Nigeria police ban: Ọlọ́pàá fòfin de lílo "siren" àti "tinted glass" lọ́nà àìtọ́

ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, @Nigeria Police

Ọlọ́pàá fòfin de lílo "siren" àti "tinted glass"

Ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá fòfin de lílo"siren" àti "tinted glass

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Adamawa ti fòfin de lilo sinrin ati gilaasi dudu(tinted glass) to fi mọ nọmba ti wọn da nkan bo nipinle naa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Adamawa, DSP Suleiman Nguroje lo f'ọrọ yii lede ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Iṣẹgun.

Nguroje ṣalaye pe awọn nkan yii le ṣi awọn oṣiṣẹ eleto abo lọna ati pe wọn tun le dẹru ba awon eeyan nipinle ọhún.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa Ondo: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelo

O fikun ọrọ rẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo mii lati ri pe iwa ọdaran di afiseyin bi eegun n fi aṣọ ni Adamawa.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni awon agbofinro ti bẹrẹ si ni dawọn awakọ duro lati ṣe àwárí awọn ọdaran to n da ilu ru.

O ni: "Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Adamawa fi n da awọn eeyan ipinlẹ naa loju pe abo to peye yoo wa fun wọn lọdun 2021," Nguroje lo sọ bẹẹ.

O rọ awọn eeyan ipinlẹ naa lati fọwọ so ọwọ pọ pẹlu awọn agbofinro lori ọrọ eto aabo.

Àkọlé fídíò, Big breast: Oluwatosin Adegboro, Oluwaseun Amoo, Remi Fatolu: Ẹlòmíì ń fi irú ọyàn wa tọrọ