Láìnání ìdájọ́ ilé ẹjọ́, Gómìnà Adeleke yọ adájọ́ àgbà ìpínlẹ̀ Osun nípò

Onidajọ Adepele Ojo n ṣeto ibura fun Ademọla Adeleke gẹgẹ bii gomina

Oríṣun àwòrán, Osun defender

Gomina ipinlẹ ṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti paṣẹ fun Adajọ agba ni ipinlẹ naa, Onidajọ Adepele Ojo pe ko lọ rọọkun nile titi di igba ti iwadi yoo fi pari lori awọn ẹsun aṣemaṣe ti wọn fi kan an.

Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan Onidajọ Adepele ni aṣilo agbara ipo rẹ, iwa ijẹkujẹ ati aibọwọ fun ofin.

Ẹsun wọnyi jẹyọ ninu iwe ifisun kan ti o farahan niwaju awọn aṣofin ipinlẹ naa.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Ọṣun, Ọlawale Rasheed fi sita ṣe alaye pe afẹnuko awọn ọmọ ile aṣofin ipinlẹ naa ni gomina tẹle ninu igbesẹ to gbe ati pe gomina Adeleke ti yan Onidajọ David Afọlabi gẹgẹbi adele adajọ agba ipinlẹ naa abyii.

Igbesẹ yii n waye pẹlupẹlu bi ile ẹjọ to n gbọ ẹjọ oṣiṣẹ ati agbanisiṣẹ NICN ni ilu Osogbo ṣe paṣẹ pe ki gomina Adeleke dawọ duro na lori igbesẹ yoowu to ba fẹ gbe lati yọ Onidajọ adepele Ojo.

Àwọn ìròyìn míràn tí ẹ tún lè kà:

Ki ni ile aṣofin sọ?

Onidajọ Adepele Ojo n ṣeto ibura fun Ademọla Adeleke gẹgẹ bii gomina

Oríṣun àwòrán, others

Ile aṣofin ipinlẹ Ọṣun kede afẹnuko rẹ lẹyin ti joko lori awọn iwe ifisun ti wọn gba lori ọrọ Onidajọ Adepele.

Lara aohun ti wọn sọ ni pe:

  • Ki Onidajọ Adepele o fara han niwaju igbimọ to wa nidi ẹka ofin, ẹhonu araalu atawọn ọrọ to ba jọ mọ ofin ni ile naa laarin ọjọ meje si asiko yii.
  • Pe titi di igba ti abajade iwadii naa yoo fi waye, ki Onidajọ Adepele yẹba lati fi aye silẹ fun iwadii to gbọngbọn lori awọn ẹsun naa.
  • Ki gomina o yan adajọ ti ipo rẹ ga julọ lati di ipo naa mu gẹgẹ bi adele adajọ agba ipinlẹ ṣun
  • Ki ẹka iṣakoso ijọba si fi ọrọ to ajọ to ga julọ lẹka eto idajọ leti nipa afẹnuko yii.