlẹ yi, IPO, Onyeisi Nwaolai lo jẹri si ọrọ yi ninu atẹjade to gbe sita nipa ohun to wa nidi iku Jumoke.

Ninu iwe ijẹri yi ti ileeṣẹ iroyin Naijiria Punch sọ pe o tẹ awọn lọwọ,awọn ọlọpaa lawọn ko le sọ pato ẹni to yinbọn naa ṣugbọn ọta ibọn ba Jumoke lootọ.

O sọ ninu iwe naa pe ''eeyan mẹjọ lo mu ẹri wa fun wa to fi mọ iya oloogbe Jumoke ati ẹni to ni ṣọọbu ti ọta ibọn ti ba,Tosin Oyemade''

Àkọlé fídíò, Igangan Mayhem: Obìnrin Fulani kan ní òun pàdánù ọkọ, ọmọ mẹ́ta àti gbogbo dúkìá torí ìjà

''Iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ naa amọ ati ribi fidi ọrọ mulẹ bayi pe ọta ibọn ti a ko mọ ẹni to yin lo ba Jumoke''

Ninu ọrọ rẹ bakan naa, Onyeisi sọ pe awọn ri nkan ija oloro gba lọwọ awọn oluwọde kan ati pe awọn ti n ṣe ayẹwo finifini lori wọn.

Bi a ko ba gbagbe lọjọ Kẹta oṣu Keje ni awọn oluwọde Yoruba Nation Rally pe jọ si ọgba Gani Fawehinmi to wa ni Ojota.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba tawọn ọlọpaa bẹrẹ si ni le awọn oluwọde yi ni ọta ibọn ba Jumoke ni ṣọọbu rẹ to wa ni Ojota lẹba ibi ti iwọde yi ti waye.

Awọn ọlọpaa kọkọ sọ ni ọjọ naa lọhun pe oku tawọn eeyan gbe ju sibẹ ni oku Jumoke wi pe kii ṣe ọta ibọn lo ba a.

Ṣugbọn awọn mọlẹbi Jumoke ati awọn araadugbo sọ pe nigba tawọn ọlọpaa le oluwọde wọ adugbo naa ni ọta ibọn pa Jumoke.

Ko pẹ si igba naa lawọn ọga ọlọpaa pada lọ ki mọlẹbi Jumoke si ile ti wọn si gbe oku rẹ lọ si aaye igbokupamọ si ki wọn to pada wa sinku rẹ.

Iwadii ṣi n tẹsiwaju lati mọ boya ọta ibọn lati ọdọ ọlọpaa lo ṣeku pa Jumoke lootọ.

Àkọlé fídíò, Sabaa Akintola: Pẹ̀lú ẹsẹ̀ kan, mo le gun kẹ̀kẹ́, lúwẹ̀ẹ́ tàbí rán aṣọ pẹ̀lú ẹ̀kọ́ dókítà