Demilade Fadare: Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí tí wọ́n fẹ̀sùn ikú Demilade, ọmọ ọdún méje tí wọ́n bá òkú rẹ̀ nínú 'cooler' lẹ́yìn tó dàwátì ní Ado-Ekiti

Oríṣun àwòrán, BBC/other
Ọwọ ọlọpaa ti tẹ afurasi ti wọn n fi ẹsun kan pe o pa Fadare Demilade, ọmọ ọdun meje ti wọn ba oku rẹ ni agbegbe Boluwaduro nilu Ekiti.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ọwọ tẹ afurasi naa atawọn obi rẹ ti wọn si ti n fi ọrọ wa wọn lẹnuwo.
Ni ọjọ kẹfa oṣu kejila ọdun 2021 ni iya Demilade ke gbajare lọ si agọ ọlọpaa to wa ni agbegbe Oke-ila nibi to ti fi to wọn leti pe oun n wa Demilade ọmọ oun lẹyin ti oun ti ran an lọ ra ẹkọ mimu wa ti ko si pada wale lẹyin wakati mẹta.
- Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ n kọlu àwọn ọkọ̀ nla ní Ojodu-Berger, nítorí àwọn akẹgbẹ́ wọn ti ọkọ̀ pa lánàá
- Ẹnikẹ́ni kò ní lè yọjú síbi ayẹyẹ kankan l'Eko láì fi ẹ̀rí hàn pé ó ti gbabẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19- Sanwo-Olu
- Àwọn agbébọn dáná sun èrò ọkọ̀ 42 láàyè ní ìpínlẹ̀ Sokoto
- Ikú Sylvester Oromoni: Wo kókó òfin ìpínlẹ̀ Eko mẹ́wàá tó tako ẹgbẹ́ òkùnkùn
Nigba to di bi agogo mẹfa irọlẹ ọjọ naa ni Ọgbẹni kan ti orukọ n jẹ Ọlajiga ati aya rẹ wa si agọ ọlọpaa kan naa lati fi ẹjọ sun pe awọn ba oku Demilade ti wọn n wa naa ni inu yara ọmọ awọn ti wọn sọ pe o langanna, ti wọn si woye pe, o ṣeeṣe ko jẹ pe oun lo pa ọmọdebinrin naa.
Iroyin abẹle tilẹ kọkọ sọ pe afurasi naa ti kọkọ na papa bora ni alẹ ọjọ Aje ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.
Eyi lo mu ki awọn eeyan kan ladugbo o lda ina sun ile wọn ti awọn oluwọde kan si jade lati bere fun idajọ ododo lori rẹ.
Kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Ekiti, Tunde Mobayọ ti paṣẹ ki iwadi idakọnkọ bẹrẹ lori iku to pa Fadare Demilade, ọmọ ọdun meje naa bayii.
Gẹgẹ bi atẹjade kan ti ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ naa fi sita, awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori rẹ bayii.
Ìbànújẹ dórí ẹbí Demilade kodò, ọdọ ìlú fi'binu dáná sún ilé pásítọ̀ tí wọ́n furasí lórí ìkú rẹ̀

Agba adura ni pe ki abiyamọ ma foju sunkun ọmọ.
Amọ ọrọ ko ri bẹẹ nigba ti awọn obi ọmọdebinrin ọmọ ọdun meje kan sadede ji lo'wuro ọjọ Isẹgun lati ri oku ọmọ wọn l'ẹgbẹ ilẹ wọn.
Àdúgbo Adeun ni Ado Ekiti láwọn obi Demilade Fadare ti ri oku rẹ ti wọn ti ge wẹlẹwẹlẹ lẹyìn ọjọ kan ti wọn ti n wa omode naa.
Ohun táa gbọ ni pé arabinrin alagana kan lo ge Demilade wẹlẹwẹlẹ.
A tun gbo pe iya Demilade ran niṣẹ l'ẹgbẹ ilẹ wọn lọjọ Aje ṣugbọn ọmọde yi kò padà wale.
Nigba ti mama rẹ kò rí Demilade,o figbe ta ti awọn araadugbo sì bẹrẹ sí ní bàa wa omode naa.
Gbogbo igbiyanju wọn já sí pabo titi di igba ti wọn padà wá rí oku rẹ l'ẹgbẹ ile wọn lọjọ keji
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ,baba arabinrin alagana ti wọn fura si pe o seku pa Demilade lọ fẹjọ sun ni agọ ọlọpaa lori iru ara ti ọmọ rẹ dá yi.

Titi di igba ta fi n ko iroyin yi jọ kò sí ẹni tó mọ ibi ti arabinrin yi wa ṣugbọn awọn agbofinro ti mu obi rẹ.
Ibinu nkan tó ṣẹlẹ yi mu kí àwọn ọdọ kan ladugbo dana sun ile awọn òbí arabinrin yi.
Alukoro ọlọpaa Ekiti Sunday Abutu fìdí iṣẹlẹ yi múlẹ tó sì ni afurasi naa ati awọn obi rẹ wà ní ahamọ lọdọ awọn.
Oro nla leleyii jẹ- ẹbí ati ẹgbẹ obinrin to ṣewọde

Awọn mọlebi ati ẹgbẹ awọn agbẹjọro obìnrin ni Ekiti ti pe fún ifidi ododo múlẹ lórí ikú ọmọdebinrin Demilade.
Lasiko iwọde kan ti wọn ṣe lọjọ Ìṣẹgun niwaju ọfisi iyawo Gomina ipinle naa ni wọn ti ke gbajare yi.
Awọn oluwọde yi n kọ orin aro orisirisi ti wọn sì gbé iwè lọwọ eyi ti won kọ ọrọ sí láti ṣàfihàn ẹdun ọkan wọn lórí ikú Demilade.
Arabinrin Abimbola Ajaja to lewaju awọn agbẹjọ́rò kẹdun iku Demilade tó sì ni iru iwà isekupa ọmọde lẹnu ọjọ mẹta yi gba amojuto.
O kesi awọn ọlọpaa lati se iwadii to yẹ kí àwọn tó bá mọ nipa iku Demilade le fojú wina ofin.
Wọ́n bá òkú ọmọ ọdún méje tó di àwátì nínú 'cooler' nílé 'pásítọ̀' ní Ado-Ekiti

Oríṣun àwòrán, others
Ariwo ibosi, ara adugbo, iru kileyi lo gba ẹnu awọn olugbe Adehun nilu Ado-Ekiti, nipinlẹ Ekiti, lowurọ oni.
Eyi ko ṣẹyin bi wọn ṣe deede ba oku ọmọdebinrin ọmọ ọdun meje kan, Demilade Fadare, ninu ile aladugbo rẹ.
Iroyin sọ pe ọjọ Aje, ọjọ kẹfa, oṣu Kejila, ni wọn ran ọmọ naa niṣẹ, amọ ko pada sile.
Lati igba naa si ni wọn ti n wa ọmọ naa ko to di pe wọn ri ninu ile kan ti ko jina sile wọn.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, ASP Sunday Abutu, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba sọ pe alẹ ọjọ Aje ni iroyin bi ọmọ naa ṣe di awati de etigbọ awọn ọlọpaa, ti wọn si bẹrẹ si ni wa.
- 'Ọmọ mi mẹ́rin, ọmọ àbúrò mi mẹ́ta ló wà lára àwọn ọmọ tí wọ́n bá òkú wọ́n nínú ọkọ̀'
- Àwọn mọ̀lẹ́bí Sylvester Oromoni bẹ Femi Falana lọ́wẹ̀ láti pe Dowen College lẹ́jọ́
- Àwọn akọrin ìjọ tó fẹ́ lọ ṣe ìgbéyàwó kàgbákò òjò àrọ̀rọ̀dá, ẹ̀mí 23 sọnù...
- Ṣé lóòtọ́ ni ajínigbé sọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjí di iṣu ní Ibadan?
- "Kí ló dé tó jẹ́ orúkọ ẹbí Kashamu nìkan lẹ mú bọnu nínú àwon ọmọ Marun ti Oromoni Jnr dárúkọ?"
- Àwọn ilé ẹjọ́ ní Naijiria yòó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ìgbẹ́jọ́ lórí ayélujára
- Àwọn ẹ̀yà kan rèé tó pe iléeṣẹ́ Facebook lẹ́jọ́, wọ́n ń bèrè $150b owó gbà mábìnú
Ọgbẹni Abutu sọ pe lootọ ni awọn ara adugbo pada ri oku ọmọdebinrin naa ninu ile kan ni adugbo ọhun.
Iroyin ni ile kan to jẹ ti pasitọ kan ni wọn ti ri oku ọmọ naa, to si ni ọpọlọpọ ọgbẹ ibi ti wọn ti fi nkan gún ni ara.
Agbẹnusọ ọlọpaa sọ pe awọn ọlọpaa ti mu ọkunrin to ni ile naa lọ si agọ awọn fun iwadii.
Yatọ si eyi, iroyin naa ni niṣe ni wọn ti ge ẹya ara ọmọ naa yẹlẹyẹlẹ, ti wọn si ko si inu abọ amounjẹ gbona 'cooler'.
Eyi si lo mu ki awọn olugbe agbegbe ọhun dana sun ile ti wọn ti ba oku ọmọ naa.
Iroyin miran to tun n lọ lori ayelujara, amọ ti a ko tii fidirẹ mulẹ sọ pe ọmọ pasitọ to ni ile na, ṣugbọn to jẹ alarun ọpọlọ, lo ṣekupa ọmọ ọhun.














