Rohingya sue Facebook: Àwọn ẹ̀yà kan rèé tó pe iléeṣẹ́ Facebook lẹ́jọ́, wọ́n ń bèrè $150b owó gbà mábìnú

Rohingya refugees

Oríṣun àwòrán, Reuters

Awọn aṣatipo Rohingya kan nilẹ Gẹẹsi ati Amẹrika ti pe ileeṣẹ Facebook lẹjọ.

Wọn fẹsun kan Facebook pe oju opo rẹ lawọn eeyan kan ti n sọrọ ikorira nipa awọn ti ileeṣẹ naa ko si ri nnkankan ṣe nipa rẹ.

Ẹya ọhun ti wa bere owo gba mabinu ti iye rẹ tọ ogoje biliọnu dọla lọwọ ileeṣẹ naa bayii fun bo ṣe dakẹ gbera lori ọrọ ti awọn to n lo oju opo naa kọ nipa awọn.

Nnkan bii ẹgbẹrun mẹwaa awọn ẹya Rohingya to jẹ Musulumi ni wọn padanu ẹmi wọn lasiko ti awọn ọmọ ogun ya bo awọn eeyan naa lorilẹ-ede Myanmar lọdun 2017.

Wọn ni Facebok faye gba awọn eeyan lati maa sọrọ kobakungbe nipa ẹya naa fun ọpọ ọdun.

Nilẹ gẹẹsi, ileeṣẹ agbẹjoro to n ṣoju awọn ẹya naa ti kọ lẹta si Facebook, ninu eyii ti wọn fẹsun kan facebook pe o gba ọrọ odi nipa awọn eeyan naa laye loju opo rẹ.

Wọn tun ni o kọ lati yan awọn eeyan ti yoo maa bojuto ohun ti awọn eeyan n kọ nipa bi eto oṣelu ṣe n lọ lorilẹ-ede Myanmar.

Àkọlé fídíò, Mama Deeper Life Ondo

Wọn tun sọ siwaju si pe ileeṣẹ Facebook kọ lati yọ awọn ọrọ odi nipa awọn eeyan naa kuro loju opo rẹ, bo tilẹ jẹ pe awọn ileeṣẹ iroyin kan ti kilọ fun Facebok lati ṣe bẹẹ ṣaaju.

Nilẹ Amẹrika ẹwẹ, awọn agbẹjọro kan ti pe Facebook lẹjọ niluu San Fransisco lori ọrọ yii kan naa.

Wọn ni Facebook n fi ẹmi awọn eeyan naa ta tẹtẹ lọna ati ri ero pupo loju opo rẹ.

Bo tilẹ jẹ pe Facebook sọ lọdun 2018 pe lootọ ni ohun ko ṣe daadaa to lori ọrọ awọn eeyan naa, ṣugbọn ko tii fesi si ẹjọ yii.

Ileeṣẹ iroyin BBC ti kan si Facebook lori ẹsun naa, ṣugbọn a ko tii gbọ esi kankan lati ọdọ wọn.

Àkọlé fídíò, Ṣé lọ́òtọ́ ọkọ àti ìyàwọ́ ní Mr & Mrs Kogberegbe? Àṣírí bí a ṣe ń ṣe ètò yìí rèé...