Sunday Igboho; Seriki Igangan ní kò sí ẹni tó ran àwọn lọ́wọ́ látí ìgbà ìṣẹ̀lẹ̀ Ibarapa

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho; Seriki Igangan ní kò sí ẹni tó ran àwọn lọ́wọ́ látí ìgbà ìṣẹ̀lẹ̀ Ibarapa

Seriki Ibarapa ni ipinlẹ Oyo, Abdulkadri Saliu ni o da awọn loju pe wọn ko fẹ ki awọn Fulani darandaran durọ ni ilẹ Yoruba.

Saliu sọ eyi lasiko to n ba BBC Yoruba lori igbe aye rẹ lati igba ti wọn ti kuro ni Ibarapa pada si Ilorin.

Seriki ni ile ni oun pada si nitori ọmọ bibi ilu Ilorin ni oun, ki oun to lọ si Ibarapa lati igba ti oun ti wa ni ọdọ, ki oun to fẹ iyawo.

O fikun wi pe oun ko ba ile jẹ ni oun ṣe pada si ile ni Ilorin, nibi ti oun ati awọn eniyan oun wa, amọ ọpọlọpọ iyawo oun lo pada si ile baba wọn nitori ko si ibi ti wọn yoo duro si.

Bakan naa ni Seriki Abdulkadri Saliu ni ko si ẹnikẹni ni ijọba to pe awọn tabi ran awọn lọwọ, to fi mọ gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde.