Mo ṣe amúgbálẹ́gbẹ́ fún Ooni Ile Ife kí n tó di olorì – Olorì Aderonke Ademiluyi Ogunwusi
Olori laafin Ọọni to tun jẹ eekan afaṣọdara, Olori Aderonkẹ Ademiluyi Ogunwusi sọ pe ọdun mẹwaa loun ti fi mọ olori ọba alade naa ki oun to di olori ni aafin rẹ.
Olori Aderonkẹ ṣalaye pe ki Kabiyesi Ọọni Adeyẹye Ogunwusi, Ọjaja keji to di ọọni loun pẹlu rẹ ti n rin irinajo mmi n mọ ọ bọ gẹgẹ bi ọmọọba.
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, Olori Aderonkẹ Ogunwusi ṣalaye pe lasiko ti oun fi n wa onigbọwọ fun eto ‘Nigeria Fashion show’ti oun maa n ṣe nigba naa lo mu oun de ọdọ rẹ nigba naa to ṣi jẹ Ọmọọba.
“Ni kete ti wọn rii pe nnkan ti mo n ṣe n gbe aṣa larugẹ, ti wọn si tun rii pe mo jẹ ọmọ ifẹ ti mo tun jẹ ọmọ ọba ni wọn ti gba lati bẹrẹ si ni ran mi lọwọ.”
- Olubadan gba ilẹ̀kẹ̀ lọ́run Mogaji, ó ní kó lọ rọọ́kun nílé torí àáwọ̀ ilẹ̀ pẹ̀lú aráàlú
- Àlejò ń fẹ́ lé Onílé jáde lọ̀rọ̀ àwọn Alfa tó ń gbógun tí oníṣẹ̀ṣe nílùú Ilorin- Ifayemi Elebubon
- Ooni, Sultan, àwọn lọ́balọ́ba ṣèpàdé pẹ̀lú Tinubu
- Ṣé lóòtọ́ ni pé Ooni Adeyeye Ogunwusi ń gbaradì fún ìgbéyàwó míràn?
Ọọni Adeyeyẹ Ogunwusi lo mu mi lọ si ilu Ifẹ fun igba akọkọ laye mi – Olori Aderonkẹ

Pẹlu bi o ṣe jẹ pe ọmọ ọmọ ile Ifẹ ati ile ọba ni olori Aderonke Ademiluyi Ogunwusi, o ni oun ko de ilu ifẹ ri ayafi igba ti oun ati ọọni bẹrẹ ajọṣepọ ti balaye naa mu oun de ile ni ọdun 2015.
O ni ọmọ-ọmọ Ọọni to jẹ ṣe ẹkẹrin nilu ile Ifẹ, Ọọni Ademiluyi loun jẹ, ṣugbọn ilu Oyinbo lawọn obi oun bi oun si, ki awọn obi oun to gbe oun pada wa si Naijiria.
Olori Aderonkẹ ni lasiko ti awọn obi oun gbe awọn wa sile, kii ṣe ilu ile Ifẹ ni wọn wa, ilu Akurẹ loun ti ka iwe ẹkọ girama oun.
Alaye ọrọ rẹ ree ninu fọnran oke yii.



