Oluwo: Èmi ni adarí àti aláṣẹ lórí gbogbo òrìṣà ilẹ̀ Yoruba àti káàkiri àgbàyé

Oríṣun àwòrán, Oluwo of Iwo
Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi ti sọ pe oun gangan lo n ṣoju Ọlọrun Eledumare, nitorinaa ni oun ṣe n joko lori itẹ rẹ nile aye.
Ọba Adewale lo fi ọrọ naa lede loju opo Instagram rẹ, nibi to ti sọ pe oun ni alaṣẹ lori gbogbo awọn oriṣa.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni "emi ni adari ati alaṣẹ lori gbogbo oriṣa ilẹ Yoruba ati kaakiri agbaye."
Kabiesi naa tẹsiwaju pe "aafin Ọba jẹ aafin Ọlọrun nile aye, eyii to n tumọ si Ọlọrun Iwo."
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
"Emi ni ojulowo Oluwo nitori Ọlọrun Eledumare gangan ni Ọlọrun Iwo, emi Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi Tẹlu 1 si ni aṣoju Ọlọrun ninu ẹran ara gẹgẹ bii Oluwo."
- Wo ọkùnrin tó dáná sun ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ torípé kó gbà látí jẹ́ aya rẹ̀
- Ààrẹ ti kọ̀wé fipò sílẹ̀ torí èèyàn méjì t'ọ́lọ́pàá pa níbi ìfẹ̀hónúhàn lòdì sí ìjọba
- Ìpínlẹ̀ Eko ní èèyàn 136 nínú èèyàn 152 lápapọ̀ tó lùgbàdì àrùn Coronavirus ní Nàìjíríà
- Awọn ọlọ́pàá gbòde kan ní Ajah, ọwọ́ tẹ àwọn afurasi tó ń jalè
Oluwo ṣalaye pe aafin oun ní ilu Iwo ni aafin Ọlọrun nile aye ko sì sí Ọba miran mọ nitori Ọba kii pe meji laafin.
O ni orogun ni awọn oriṣa jẹ si Ọlọrun nitori ko ṣeṣe ki eeyan ki Ọlọrun lara oun ko tun lọ foribalẹ fun awọn oriṣa miran.
Ọpọ awọn ololufẹ rẹ lori ikan Instagram lo ti n fi erongba wọn lede lori ọrọ naa.


















