Wunmi, aya Mohbad ní ẹni tó bá fẹ́ ṣe DNA fọ́mọ òun, kó wá sanwó rẹ̀, àbúrò Fayose yọjú

Oríṣun àwòrán, Facebook/Isaac Fayose
Bi ẹnu ṣe n kun sise ayẹwo DNA fun ọmọ olorin takasufe to di oloogbe, Ilerioluwa Aloba , ti ọpọ mọ si Mohbad, aburo Gomina tẹlẹri nipinlẹ Ekiti, Isaac Fayose ni oun ṣetan lati san owo ayẹwo naa.
Ninu fọnran kan to gbe sori opo ayelujara ikani ibanidọrẹ Facebook rẹ, Fayose ni owo wa nilẹ, ti awọn mọlẹbi Mohbad ba setan lati se ayẹwo naa.
Bẹẹ ba gbagbe, lati igba ti Mohbad ti jade laye ni ọpọ ọmọ Naijiria ti n pe fun ayẹwọ DNA fun ọmọ Mohbad.
"Mo setan lati tọju ọmọ naa, boya ọmọ Mohbad ni tabi bẹ́ẹ̀kọ́"
Ninu ọrọ rẹ, Isaac Fayose ni “Mo setan lati san owo ayẹwo DNA ọmọ Mohbad.
Ni gbogbo igba ti awọn mọlẹbi ba ni awọn ṣetan, emi naa ṣetan pẹlu wọn, koda ki wọn ni o ya lọla, mo ṣetan.
“Mo dẹ fẹ ki ẹ mọ, boya ọmọ yẹn jẹ ọmọ Mohbad tabi kii ṣe ọmọ Mohbad, mo setan lati pese itọju fun ọmọ naa."
Fayose ni oun gbe igbesẹ yii lati jẹ ki alaafia jọba laarin Baba Mohbad ati Iyawo Mohbad, eyi to ni yoo fun Mohbad ni anfani lati suure lọna ọrun.
“Wunmi, ni gbogbo igba to ba ṣetan, itọju wa nilẹ, mo si setan lati san owo DNA naa.
“Mo setan lati san owo DNA yii lati jẹ alaafia jọba laarin iwọ ati Baba ọkọ rẹ.
“Mo n rọ yin pe ki ẹ mu ọjọ ti ẹ fẹ se DNA yii ati ibi ti ẹ ti fẹ se,
"Koda, mo le fi owo naa sọwọ sii akanti yii bayii.
“Ẹ jẹ ki a pari ija yii ki Mohbad le sun daada.”
Wunmi sọ fun mi pe ẹni to ba fẹ se ayẹwo DNA, ko san owo rẹ - Iyabo Ojo
Saaju ni gbajugbaja oṣere tiata, Iyabo Ojo ni oun kan si Iyawo Mohbad, Wunmi, to ni o sọ fun oun pe oun setan fun ayẹwo DNA.
O ni sugbọn awọn to n beere fun ayẹwo naa lo gbọdọ pese owo lati se.
Iyabo Ojo salaye pe Wummi ni, ko ti si ẹnikẹni to kan si oun lati wa lọ se ayẹwo DNA, to si jẹ pe ori ayelujara ni oun ti n ri ọpọ wọn ti wọn n sọrọ.
“Mo bi pe se Baba ọkọ rẹ tabi agbẹjọro ti kan si, o ni rara pe oun ko ti ri nkankan.
“O ni oun ko le lo owo ara oun se ayẹwo DNA nitori oun ko ni owo lọwọ ati pe oun ko ni isẹ lọwọ, ti oun si n tọju ọmọ lọwọ.
“ O ni awọn to n bẹrẹ fun ayẹwo DNA naa lo ma wa san owo fun DNA, ti wọn yoo si se ayẹwo naa lorilẹede Naijiria ati oke okun.”















