Òfo ni ìyanṣẹ́lódì táwọn òṣìṣẹ́ ètò ìdájọ́ l‘Osun gùnlé, a kò lọ́wọ́ si - Olú ilé ẹgbẹ́ lahùn

Ọrọ awuyewuye to n waye n'ipinlẹ Osun lori yiyọ adajọ agba ipinlẹ naa ati yiyan ẹlomiiran sipo ti gba ọna mi yọ.
Isẹlẹ ọtun n waye ni bi awọn ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ẹkaeto idajọ nipinlẹ Osun se ṣe ifẹhonuhan, ti ikọlu si waye pẹlu awọn ọlọpaa lasiko naa.
Lẹyìn ikọlu yii si ni alaga ẹgbẹ naa ni ipinlẹ Osun kéde pe awọn yoo gunle iyanṣẹlodi.
Ni bayii olu ileeṣẹ ẹgbẹ naa ti sọ pe, awọn ko ran ọmọ ẹgbẹ naa kankan pe ko gunle ifẹhonuhan tabi iyanṣẹlodi kankan.
Ninu atẹjade kan ti igbakeji aarẹ ẹgbẹ naa, Emmanuel Abioye buwọlu, o ni gẹgẹ bi ẹgbẹ alapọnle, awọn ko ni gbe igbesẹ kankan to lọwọ oṣelu ninu.
O sọ pe gbogbo awuyewuye to n lọ lọwọ n'ipinlẹ Osun l'awọn ti n fi ọkan tẹle pẹlu bi awọn nkan ṣe n fi oruko ẹgbẹ awọn da rugudu silẹ lẹka idajọ ipinlẹ Ọsun.
"Ẹgbẹ́ JUSUN ko lọwọ ninu igbesẹ tawọn ọmọ ẹgbẹ wa n gbe n'ipinlẹ Osun"
Atẹjade naa salaye pe "JUSUN ko fi igba kan pàṣẹ tabi dari awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ pe ki wọn ṣe iwọde ifẹhonuhan tabi ki wọn ti ọfisi ẹka idajọ ni Osun tabi ipinlẹ mii lọna ati fi doju ija kọ ẹnikẹni"
O tẹsiwaju pe JUSUN ko lọwọ ninu igbesẹ kankan tí awọn kan n gbe n'ipinlẹ Osun lori eyikeyi erongba ti awọn ko mọ nípa rẹ.
O ni "igbesẹ yii jẹ ọna ati ba orukọ rere ẹgbẹ wa, to ti wa tipẹtipẹ jẹ ni "
Fún idi eyi, ẹgbẹ naa wa kìlọ pe ki ọmọ ẹgbẹ ohun kankan ma ṣe ba wọn kopa ninu iwọde tabi ifẹhonuhan kankan tabi iyanṣẹlodi tori pe awọn ko lọwọ si.

Oríṣun àwòrán, JUSUN
Àwọn òsìṣẹ́ ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Osun àtàwọn ọlọ́pàá gbéná wojú ara wọn lórí ọ̀rọ̀ adajọ́ àgbà Adepele Ojo

Oríṣun àwòrán, bbc
Loni ọjọ́ kejìdínlógún, oṣu Kọkànlá ọdun 2023, laàkókò tí àwọn òṣìṣẹ́ ile ẹjọ́ gíga tí ipínlẹ̀ Osun fẹ́ ṣe ìpàdé pọ pẹ̀lú àwọn Adajọ ni àwọn ọlọpaa da gaasi tajutaju bolẹ
Bí àwọn òṣìṣẹ́ ile ẹjọ́ gíga tí ipínlẹ̀ Osun ṣe n ṣe ifẹhonuhan láti má fi aaye gba Adajọ Agba Adepele Ojo lati wọ ọ́fíìsì rẹ ni iṣẹlẹ naa waye.
Awọn ọlọpaa fi gaasi tajutaju le awọn oṣiṣe naa, ọ̀pọ̀ lara àwọn sì fara pa pẹ̀lú àwọn akọroyin to lọ síbẹ̀ pẹlu.
Nígbà tí ẹnì to jẹ́ alaga àwọn òṣìṣẹ́ ile ẹjọ́ gíga naa, Olugbenga Olakunle Eludire ba àwọn akọroyin sọ̀rọ̀ lori ìṣẹ̀lẹ̀ náà, sọ pe ẹtọ awọ lawọn n bere fun.
Eludire ni “Ẹtọ wa lawa bere lọ́wọ́ Adajọ Agba Adepele Ojo tí àwọn eeyan wa si ṣe ifehonuhan lori ẹtọ àwọn.
Lójijì ni ọgọrọ àwọn ọlọpaa yà de tí wọ́n sì fi gaasi tajutaju le wa pẹlu koboko tí ọ̀pọ̀ sì farapa yannayanna.”
Eludire ni àwọn ìgbìmò kan lara àwọn adajọ lo pe fun ìpàdé lori ẹtọ àwọn òṣìṣẹ́ náà kì àwọn ọlọpaa to tẹle adajọ agba Adepele to fìyà jẹ lọpọlọpọ ninu wọn.
“Oun ti awa òṣìṣẹ́ bere lọ́wọ́ Adajọ Agba Adepele Ojo ni pe ko da àwọn òṣìṣẹ́ to tí fún ní ìwé idaduro lẹ́nu isẹ padà ati awọn ẹtọ wọn.”
Ní báyìí ẹni to jẹ́ Alaga fún àwọn òṣìṣẹ́ ile ẹjọ́ gíga tí ipínlẹ̀ Osun, Olugbenga Olakunle Eludire tí kede idasẹsilẹ títí ìgbà tí Adajọ Agba Adepele Ojo yoo fi san gbogbo awọn ẹtọ wọn fún wọn.















