Ondo politics: Ta ló ń lépa ẹ̀mí Eyitayo Jegede, olùdíje gómìnà Ondo lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP?

Oríṣun àwòrán, Eyitayo Jegede
Lẹyin idibo sipo gomina to waye ni ipinlẹ Ondo, eyi ti Gomina Akeredolu ti fi ẹyin oludije fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Eyitayọ Jẹgẹdẹ atawọn oludije marundinlogun miran gbolẹ, ko daju pe ọrọ ti tan laarin Akeredolu ati Eyitayọ o.
Nibayii, ohun ti Eyitayọ Jẹgẹdẹ n pariwo rẹ sita bayii ni pe awọn eeyan kan n lepa ẹmi oun.
- Àwọn ọmọ Naijiria kó owó wọn kúrò ní Áccess Bank' lẹ́yìn tó gbẹ́sẹ̀lé àpò owó àwọn olùwọ́de EndSARS
- 'Banji Akintoye kìí ṣe adarí àwọn ọmọ Yorùbá mọ́, a ti ní ẹgbẹ́ tuntun'
- Ọpẹ́ o! Wo bí agbábọ́ọ̀lù Super Eagles tẹ́lẹ̀, Christian Obodo tí wọ́n jígbé lẹ́ẹ̀kejì ṣe móríbọ́
- Wo ọkùnrin tó dáná sun ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ torípé kó gbà látí jẹ́ aya rẹ̀
O ni eyi ko si ṣẹyin bi oun ṣe pe ẹjọ kotẹmilọrun tako abajade ibo gomina ipinlẹ Ondo to waye lọjọ Kẹwaa oṣu kẹwaa ọdun 2020.
Atẹjade kan eyi ti agbẹnusọ fun Amofin Jẹgẹdẹ, Gbenga Akinmoyọ gbe jade ṣalaye pe awọn hu gbọ pe awọn alagbara kan n ṣe ipade lori igbesẹ ipẹjọ naa eleyii ti wọn ni o ṣeeṣe ko ṣẹ wọn leegun ẹyin.

Oríṣun àwòrán, Arakunrin akeredolu/twitter
Amọṣa o, ikọ ipolongo fun Gomina Rotimi Akeredolu ati igbakeji rẹ, Aiyedatiwa ti ṣe akawe ẹsun naa gẹgẹ bi yẹyẹ lasan lati fi mu ki awọn eeyan ri toun ro.
Atẹjade kan ti ikọ naa gbe jade latọwọ Ọlabọde Richard Ọlatunde ṣalaye pe ko si ẹni ti ko mọ pe "abaniwọran ba o ri da ni Jẹgẹdẹ" ati pe o fẹ ki wọn mọ pe oun naa ṣi wa loju agbo oṣelu ni.
O ni bi o ba jẹ lootọ ni ọrọ ọhun ri, ile lo yẹ ki Jẹgẹdẹ o wo nitori pẹlu aawọ ọrọ adari to n waye laarin ẹgbẹ oṣelu PDP, ko yẹ ko wota lati mọ awọn to lee maa lepa ẹmi rẹ.











