Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Oladips olórin tàka-súfèé tó kú lẹ́ni ọdún 28

Oríṣun àwòrán, oladipsoflife/Instagram
Ọladipupọ Ọlabọde Ọladimeji gan-an lorukọ akọrin to doloogbe yii, ṣugbọn Oladips lọpọ eeyan mọ ọ si lagbo orin taka-sufee.
Ọmọ bibi ipinlẹ Ogun ni Oladips jẹ.
Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹta ọdun 1995 ni bi Oladips ọdọmọde olorin to di oloogbe yii.
Olorin taka-sufee ni, o tun maa n kọ orin sinu iwe fawọn olorin mi-in lati gbe jade.
Ọdun 2012 lo bẹrẹ iṣẹ orin, orin to kọkọ kọ lo pe ni akori rẹ n jẹ ‘SUCCESSFUL.’
Ifigagbaga ti D’banj gbe kalẹ to pe ni ‘King is here’ lo jẹ kawọn eeyan mọ Oladips, nitori oun lo gbegba oroke ninu eto naa.
Ibẹ lo si gba wọ ileeṣẹ Reminisce to n gbe awo jade pẹlu Edge Records.
Awọn orin oloogbe yii tawọn eeyan mọ daadaa ni Ajala, Mainland 2 Island toun ati Zlatan jọ kọ ati Lalakukulala toun ati Reminisce jọ kọ papọ.
Ọdun 2019 lo kuro nileeṣẹ Reminisce.
Ọjọ kẹfa, oṣu kẹwaa ọdun 2023 yii lo gbe orin to pe akọle ẹ ni ‘Die Young’ jade.
Ọpọlọpọ olorin ni Oladips ti ba kọrin ri, lara wọn ni Oloogbe Mohbad, Zlatan, Reminisce, T-classic, CDQ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Oladips ku lẹni ọdun mejidinlọgbọn lọjọ kẹrinla, oṣu kọkanla ọdun 2023.
Ohun ti a mọ nipa iku akọrin Oladips ree
Ni nnkan bii aago mẹwaa kọja iṣẹju diẹ lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii la gbọ pe Oladips jade laye ko to di pe iroyin naa gba gbogbo ori ayelujara lọjọ keji ti i ṣe Ọjọru.
Bo tilẹ jẹ pe aṣiri iku to pa akọrin yii ko ti i han saye, awọn nnkan to n tọka pe ọkan rẹ ko balẹ lo gbe jade loju opo ayelujara rẹ ni wakati diẹ ṣaaju ki wọn too kede iku rẹ faye.
Oladips gbe awọn ọrọ kan jade loju opo Instagram rẹ to mu kawọn eeyan maa bẹru pe ki lo n ṣẹlẹ.
Akọkọ ni ọrọ to fi ba ọrẹ rẹ to n jẹ Rasheed sọrọ, nibi to ti kọ ọ pe "jọọ, nibo lo wa?
Mo ti pe nọmba ẹ titi. Mo ni kẹ ẹ yee f’emi nikan silẹ sinu ile yii.
O ti fẹ to miliọnu ikan igba ti mo ti n sọ ọ fun yin. Bayii gan-an, jọọ, maa bọ nile".
Ko pẹ pupọ lẹyin eyi ni Oladips tun ju fidio kan sori ayelujara, nibi to ti n sọ fun Rasheed kan naa pe ko maa gbe oun lọ sile iwosan, bẹẹ lo si jọ pe o n sunkun ninu fidio naa.
Ohun ti oloogbe naa fi soju opo rẹ gbẹyin ree kawọn ẹbi rẹ too kede pe o ti papoda.
Wakati meji lẹyin eyi, Rasheed ti Oladips darukọ naa bọ soju opo ayelujara, o si dahun sibẹ pe ‘’ Ẹ jọọ, ori ìrìn ni mo wa, mama rẹ ni ki n ma gbe e lọ s’ọsibitu, pe ki n maa gbe e bọ nile’’
Diẹ nipa igbesi aye oloogbe Oladips ree
Ileri oloogbe Oladips ni pe oun yoo gbe awo orin kan jade kọdun yii too pari.
O ṣalaye ninu ifọrọwerọ kan to ṣe, pe ọrọ iku Mohbad toun fẹ ko yanju naa loun ko ṣe ti i gbe awo orin oun jade.
Ko sọ asiko to fẹẹ gbe awo ọhun to pe akọle ẹ ni ‘Super Hero Adugbo’ jade, ṣugbọn o jẹ kawọn ololufẹ rẹ mọ pe oun yoo ṣere ita (concert) loṣu kejila ọdun yii
Oloogbe Oladips bi ọmọbinrin kan, Paris lorukọ to sọ ọmọ naa.
Gbajugbaja akọrin to ku yii ti ba Mayorkun ati Olamide kọrin pọ ri.
O kuro nileeṣẹ orin Reminisce nigba to ni wọn ko po kiki orin to n ṣe pẹlu Mayorkun, wọn ko si ya fidio rẹ.
Ni 2017, oloogbe Oladips di gbajugbaja olorin, iyẹn lẹyin ti orin rẹ to pe ni Lalakukulala jade.















