Sunday Igboho: Oluwo kọ lẹ́ta sí Buhari pé òun yóò mú Igboho wá bẹ̀bẹ̀ tí àkókò bá tó

Sunday Igboho n dọbalẹ fun Oluwo tilu Iwo

Oríṣun àwòrán, Oluwo of Iwo

Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, Telu Kinni, ti kọwe si aarẹ Muhammadu Buhari lori ọrọ Ajijagbara fun ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Igboho.

Ninu ẹda iwe naa ti Oluwo fi sọwọ si BBC Yoruba lo ti salaye pe Igboho bẹrẹ isẹ ijijagbara rẹ gẹgẹ bii olugbeja fun awọn alailagbara ni amọ ilana to n tọ ko ye oun.

Oluwo ni oun ko si lara awọn Ọba to n se atilẹyin fun ijijagbara Sunday Igboho rara bi o tilẹ jẹ pe oun maa n kilọ fun pe ko sọra se nigba ti oun ba gbọ nipa igbesẹ to ba fẹ gbe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, 'Nínú ìran, Olúwa sọ fún mi pé èmi ni màá tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ìráńṣẹ́ Wòlìí TB Joshua, kàyéfì ti ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ mi báyìí'

O ni Igboho wa si aafin oun lọdun 2018, ti oun si gba ni imọran lori oun to ba wa amọ o kuna lati mọ iyatọ laarin ijijagbara ati kikọju ija si ijọba.

"Nigba to tiẹ ya, se lo n bu gbogbo alẹnulọrọ, to si n fi oniruuru ẹsun kan wọn, emi si ni ẹni akọkọ to ni mo n kọrin fun isọkan Naijiria.

Sunday Igboho n dọbalẹ fun Oluwo tilu Iwo

Oríṣun àwòrán, Oluwo of Iwo

Gẹgẹ bi baba, mo dari jin, bẹẹ naa ni mo si n rọ aarẹ wa ni Naijiria lati si oju aanu wo ọmọ rẹ, Sunday Igboho."

Oluwo ni alaimọkan ni Igboho nidi sise akoso awọn nnkan pẹlu ijọba amọ lootọ lo jẹ ẹbun nla fun ilẹ Yoruba.

O ni Igboho ti jẹjẹ bayii lati maa tẹti si awọn agbaagba, ti yoo si maa sọrase lori awọn igbesẹ to ba n gbe lati akoko yii lọ.

"Mo n rọ aarẹ lati seraro lori awọn agbofinro to n lepa Igboho, mo si mọ pe isẹlẹ yii yoo tubọ mu ki okun isọkan Naijiria tubọ yi dain si ni.

Igboho ti jiya pupọ, yoo si jawọ ninu ipe fun iyapa Naijiria to n se, maa mu wa sọdọ yin fun ijiroro alaafia nigba ti akoko ba to."

Àkọlé fídíò, Ṣé o lè gbé orí rẹ lọ sọ́dọ̀ fárífárí alábẹ kó dán bí àwọn tó ní àwọn kò lè lo "clipper láéláé yìí?

Oluwo fikun pe orilẹede Naijiria ko se e pin lọsan kan, oru kan nitori idi kan tabi oniran atipe, agbara Naijiria ko si ninu oniruuru ede ta jẹ nikan bikose ninu idarijin pẹlu.

O wa mu wa siranti nipa iku to pa MKO Abiola, Ken Saro Wiwa atawọn ajijagbara miran ni ẹkun kọọkan ni Naijiria eyi tawọn ọmọ orilẹede yii ko le tete gbagbe.

"Amọ bi ọmọ ko ba tete maa fi itan kọgbọn, baba to ba dara ko ni da ọmọ nu pẹlu omi iwẹ, mo si n sọ eyi, ki aarẹ le mọ pe a wi fun Sunday Igboho to nipa ijijagbara fun idasilẹ orilẹede Yoruba to n se, ko gbọran ni."

Àkọlé fídíò, 'Ìjámbá Ọ̀kadà ló dédé sọ mi di òdi, ìyàwó tí mo yó ìfẹ́ rẹ̀ náà tún wá jẹ́ odi'

Nipari, Oluwo wa kan saara si aarẹ Buhari lori aayan rẹ lati gbogun ti iwa ọdaran, agbebọn, ijinigbe ati bo se mu agbega awọn ohun eelo amayedẹrun nibaada.