Wo iye ẹlẹ́wọ̀n ọmọ Palestine tó wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Israel àti iye tí yóò gba ìtúsílẹ̀

Aworan awọn olufẹhonuhan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ida ogoji ninu awọn ẹlẹwọn Palestinian ti yoo gba itusulẹ lo jẹ awọn ọdọ ti ọjọ ori wọn jẹ mejidinlogun.
    • Author, Alaa Daraghme
    • Role, BBC News Arabic
    • Reporting from, Ramallah

Orilẹede Israel ati Hamas ti gba lati ṣe pasiparọ awọn ẹlẹwọn, awọn ti wọn jigbe silẹ ati lati dawọ ogun duro fun ọjọ mẹrin.

Ohun to ye Ileeṣẹ BBC ni pe idaduro ogun yoo bẹrẹ lago mẹwaa Ọjọbọ yoo, ti pasiparọ awọn ẹlẹwọn yoo waye lọsan ọjọ naa.

Israel ti fi akojọpọ ẹlẹwọn ọọdurun sita ti wọn yoo gba itusilẹ. Ọpọ wọn ni ọjọ ori wọn jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun tabi mejidinlogun. Ẹlẹwọn 274 ninu awọn ẹlẹwọn lo jẹ ọkunrin.

Wọn gbe akojọpọ orukọ awọn eeyan sita nitori ilana ofin ni Israel. Saaju ki wọn to tu ẹlẹwọn silẹ, awọn araalu israel ni anfani lati gbe ẹjọ naa si ilẹ ẹjọ ga ju lọ ni Israel.

aworan olufẹhonuhan mi Gaza

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni ipele akọkọ, ti yoo waye Lọjọbọ, Hamas yoo tu awọn ẹlẹwọn obinrin ati ọmọde adọtaa silẹ, ti yoo si pin wọn si isọri mejila tii lọjọ kan. Israel naa yoo wa tu ẹlẹwọn 150 silẹ

Ni ipele keji, wọn yoo fikun ọjọ kan ku ọjọ ti wọn fi da ogun duro fun ẹlẹwọn mẹwaa to ba tu gba itusilẹ. Israel yoo tu ẹlẹwọn Palestinian 150 silẹ if Hamas ba tu ẹlẹwọn adọta silẹ.

Awọn olori orilẹede agbaye tẹwọgba aba naa ninu ipade to waye ni Qatar.

Hamas, ikọ ologun ti ajọ EU, UK ati US sapajuwe gẹgẹ bii ikọ ọdaran ti sekupa o le ni ẹgbẹrun kan eeyan, ti wọn si tu ji o le igba eeyan gbe wa si Gaza lọjọ Keje oṣu kẹwaa, ọdun 2023.

Lati igba naa, o le ni ẹgbẹrun mẹrinla eeyan Palestinian to n gbe ni Gaza lo ti dero ọrun nitori ikọlu Israel.

Itan nipa pasiparọ awọn ẹlẹwọn

Bakan naa ni orilẹede Israel tu ṣe akọsilẹ awọn ẹsun ti wọn fi kan awọn ẹlẹwọn ọọdurun ti wọn fẹ gba itusilẹ.

Iṣekupani, jiju odo oloro, sisọ oko, gbigbimọpọ lati ṣe ohun ija oloro ati awọn ẹsun mii ni wọn fi kan awọn ẹlẹwọn yii.

Pasiparọ ẹlẹwọn to waye saaju waye ninu oṣu kẹwaa ọdun 2011 nigba ti ọmọ ologun Israel, Gilad Shalit gba itusilẹ lẹyin ọdun marun un to ti wa ni ahamọ Hamas.

Wọn ti ṣe pasiparọ awọn ẹlẹwọn Palestine 1,026 gẹgẹ bi ti adehun to wa laarin Israel ati ikọ ologun Hamas.

Diẹ ninu awọn ẹlẹwọn to gba itusilẹ yii ni wọn ti fẹsun iṣekupani kan paapa Yahya Sinwar, olori Hamas niluu Gaza ati ọkan lara awọn ologun ti wọn fẹsun kan fun ikọlu ọjọ keje oṣu kẹwaa.

Aworan bi ọmọ ologun Israeli, Gilad Shalit ṣe igba itusilẹk (L), Israeli Prime Minister Benjamin Netanyahu (2nd, L) and IDF Chief of General Staff Benny Gantz (R) at Tel Nof Airbase on 18 October 2011 in central Israel

Oríṣun àwòrán, Israel Defense Force

Alekun iye awọn eeyan to wa ni ọgba ẹwọn

Iye awọn ẹlẹwọn Palestine to wa ni ọgba ẹwọn Israel to ti ku akuju pẹlu apapọ eeyan ẹgbẹrun meje gẹgẹ bi akọsilẹ ọjọ kẹfa oṣu kọkanla eyi ti Addameer, Ileeṣẹ kan lorilẹede Palestinie to n ja fun ẹtọ ọmọniyan salaye.

Obinrin ọgọriin ati awọn ọmọde to to igba ti ọjọ ori wọn wa ni mejidinlogun.

Ileeṣẹ adani yii ni ẹgbẹrun mẹta ọmọ Palestine ni ọwọ Israel ti tọ lati igba ikọlu Hamas ti waye lọjọ keje oṣu kẹwaa.

Israel ni Ileeṣẹ Addameer ati awọn ileeṣẹ marun un mi to n ja fẹtọ ọmọniyan gẹgẹ bii ileeṣẹ ọdaran. Ajọ UN ati awọn ẹgbẹ isokan agbaye tako ohun ti Israel sọ.

Ni ipari oṣu kẹsan an, ẹka ijọba Israel nipa ọgba ẹwọn ni awọn ọdọ Palestine 146 lo wa ni ahamọ tabi ọgba ẹwọn gẹgẹ bi ileeṣẹ to n ja fẹtọ ọmọniyan B’Tselem se salaye

Bakan naa ni ileeṣẹ yii fẹsun kan ẹka ijọba to n risi ọgba ẹwọn pe ọdọ mẹrinlelogbọn ni ọna ti ko ba ofin mu.