Money to who turns to cat in Ibadan: Njẹ́ iwọ lòògùn owó tó lè fí hàn? Ka nípa arákùnrin tó ṣetán láti fún ẹnikẹni tó bá lè fí oògùn hàn ní 2.5m

Gbenga Adewoyin
    • Author, Nduka Orjinmo
    • Role, BBC News, Ibadan

Dan an wo lo bi iya ọkẹrẹ larakunrin yi fi ọrọ naa ṣe.

Ninu ọja Gbagi ni ilu Ibadan lo si gbe ipolongo rẹ lọ lati fi mọ boya lootọ ni oogun a maa jẹ.

Ẹni ba pade Gbenga Adewoyin yoo ro pe oniwaasu ni tabi ẹni to n polowo ọja amọ bi ẹ ba ti gbọ ọrọ ẹnu rẹ, ohun to wa ṣe yoo ye eeyan kedere.''Ẹnikẹni to ba le fi han mi pe oogun wa, miliọnu meji naira abọ ni maa fi taa lọrẹ''.

Aworan afihan oogun abẹnugangan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ṣigidi bi iru eleyi lawọn eeyan nigbagbọ si pe o lagbara lati ṣaburu fun eeyan

Leralera lo n mu ikede yi bẹnu lede Gẹẹsi ati Yoruba amọ kete tawọn eeyan to sunmọ ọ ba gbọ nkan to wi tan, wọn a pẹsẹda kuro lọdọ rẹ.

Laipẹ yi ni ẹni ọdun mẹ́rinlelogun yi bẹrẹ ipolongo loju opo ayelujara ni itako igbagbọ ninu oogun tabi awọn nkan ti a ko le fẹnu ṣalaye.

Ni tootọ Gbenga ko ni igbagbọ pe Ọlọrun wa ṣugbọn iru igbagbọ rẹ yi ko ribi joko si laarin ọpọ ni Naijiria.

Igbagbọ pe oogun wa jẹ eleyi to gbilẹ laarin awọn alakọwe ati awọn mii ti ko kuku kawe. Ọpọ a si maa ṣe ẹsin abalaye pẹlu ẹsin Kristẹni tabi ti musulumi.

Àkọlé fídíò, Wòlíì ni ọmọ táà bá bí ni ago kan géérégé ni...Bàbá tó bí Ooni Adeyeye Ogunwusi sọ àṣírí àkọsẹ̀jayé rẹ̀

Onimọ Olaleye Kayode ,to jẹ olukọni agba ni fasiti Ibadan sọ fun BBC pe oogun owo ,tawọn eeyan a maa lo ẹya ara eeyan lati fi ṣẹṣo a maa jẹ lootọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ awọn alujannu lo maa gbe owo aganran tawọn ẹni naa a maa na wa lati ile ifowopamọ.

Jude Akanbi, toun naa jẹ olukọni ni fasiti Crowther Graduate Theological Seminary in Abẹ́òkúta ko niye meji pe oogun wa lootọ.

"Agbara lati yira pada di olongini, tabi eeyan poora ko si tun foju han, gbogbo rẹ lo wa lọwọ awọn Yoruba to mọ orukọ ti ewe n jẹ''

Àkọlé fídíò, Money Ritual: Ǹ kò le bèèrè

O tẹsiwaju pe ''lootọ o jọ pe ko bojumu ṣugbọn pẹlu nkan taa ti ri, lootọ ni oogun wa''

Lẹnu lọọlọ yi, igbagbọ tawọn eeyan ni pe lilo ẹya ara lati ṣe oogun owo ti jẹ nkan to n kan awọn araalu lominu.

Eyi ko si sẹyin bawọn ọdọ kan se n fi awọn obinrin ṣẹsọ ti wn si n pawọn ni ipakupa.

Idi ti mo fi lọ koju awọn to sọ pe oogun wa pẹlu 2.5miliọn

Àkọlé fídíò, Africa Eye Kenya blood sucking road: Àṣírí àwọn ọ̀nà mùjẹ̀-mùjẹ̀ tú! 'À ò kí ń mọ̀ bóyá a

''Bo ba ṣepe oogun owo n ṣiṣẹ ni, ko yẹ ki ọrọ aje wa ma ti doju bolẹ pẹlu iru owo tabua tawọn eeyan yoo ti ni lati igba ti wọn ti n ṣe oogun yi''

Bayi ni o se n tẹnumọ idi to fi ro pè ko si oogun rara.

O mu ọb kan lọwọ to si sọ pe ki ẹni to baa loogun ti ọb ko fi ni gẹ yọju lati wa gba miliọnu meji abọ Naira.

Ilu Ibadan lo gbe ipolongo yi lọ lẹyin to ti kọk bẹrẹ loju opo Twitter tawn eeyan si ti dawo jọ pe ko lọ koju awọn to ni oogun wa.

Àkọlé fídíò, Elebuibon: Àwọn àṣà àtọ̀húnrìnwá ló fa títa ẹ̀jẹ̀ nítorí ògùn owo

Amọ ṣa iru nkan ti Adedoyin n danwo laarin ọja yi lewu ni awujọ ilẹ Yoruba.

O ṣeeṣe ki awọn eeyan yabo tabi ki awọn mii mu pe o n sọ isọkusọ.

Ju bẹẹ lọ awn mii le fẹ dan iṣẹ wo lara rẹ ṣugbọn titi di igba to fi kuro lọja ko si ẹni to koju rẹ.

Awọn to kọja kan n sọ pe ''ọmọde rẹ ko da oogun m, o n pe lẹfọ''

Ninu wọn larakunrin kan wa to yọ bantẹ kan jade ninu apo rẹ to si ni lootọ ni oogun wa.

Pẹlu bi Adedoyin se sọ to, ko safihan iru itu ti oogun rẹ le pa toun ti pe wọn ni ko wa gba ẹgbẹrun mẹfa dọla lati fi jẹwọ ara rẹ.

Nibayii, Adedoyin ti gbe ipolongo rẹ l si ipinlẹ Anambra lẹyin ti awọn to ko ija lọ ba ni Oyo ati Ogun ko ri nkankan ṣe si ọrọ rẹ.

Lawujọ wa loni, igbagbọ oogun jẹ eleyi to fẹsẹ rinlẹ laarin awọn musulumi ati Kristẹni.

Awọn oniwaasu ẹlẹsin mejeeji a si maa fi iwaasu wn koju ẹsin abalaye gẹgẹ bi nkan toburu tawn si le fi agbara ti wọn bori.

Aimọye Pasitọ ni wn ti di ilumọọka ti wn si ti dọlọrọ nipa pe awọn le fi agbara ti wọn bori oloogun. Awọn alufa musulumi kọọkan naa a maa se bẹ.

Bo ti lẹ jẹ wi pe awọn eeyan kan sọ pe karimi lasan ni Adedoyin n ṣe, eleyi ko mu ki a sọ pe ko si ootọ ninu aworan awọn ti wn ge lapa lẹsẹ nitori oogun owo.

Aworan Adedoyin
Àkọlé àwòrán, Adedoyin ni oun fẹ fọrọjomitooro ọrọ lori oogun pẹlu awọn oloogun

Nigba wo wa ni pipa eeyan fi ṣoogun owo wa di gbajumọ?

Aṣa yi gbalẹ laarin ọdun 1990 de bi pe awọn kan se iwọde ni Owerri lẹyin ti wọn ṣeku pa ọmọkunrin ọdun mọkanla kan nitori oogun owo.

Ni bayi ti oju opo ayelujara ti sọ gbogbo nkan di pe ko si aṣiri kankan mọ,ojojumọ la fi n gbọ iroyin eeyan to sọnu tabi ti wọn ge ara wọn lati fiṣe oogun owo.

Losu to kọja yi ni iroyin iku ọmọdebinrin kan tawọn ọmọdekunrin ti ọjọ ori wọn ko kọja ogun ọdun gbode lẹyin ti wọn ge ori rẹ lati fi ṣoogun owo.

Ọrọ yi kan ara ilu lominu tawọn eeyan si n beere pe kini awọn ọmọde wọnyi fẹ fi owo ṣe debi pe wọn ṣeku pa eeyan.

Arakunrin kan to kunlẹ siwaju babalawo

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Oogun fẹsẹrinlẹ ni orileeede Benin to jẹ alamuleti Naijiria

Awuyewuye yi mu ki awọnaṣofin jiroro lori ọrọ yi ti wọnm si ni kiijọba wa wọrọkọ fi ṣada ki ọrọ to kọja afẹnusọ.

Wọn di ẹbi ru awọn fiimu Nollywood pe wọn n gbogo fun oogun owo ṣiṣe.

Koda Minisita fọr Aṣa Lai Mohammed naa da si to si ni ki ajọ to n mojuto ere fiimu bawọn elere fiimu sọrọ ki wọn ye gboriyin fun oogun owo ṣiṣe.

Ọrọ yi ko dunmọ awọn elere sinima ti wọn si fesi pada fun Minisita pe o fẹ fi ori awọn fọ agbọn lori ọrọ tawọn ko mọwọ mẹsẹ ni.

Kanayo O Kanayo to jẹ agbaọjẹ elere sinima ni ẹbi ọrọ naa wa lọdọ awọn obi awọn onimọ aṣa olori ẹlẹsin ati awọn oloṣelu to yẹ ko mojuto awọn ọdọ.

Adedoyin kasẹ ọrọ nilẹ pe ''Bi awọn eeyan ṣe n wi ti ọkan wọn lori ọrọ yi, eleyi to nilo akiyesi ni ẹka eto ẹkọ wa to kọ lati j ki awọn eeyan mọ pe ofutufẹẹtẹ ni pe oogun wa''

Ireti rẹ ni pe ipolongo yi yoo jẹ ki awọn eeyan mọkan kuro nibi aburu yi ki wọn si gbajumọ nkan mii to ṣe pataki lawujọ.