Igangan Mayhem: Obìnrin Fulani kan ní òun pàdánù ọkọ, ọmọ mẹ́ta àti gbogbo dúkìá torí ìjà
Yoruba ni ọrọ kanlẹ, kan baale, koda yoo kan jẹjẹ ni mo joko mi nitori ibẹrẹ ogun laa mọ, ko si ẹni to le sọ opin rẹ.
Obinrin Fulani kan ree, Aishatu Saado to n fi omije salaye ipo ibanujẹ ayeraye to wa bayii nitori aawọ ati rogbodiyan to waye laarin ẹya Yoruba ati awọn Fulani.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Aishatu ni lẹyin ti Sunday Igboho wa si Igangan, to si le Seriki Fulani kuro, ni awọn araalu sọ fun ọkọ oun pe ko bura lati maa gbe nilu naa lai gba abọde fun awọn lọdọ Fulani ẹgbẹ rẹ.
- Wo orúkọ ìye àwọn tó kú nínu ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn ní Igangan
- Ta bá gba Seriki Fulani padà sí Igangan, a fi ọwọ́ ara wa, pa ara wa ni - Aráàlú
- Ẹ̀yin Fulani, ẹ yàgò fún ilẹ̀ Yorùbá lásìkò yìí- Iba Gani Adams
- Sunday Igboho ṣàbẹ̀wò sí Igangan lẹ́yìn ìkọlù, àmọ́...
- Jàndùkú Yorùbá sá mi lọ́bẹ́ nínú yàrá mi ní Igangan - Aya seriki Fulani
- Alaafin Oyo, Oba Adeyemi yarí lórí isẹ̀lẹ̀ ìsekúpani tó wáyé ní Igangan
- Ẹ̀yin olóṣèlú, ẹ má fi ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn Igangan dá ìjà ẹlẹ́yàmẹ̀yà sílẹ̀- YWG
- "Bí Buhari kò bá dáàbò bo aráàlú, Sunday Igboho àtàwọn èèyàn míì yóò ṣé"
- A ti ri pé wọ́n fẹ́ kí àwa Fulani kúrò ní ilẹ̀ Yoruba - Seriki Igangan
- Àwọn ọ̀dọ́ Igangan fárígá pé Seyi Makinde kò dúró gbọ́ èrò àwọn lásìkò àbẹ̀wò rẹ̀
O ni ọkọ oun bura lootọ amọ ko pẹ lẹyin igba naa ni awọn Fulani wa kọlu Igangan, ti wọn si pa ọpọ eeyan, ti wsn tun ba ọkẹ aimọye dukia jẹ.
Obinrin Fulani naa idi ree ti awọn eeyan kan fi wa kọlu awọn, ti wsn si pa ọkọ oun ati ọmọ rẹ mẹta pẹlu ọmọ-ọmọ rẹ kan.
Koda, o fikun pe wọn jo gbogbo dukia awọn, ti oun si wa ni kolobo bayii nitori ko si ilegbe mọ tabi dukia kankan, bẹk ni oun ko ni asọ lara mọ.
Obinrin naa, to n gbe nile ọmọ ẹgbọn ọkọ rẹ to ti di oloogbe naa ni isẹ Alfa ni ọkọ oun n se ati agbẹ, awọn kii si se darandaran rara.





