Ooni Adeyeye's father John Ogunwusi: Ohun to ṣẹlẹ̀ láàrin Ooni àtàwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lásìkò tó fẹ́ jẹ Ọba rèé
Ọmọba ati Baba Ọba ni Akọle lo tẹle orukọ Baba to bi Ooni ti Ile Ife gangan, iyẹn Ọmọba/Baba Ọba John Oluropo Ogunwusi.
Baba to pe ẹni ọdun ọgọrin lọdun 2022 yii ṣalaye iru ayanmọ didi Ọba eyi ti o dabii pe Eleduwa da a mọ Ọba Adeyeye Ogunwusi ni.
Lati idile Ọba Giẹsi ni Ọjaja lagbegbe Moore nile Ife ni Baba John ati ọmọ rẹ Adeyeye Ojaja Keji ti wa.

Oríṣun àwòrán, Ooni of Ife
Baba Ooni ṣalaye iran ti Wolii kan ti ri nigba ti iya rẹ ko tilẹ tii loyun rẹ eyi to sọ nipa akọsẹjaye rẹ.
"Emi ati iya rẹ joko si iwaju ile lọjọ kan ni Wolii n kọja to ni maleka Ọlọhun loun to si ni Ọlọhun maa fi ọmọ kan ta wa lọrẹ pe ọla Ọlọhun laye rẹ yoo karii gbogbo aye".
Baba Ọba John tun ni Wolii ọhun yanana rẹ pe kii ṣe ọmọ ti wọn ba bi laarọ tabi ọsan bi ko ṣe eyi ti wọn ba bi ni ago kan geerege ni ọmọ alalubarika ti oun n sọ.
Baba Ọba John tun ṣalaye pe nigba ti oun yoo ti pa ẹsẹ da pe ki oun ta Woli ọhun lọrẹ, o ti poora.
Baba Ọba tun sọ omii pe baba oun gan ti ni ki awọn ma maa fi ọwọ gba a lori toripe ori ade ni.
'Ọjọ́ méjì àti wákàtí díẹ̀ péré la fún Ramon Adedoyin láti gbé ìwée 'a kò ní ẹjọ́ jẹ́' wá sílé ẹjọ́'
Ninu ọmọkunrin mẹta ti Ọlọrun fi ta Baba John lọrẹ, o ni oun ti n tọ gbogbo wọn sọna ni ilana jijẹ Ọba tori ẹnikẹni ti yoo jẹ to si yẹ ki wọn dije du ipo Ooni amọ iyalẹnu lo jẹ fun wọn nigba ti asiko to ki idile mu ọmọ oye silẹ ti awọn ẹgbọn Ooni Adeyeye mejeeji yari pe awọn ko raye tabi nifẹ si jijẹ Ọba Ife.
