Wo ohun tí Labour Party àti NNPP sọ lẹ́yìn tí Atiku ní kí wọ́n parapọ̀ láti lé APC kúrò lórí oyè

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar
Ẹgbẹ oṣelu Labour Party ti sọ pe erongba oludije fun ipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar, lati ko ẹgbẹ oṣelu alatako pọ lati gba ijọba kii ṣe ohun to buru.
Amọ ẹgbẹ oṣelu NNPP ni tirẹ ni oun yoo gbe aba naa yẹwọ ti Atiku ba le ṣatilẹyin fun gomina ipinlẹ Kano tẹlẹ, Rabiu Kwankwaso, lati de ipo Aarẹ lọdun 2027.
Ọrọ yii lo n jade lati ọdọ LP ati NNPP lẹyin ti Atiku ke si awọn ẹgbẹ naa ki wọn parapọ lọna ati gba agbara lọwọ ẹgbẹ oṣelu APC to wa lori alefa lọwọ.
Ṣaaju ni Atiku ti kọkọ ke si awọn ẹgbẹ oṣelu naa pe ki wọn ṣe bẹẹ lasiko to n gbalejo igbimọ ajọ to n ri si ọrọ awọn ẹgbẹ oṣelu ni Naijiria.
Atiku sọ nibi ipade naa pe ti wọn ko ba gba agbara lọwọ APC, o ṣeeṣe ki Naijiria di orilẹ-ede ti ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo ti n ṣejọba titi lai.
O ni “Ati ri bi APC ṣe n sọ Naijiria di ijọba Basọrun Gaa ẹlẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo, ti a ko ba parapọ lati gbena woju wọn, eto oṣelu Naijiria ni yoo jiya rẹ, atunbọtan rẹ yoo si koba awọn iran to n bọ.”
Aba rere ni Atiku da – LP
Ẹwẹ, ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle Punch, agbẹnusọ Labour, Obiorah Ifo sọ pe gbogbo ọmọ Naijiria lo yẹ ki wọn gbe ọrọ ti Atiku sọ naa yẹwo.
O ni “Aba ni Atiku da, gbogbo ọmọ Naijiria lo si yẹ ki wọn gbe aba naa yẹwo lọna ati yọ awọn to wa lori oye kuro nitori wọn kii ṣe oloṣelu gidi.”
“Gbogbo ọmọ Naijiria lo n fẹ oṣelu tootọ, amọ eyii ti a ni lọwọ bayii kii ṣe oṣelu rara.”
“Nitori naa, ti ẹgbẹ alatako ba gbero lati jẹ ki oṣelu to ṣe e mu yanga gbilẹ ni Naijiria, kilode ti a ko ni ti irufẹ erongba bẹẹ lẹyin?”
“A ni lati ronu si daadaa, ohunkohun ti yoo ba mu ki awọn ọmọ Naijiria jẹ adun oṣelu tootọ lo ṣe itẹwọgba lọdọ tiwa.”
Kwankwaso nikan lo le ṣe – NNPP
Nigba ti NNPP n sọrọ, o ni igbesẹ Atiku naa ti pẹ ju.
Agbẹnusọ ẹgbẹ ọhun, Yakubu Shendam sọ pe ẹgbẹ oun ko ni lọwọ si ibaṣepọ kankan ayafi to ba jẹ lati ṣatilẹyin fun Kwankaso lati di Aarẹ.
O ni “A gbagbọ pe a nilo atilẹyin ọpọ eeyan lati bori ninu eto idibo, amọ ṣa, igbagbọ wa ni pe Kwankwaso nikan lo le gba Naijiria silẹ lọjọ iwaju.















