ìjàńbá iná ṣẹlẹ̀ n'Ilorin, ọjà ọdún àìmọye Naira jóná ráúráú

Inu iporuru ọkan lawọn oniṣowo Ọja Tuntun to wa niluu Ilọrin ipinlẹ Kwara wa bayii, nitori ina ojiji to ṣẹyọ ninu ọja naa loru Ọjọruu.
Ọpọ dukia atawọn ọja olowo iyebiye si jona kọja sisọ.
Bo tilẹ jẹ pe awọn panapana lọ sibẹ, nnkan ti bajẹ jina ki wọn too de, ṣọọbu mẹẹdogun lo jona ninu awọn ẹgbẹlẹgbẹ ṣọọbu ati yara ikẹrusi to wa ninu ọja naa.
"A o le fidi ohun to fa ijanba naa mulẹ nitori ko si ina monamona ninu ọja naa fun ọdun mẹta gbako”

"A o le fidi ohun to fa ijanba naa mulẹ tori ko si ina mọnamọna ninu ọja naa fun ọdun mẹta gbako”
BBC Yoruba fọrọwerọ pẹlu alaga ẹgbẹ olutaja Igbo ni ipinlẹ Kwara, Alufa Uche Goodwill, ẹni to ni ko si ẹni to le sọ ohun to sokunfa ijanba ina naa ni pato.
Alufa Goodwill sọ pe nkan bii ago mẹsan ọjọru ni oun gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ti oun si sare de ọja, sọọbu mẹẹdogun si n jo.
"A o le fidi ohun to fa ijanba naa mulẹ nitori ko si ina monamona ninu ọja naa fun ọdun mẹta gbako.
O ti pẹ ti iṣẹlẹ ijanba ina ti n ba wa finra, eyi lo fa a ti a fi sofin pe ki gbogbo awọn ti wọn n lo ẹrọ amunawa maa pa ẹrọ wọn, o pẹ ju ago marun-un irọlẹ.
Eyi yoo mu ki o baa le tutu, ko to di ago mẹfa irọlẹ ti wọn maa n ti ọja.
"A ṣekilọ fun awon telọ ti wọn n fi ayọọnu eleedu lọ aṣọ pe ki awọn naa dawo duro ni ago marun-un bakan naa, ki wọn si fi omi pa eedu wọn daada ki wọn to lọ sile ni ago mẹfa.
Pẹlu gbogbo eyi, ijamba ina si tun sẹlẹ, a fẹ ki ijọba wa gba wa o"

Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ yáwó rajà ọdún sí sọ́ọ̀bù ni, kí gbogbo rẹ̀ tó jóná pátápátá – Olùtajà
“Mo sẹsẹ ti ọja Aba de ni, nibi ti mo ti ra ọja keresi pẹlu owo ti mo ya, mi o ni nkankan mọ bayii.”
Ọkan lara awon to fara kaasa iṣẹlẹ naa, arabinrin Doris Chukwudi salaye ọgbẹ ọkan to ni nipa ijanba naa.
"Mo ni sọọbu mẹrin to kun fun ọja ti owo rẹ to ogun miliọnu naira, gbogbo rẹ lo ti jo patapata bayii.
Mo sẹsẹ ti ọja Aba de ni, nibi ti mo ti ra ọja keresi pẹlu owo ti mo ya, mi o ni nkankan mọ bayii.”
Ada Nwangwo ni tirẹ sọ pe, oun ṣẹsẹ ja ọja to to milionu mẹẹdogun naira lati iluu Eko ni ọjọru ni.
"Mo fẹ ki ijọba ran wa lọwọ nitori tijẹ ati titọju ẹbi mi ti di ogun bayii tori mo gbọdọ san owo ti mo ya lati ra awọn ọja ọhun.
Abdulfatai Nafisat, ti o jẹ oluransọ padanu gbogbo masinni iransọ rẹ ati ẹrọ amunawa to fi mọ awọn aṣọ onibara rẹ.
Bakan naa, Wasilat Aliyu ati Rebecca Samuel, ti awon mejeeji n ta ounjẹ padanu gbogbo awọn ọja wọn.

Ki ni Ileeṣẹ panapana Kwara sọ?
Agbẹnusọ ileeṣẹ panapana ni Kwara, Hassan Adekunle, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ l’Ọjọbọ.
O ni awọn gba ipe pajawiri kan loru ọjọru lati agbegbe Ọja Tuntun pe ọja ọhun n jona, tawọn si lọọ pana ọhun ni kiakia.
O tẹsiwaju pe Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq, wa sibi iṣẹlẹ naa loru ganjọ tawọn gunlẹ sibi iṣẹlẹ naa, lawọn ri gomina.
O ni gomina naa si kẹdun pẹlu gbogbo awon onisowo ti ijanba naa kan.
Ọga agba ajọ panapana ni Kwara, Ọmọọba Falade John Olumuyiwa, o fi ibanujẹ ọkan rẹ han lori iṣẹlẹ naa.
O wa rọ gbogbo olugbe ipinlẹ ọhun lati maa ṣọra gidigidi lori gbogbo ohun ti wọn ba n ṣe lojoojumọ, ki wọn si maa pa gbogbo ina ti wọn ba fẹẹ sun lalẹ tabi kuro ni ṣọọbu wọn.
Iwadi jẹ kaa mọ pe gbogbo dukia to jona nibi iṣẹlẹ laabi naa le ni Ọgọrun milionu naira.















