Gómìnà Adeleke kò jẹ́ rí Ooni Ile Ife fín, ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ni fídíò tó ń káàkiri – Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun

Oríṣun àwòrán, screenshot
Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti ke sọrọ sita pe ko si aawọ laarin gomina ipinlẹ naa, Ademọla Adeleke ati Ọọni ile ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, Ọjaja keji gẹgẹbi awọn kan ṣe n gbe e kiri.
Atẹjade ijọba ipinlẹ Ọṣun naa n waye pẹlu bi awuyewuye ṣe n ja ranyinranyin lori fidio kan ti awọn kan fi sita eyi to ṣafihan pe Gomina Ademọla kọ lati bọwọ pẹlu Ọọni.
Kọmiṣọna fun eto iroyin ni ipinlẹ Ọṣun, Kọlapọ Alimi ṣalaye ninu atẹjade to fi sita lori ọrọ naa pe ajọṣepọ to dan mọran lo wa laarin awọn aṣiwaju mejeeji yii eleyi to ni o farahan nibi apejẹ iwuye Sẹnetọ Olubiyi Ajagunla ni aafin Oṣemawe ti ilu Ondo.

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Atẹjade naa tun ṣalaye pe wọn ti tọwọbọ fọnran fidio to n kaakiri naa ati pe ẹkunrẹrẹ ẹda fidio ọhun ti wa lori ayelujara fun awọn eeyan lati wo.
Ijọba ipinlẹ Ọṣun ni awọn agbodegba fun ẹgbẹ alatako ijọba lo n fọn iroyin ẹlẹjẹ naa kiri.
Bi o tilẹ jẹ wi pe ẹkunrẹrẹ fidio naa fihan pe Ọọni ati gomina Adeleke kira ṣaaju ibi ti wọn ti ge fọnran fidio naa ati lẹyin ibi ti wọn ge e pari si.










